Olóòtú ìjọba Abiy ni awọn obìnrin kìí hùwà jẹgúdújẹrá tó àwọn ọkùnrin

Aworan awọn minisita Ethiopia

Oríṣun àwòrán, Alamy

Àkọlé àwòrán,

Okunrin mẹfa,Obinrin mẹfa ni wọn bura wọle fun sipo bi minisita lorileede Ethiopia

Njẹ ijọba orile-ede Naijiria le fun awọn obinrin ni ida kan ida meji ipo minisita ninu ijọ́ba?

Ibeere yi gba aronusi ṣugbọn ki ẹ to wa esi fun, a fẹ fi to yin leti wi pe awọn orile-ede kan l'Afrika ti n ṣe bẹẹ.

Olootu ijọba orile-ede Ethiopia Abiy Ahmed ti se oun ti ẹnikan o ṣe ri nijọba ilẹ naa pẹlu bi o ti ṣe fun awọn obinrin ni ida kan ninu ida meji awọn ipo minisita ninu ijọba rẹ.

Koda a gbọ pe minisita to n risi eto abo lorile-ede naa jẹ́ obinrin.

Nigba ti o n ṣalaye ohun to fa igbese yi, Abiy ni awọn obinrin kii ṣe onijẹgudujẹra bi awọn ọ́kunrin ati wi pe wọn leè mu alaafia ati iduro ṣiniṣin ba ijọba.

Oríṣun àwòrán, EDUARDO SOTERAS/AFP/GETTY

Àkọlé àwòrán,

wọn obinrin ti kun inu ijọba Ethiopia

Ni bayi, orile-ede Ethiopia ti kun Rwanda gẹgẹ bi orile-ede ti won ni ida to se deede laarin okunrin ati obinrin ninu ipo igbimọ alaṣẹ ijọba.

Bakan naa ni ọgbẹni Abiy mu adinku ba iye awọn to di ipo minisita mu ku lati mejidinlgbn si oogun.

Oríṣun àwòrán, Reuters

Àkọlé àwòrán,

Abiy ti ṣe awọn iyipada to lamilaka laarin oṣu mẹfa to de ori aleefa

Lati igba ti ọgbẹni Abiy ti de ori ijọba losu kẹrin, orisirisi ayipada lo ti mu ba isejọba.

O ti mu opin ba ija ogun ọdun ton waye laarin Ethiopia ati Eritrea, o si tun ti tu awọn oloselu ti wọn sọ sẹwọn silẹ.

O tun dẹkun bi ijọba ti se wawọ mọ eto ọrọ aje lorileede naa.

Aisha Mohammed ni o kọkọ kede orukọ rẹ gẹgẹ bi minisita fun eto abo.

Lati agbegbe Afar lo ti wa ni ariwa ila oorun Ethiopia ti o si ti saaju jẹ minisita fun eto ile kikọ

Muferiat Kamil, to jẹ olori ile asofin tele di Minisita fun eto alaafia akọkọ.

Oun ni yoo ma dari awọnile iṣe otẹlmuyẹ ati ọlọpaa ijọba apapọ orile-ede naa.

Mahlet Hailu, to jẹ igbakeji asoju Ethiopia si ajọ isọkan agbaye ṣe afihan iye awọn minisita tuntun ohun sójú opo Twitter pé

Ogbeni Abiy ni eto ayipada ọhun ni lati se agebyẹwo awọn aiṣedede to koba orile-ede awọn tele.

O ni awọn obinrin ko ipa ribiribi nipase mimu alaafia wa ti wọn ko si ki n mu igba kan bọ ọkan ninu.

Oríṣun àwòrán, AFP

Àkọlé àwòrán,

Aisha Mohammed ti saaju jẹ Minisita eto ikọle saaju ki o to jẹminisita fun eto abo

Ọmọ ọdun mejilelogoji naa di olootu ijọba leyin igba ti Hailemariam Desalegn ṣaadede fipo silẹ.

Eyi waye lẹyin ọpọ ọdun ti awọn ẹya Oromo ti n fi ehonu han lori bi wọn ti ṣe ko iyan wọn kere ninu isejọba orileede Ethiopia

Oromo ni ọgbẹni Abiy ṣugbọn bi o ti ṣe n pe fun isọkan ati ibaranisepo ti mu ki awọn ara ilu fẹ maa tẹwọ gba a.