Owó ounjẹ El-Zakzaky lósù kan nijọba lè fi bọ́ ẹlẹ́wọ̀n 208

Ibrahim El-Zakzaky

Oríṣun àwòrán, Islamic movement

Àkọlé àwòrán,

Agbẹnusọ fun ijọ ẹsin Shiite ni El-Zakzaky n kerora lori ohun ti oju rẹ n ri nipa ounjẹ

Miliọnu mẹta ati aabọ ti ijọba apapọ ni awọn fi n bọ olori ijọ Shiite Ibrahim El-Zakzaky to wa ni atimọle ni oṣooṣu ni iye ti ijọba apapọ fi n bọ ẹlẹwọn mẹjọlenigba ni Naijiria.

Eyi ni iwadii BBC Yoruba latari rogbodiyan to jade lẹyin ti Minisita fun Iroyin ati Aṣa ni Naijiria, Lai Mohammed sọrọ lori iye owo ounjẹ El-Zakzaky.

Isuna owo 2018 ti ileeṣẹ ijọba fun ọrọ abẹle eyi ti o n ṣe akoso awọn ọgba ẹwọn Naijiria ṣe fihan pe N15.34 biliọnu ni ijọba fi n bọ awọn ẹlẹwọn 75,789 to wa ni orilẹ-ede yii.

Eyi tumọ si pe, ẹlẹwọn kookan yoo fi N202,404 jẹun fun ọdun kan tabi N16,867 fun oṣu kan, eyi to ja si N562 lojoojumọ.

Miliọnu mẹta ati aabọ ti Lai Mohammed ni El-Zakzaki fi n jẹun ja si N117,000 lojoojumọ.

Ki ni ounjẹ ti ẹ ro pe N117,000 le ra ni ojoojumọ?

Àkọlé àwòrán,

Ki ni ounjẹ ti ẹ ro pe N117,000 na le ra ni ojoojumọ?

'Irọ́ ni Lai Mohammed pa pé #3.5M ni wọ́n fi n bọ́ El-Zakzaky'

Agbẹjọro fun Ibrahim El-Zakzaky ti sọ fun BBC pe irọ ni Alhaji Lai Mohammed pa lori iye ti El-Zakzaky fi n jẹun lojoojumọ.

Haruna Magashi sọ ọrọ naa gẹgẹ bi esi si ohun ti Minisita fun eto iroyin ati aṣa ni Naijiria, Lai Mohammed sọ ninu fidio kan, pe miliọnu mẹta ataabọ ni ijọba apapọ fi n bọ olori ẹlẹsin Shia loṣooṣu.

"Ọrọ yii ki ṣ'oun to pamọ fun mi, mo mọ nipa ohun ti mo ri ati nkan ti El-Zakzaky sọ fun mi, fun ra rẹ lo n ra ounjẹ to n jẹ lati igba to ti wa ni ahamọ

Àkọlé fídíò,

ẹ̀fọ́ rírò jẹ́ alábárìn iyán, fùfú, ẹ̀bà, àmàlà àti ìrẹsi funfun

"O si yẹ k'oju ko ti ijọba pe iru eniyan bi Lai Mohammed n parọ.''

Irọlẹ Ọjọbọ ni iroyin kan jade pr Minisita ọhun, Lai Mohammed sọ pe miliọnu mẹta ataabọ Naira ni ijọba fi n fun El-Zakzaky l'ounjẹ loṣooṣu lati igba to ti wa lakata wọn.

Ileeṣẹ amohunmaworan Oaks lo fi fidio ipade oniroyin ti Mohammed ṣe pẹlu awọn akọroyin lẹyin ti ipade igbimọ alaṣẹ orilẹede Naijiria waye l'Ọjọru.

Bakan naa ni agbẹnusọ fun ijọ ẹsin Shia lorilẹ-ede Naijiria, Ibrahim Musa sọ fun BBC News Yoruba pe ẹni ti wọn ba n na obitibiti owo bẹ fun ounjẹ rẹ yẹ ki o mọọ li ara.

Ẹwẹ, ọkan lara awọn oloye ẹgbẹ ẹlẹsin Shia, ta a tun mọ si Islamic Movement of Nigeria, IMN, Mohammed Ibrahim Gamawa, ṣalaye pe awọn ọmọ ijọ El-Zakzaky paapa maa n da owo lati fi ra awọn nkan ti olori wọn nilo lahamọ.

Àkọlé fídíò,

Ẹwa Agọnyin jẹ aayo ounjẹ Badagry

'Koda, ẹrọ amunawa t'oun lo lahamọ ti wọn fi si, awa la ra a."

Àkọlé fídíò,

Ìwà olè, jìbìtì àti ìjẹkújẹ ló n jé káwọn mii yí ọjọ́ orí wọn padà

IMN fidirẹmulẹ pe lootọ ni ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ti gbe El-Zakzaky kuro ni ilu Abuja lọ si ipinlẹ Kaduna, ṣugbọn wọn ko ti i gba beeli rẹ.

Amọṣa awọn ọmọlẹyin ijọ Shiite lorilẹ-ede Naijiria, IMN ni o ṣeeṣe ki o jẹ pe awọn eeyan kan ni ijọba aarẹ Buhari n fi orukọ aṣiwaju ẹsin Shiite naa, El-Zakyzaky gba owo si apo ara wọn.

"Gẹgẹ bi ẹ ṣe mọ bi iwa ijẹkujẹ ṣe gbilẹ ninu iṣejọba yii, eyi fihan pe nṣe ni wọn n gbọn owo kuro ninu apo araalu lorukọ Sheikh El-Zakyzaky nitori, lai fọta pe, irọ nla ni wọn n pa."

Ọrọ yii ti wa di alatagba laarin awọn Ọmọ orilẹede Naijiria bayii. Ti ọpọlọpọ si n bu ẹnu ẹtẹ lu minisita naa pe irọ pipa rẹ ẹ ti pọju, ati pe ijọba to n ri owo fun ẹni kan ṣoṣo l'ounjẹ pẹlu miliọnu mẹta ataabọ Naira gbọdọ le ri ọgbọ̀n ẹgbẹrun Naira san gẹgẹ bi owo oṣu oṣiṣẹ to kere ju.

Awọn kan tilẹ n ṣe atupalẹ iru ounjẹ ti ẹnikan le jẹ loṣu.

Shitte:El-Zakzaky tún kùnà láti rí ojúrere níle-ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, @i_batoula

Ile-ẹjọ giga to n joko si ipinlẹ Kaduna ti kọ lati gba oniduro adari ẹgbẹ musulumi Shitte, El-Zakzaky ati iyawo rẹ.

Iroyin to to wa leti sọ pe, ko to yọju si ile ejo ni Ọjọru, ile isẹ ọlọpa nipinlẹ Kaduna ti fofin de eto irinna awọn eniyan lagbeegbe ilu Kaduna.

Bẹẹ si awọn ọmọ ẹgbẹ́ Shitte ti n se iwọde lọpọ igba láti bèérè fún ìtúsílẹ̀ olórí wọn, Ibrahim El-Zakzaky, tó ti wà ní àhámọ́ àwọn ológun láti bi i ọdún méjì.

Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà àti àwọn ọmọ ẹgbẹ Shiite tún kọlu ara wọn l'Abuja

Ìròyìn tó tẹ̀wá lọ́wọ́ sọ pé iléèṣẹ́ ológun Nàìjíríà àti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn Shiite tún ti n kọlu ara wọn ní agbègbè Maraba nílùú Abuja.

Ìkọlu tuntun yìí wáyé lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ tí ọ̀kan wáyé. Tí iléèṣẹ́ ológun Nàìjíríà sì sọ̀ pé l'óòtọ́ ni àwọn ọmọ ogun yìnbọn pa ọmọ̀ ẹgbẹ́ Shiite mẹ́ta ní agbègbè Zuba, tó wà ní ìlú Abuja.

Ẹnìkan tí ìṣẹ̀lẹ̀ nàá ṣojú rẹ̀ sọ fún BBC pé ìjà ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ lásìkò tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Shiite n rìnrìn àjò láti Nasarawa lọ sí ìlú Abuja, tí àwọn ọmọ ogun sì ''dí ọ̀nà mọ́ wọn, pé kí wọ́n padà sí ibi tí wọ́n ti n bọ̀."

Ṣùgbọ́n, àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Shiite kò dá wọn lóhùn. Èyí ló mú kí wọ́n wojú ara wọn.

Akọ̀ròyìn BBC, Ahmed Wakili tí ìṣẹ̀lẹ̀ nàá ṣojú rẹ̀ jábọ̀ pé níṣe ni àwọn ọmọ ogun n yìnbọn sí afẹ́fẹ́, kí ìbọn nàá tó bá àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Shiite lásìkò tí wọ́n kọ̀ láti mú àṣẹ tí àwọn ọmọ ogun pa fún wọn ṣẹ.

Oríṣun àwòrán, Nigeria Army

Àkọlé àwòrán,

Aworan awọn ọmọ ogun naa farapa nibi iṣẹlẹ naa

O sọ pé ''àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Shiite péjọ sí agbègbè Maraba, wọ́n n gbìyànjú láti wọ ìlú Abuja.''

Òkú ènìyàn mọ́kànlá ni mo rí níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ nàá ti wáyé, tó fi mọ́ òkú obìnrin kan tó n tọ́mọ lọ́wọ́.

Agbẹnusọ fún ẹgbẹ́ Shiite sọ fún BBC pé ẹgbẹ́ nàá n ṣe ìwọ́de ẹ̀sìn tó l'ápẹrẹ ní ọ̀sán ọjọ́ Aje, ni àwọn ọmọ ogun yabò wọ́n.

Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ nàá n ṣe ìwọ́de láti bèérè fún ìtúsílẹ̀ olórí wọn, Ibrahim El-Zakzaky, tó ti wà ní àhámọ́ àwọn ológun láti bi i ọdún méjì.

Oríṣun àwòrán, Manzo Ezekiel

Àkọlé àwòrán,

Nísẹ ni àwọn tó n lọ, àti àwọn to n bọ̀ kòrí àáye kọjá nítorí bí ojú ọ̀nà ṣe dí.

Ní báyìí, páro-páro ni agbègbè nàá dá, tí àwọn onílé ìtajà sì ti gbé ilẹ̀kùn wọn tì pa.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò ti gbégi dínà gbogbo ọ̀nà tó wọ ìlú Abuja látu agbègbè ọ̀hún.

Iléèṣẹ́ ológun kò tíì sọ nkankan lórí ọ̀rọ̀ yìí, bẹ́ẹ̀ni a kò sí tí ì rí wọn bá sọ̀rọ̀ títí di àsìkò tí a kó ìròyìn yíì jọ.

Lóòtọ́ ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Shiite kú

Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà ti fidi ọrọ mulẹ pe awọn ọmọ ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn Shiite mẹta lo ku ninu ikọlu to wáyé láàrin àwọn ọmọ ogun Nàìjìríà àti ẹgbẹ Shiite l'Abuja.

Wọn ni awọn ọmọ ogun meji kan naa farapa ninu ikọlu ohun púpọ̀.

Ogagun James Myam ninu atẹjade kan ti o fi sita loju opo Twitter, Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà so pe ikọlu naa waye nigba ti awọn ọmọ ẹgbẹ ẹlẹsin naa gbegi dina awọn ọmọ ogun ti wọn n gbe ọta ati ohun ija lati Abuja lo si Kaduna.

Oríṣun àwòrán, Ibrahim Musa

Àkọlé àwòrán,

Òkú ènìyàn mọ́kànlá ni mo rí níbi tí ìṣẹ̀lẹ̀ nàá ti wáyé, tó fi mọ́ òkú obìnrin kan tó n tọ́mọ lọ́wọ́.

O ni o ''ṣe ni laanu pe awọn ọmọ ẹgbẹ naa mẹta padanu ẹmi wọn ninu ikọlu ohun ṣugbọn awọn ọmọ ogun meji naa farapa.''

''Iwọde lo yẹ ki wọn ma ṣe ṣugbọn niṣe ni wọn gbegi dina ti wọn ko jẹ ki awọn eeyan kọja.

Nigba ti awọn ọmọ ogun wa gbiyanju lati kọja,niṣe ni wọn kagidi bori ti wọn si bẹrẹ si ni sọ oko ati awọn nkan ija oloro lu wa.Wọn ba ọkọ wa ati tawọn ara ilu ti wọn koja ninu iṣẹle naa.''

Oríṣun àwòrán, @Nigerian Army

Àkọlé àwòrán,

Aworan awọn ọmọ ogun naa farapa nibi iṣẹlẹ naa

Eyi kii se igba akọkọ ti ikọlu yoo ma waye laarin awọn ọmọ ogun Naijiria ati ọmọ ẹgbẹ Shiite papajulọ lati igba ti awọn ologun ti sọ olori wọn Ibrahim El-Zakzakky si ahamọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Shiite: Tinúbú, bá Buhari sọ̀rọ̀ kó tú ZakZaky sílẹ̀ kó tó pẹ́ jù