Google ati awọn ọmọ Naijiria ṣe ìrántí ọjọ ibi Dokita Stella Adadevoh pẹlu àwòrán

Dr Ameyo Stella Adadevoh,

''Eeehya! Iku ma d'oro o!

Emi na ri "doodle" naa ni owuro oni, ni igba ti mo si oju-iwe google lori ayelujara itakun agbaye.

Mi o kọkọ mọ itumọ rẹ fun igba diẹ, sugbọn lẹhin ti mo ri aworan kokoro aarun Ebola , o ye mi kedere wi pe Arabinrin Dokita Stella Folashade Adadevoh ni wọn n se iranti rẹ.

Ki Ọlọrun Olodumare o fi ọrun kẹ wọn.''

Ọrọ ree lati ọdọ ọkan lara awọn ololufẹ oju opo BBC Yoruba, arakunrin Olayemi Patrick Edema nigba ti o ri aworan Dokita Stella Adadevoh ti Google se iranti ọjọ ibi méjílélọ́gọ́ta ti ko ba ṣe kani pe o wa laye.

Oríṣun àwòrán, Google

Oun nikan kọ ni o n ranti Dokita Stella Adadevoh ati ipa ribi ribi to kọ nigba ti itankalẹ aarun Ebola ṣẹlẹ ni Naijiria.

Loju opo ayelujara ni kete ti aworan Google yii lu jade ni awọn ọmọ Naijiria ti n fi ọrọ iranti ati adura ranse loju opo Twitter lori ọjọ ibi Dokita Adadevoh.

Sugbọn ṣe ẹyin tilẹ ranti itan Dokita Adadevoh ati oun ti o ṣe ti gbogbo eeyan fi n jaran iku rẹ?

Ẹ jẹ ki a ranyin leti.

Patrick Sawyer ati Dokita Stella

Ogunjọ osu kẹjọ odun 2014 ni Dokita Stella Ameyoh Adadevoh se alabapade arakunrin ọmọ orileede Sierra Leone kan ti orukọ rẹ n jẹ Patrick Sawyer nigba ti arakunrin naa ti o ni aarun Ebola fẹ fi tipa kuro ni ile iwosan aladani kan ti Dokita Stella ti n sisẹ ni ilu Eko.

Oríṣun àwòrán, PIUS UTOMI EKPEI/Getty

Ipade wọn yii jẹ eleyi to lamilaka nitori oun lo se okunfa bi Dokita Adadevoh ti se di ilumọka gẹgẹ bi ẹni to kọdi itankalẹ aarun ebola ni orileede Naijiria.

Oye ati ifarajin Dokita Stella lo mu u sọ wi pe oun ko ni jẹ ki wọn tu arakunrin na silẹ kuro nile iwosan naa nitori pe o fura si i pe o ni aarun Ebola.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ilakaka rẹ ati tawọn osise ilera miiran sokunfa bi Naijiria ti se ribi koju aarun yi ti ajọ eleto ilera lagbaye si sọ wi pe Naijiria ti jajabọ lọwọ ajakalẹ aarun naa logunjọ Osu kẹwa ọdun 2014.

Àkọlé fídíò,

Àtọ̀ ọmọkùnrin ti rógo o!

Oríṣun àwòrán, Reuters

Ipinlẹ Eko ti isẹlẹ yi ti waye ko ni agbara tabi ipalẹmọ kankan ti wọn se kalẹ de aarun Ebola sugbọn igbiyanju Dokita Stella ko ipa ribiribi lati le dena aarun naa.

Lẹyin orẹyin, arakunrin Patrick Sawyer to gbe aarun naa wọ Naijiria ku ti osisẹ ilera mẹfa si padanu ẹmi wọn bakanna.

Ninu awọn mẹfa naa ni a ti ri Dokita Stella Adadevoh.