Àwọn obi ọmọ Obìnrin Chibok ni wọn tí lọkọ ní Cameroon

Aworan obi ọmọ Obìnrin Chibok

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Inu ibanujẹ lọpọ awọn obi ọmọ Obìnrin Chibok wa

Àwọn òbí àwọn ọmọ akẹkọ obìnrin Chibok ti boko-haram ji gbé ti figbe síta pé àwọn ní ìròyìn tó dájú wí pé metadinlogota nínú àwọn ọmọ obinrin Chibok lo wà ní àríwá orílèèdè Cameroon.

Wọn ni Obìnrin kàn láran awọn tí boko-haram ji gbé to ribi sá mọ wọn lọwọ l'agbegbe ibẹ ló jẹri sí wí pé lootọ ní àwọn ọmọ obinrin náà wà lahamọ níbẹ.

Wọn ṣàlàyé pé o sọfun awọn pe abúlé Garin Magaji ati Garin Mallam ní Marwa lariwa Cameroon ní àwọn ọmọ náà wà.

Obinrin ohun ní ọpọ nínú wọn ló tí lọkọ ti wọn sì ti bímọ.

Àkọlé fídíò,

Boko Haram yóò dá Leah sílé

Alága ẹgbẹ́ àwọn òbí ọmọbinrin Chibok tí wọn jigbe ṣàlàyé fún BBC pé àwọn gbà obinrin náà gbọ nitoripe o juwe àwọn ọmọ àwọn yékéyéké.

Yakubu Nkekeso ni obinrin naa sọ wi pe nnkan ko rọgbọ lawọn abule ti awọn ọmọ naa wa ti wọn si fẹ le ma ri ounjẹ jẹ nibẹ.

Méjìléláàdọ́fà ninu ọ̀rìnlénígba din mẹrin awọn ọmọbinrin naa ti wọn jigbe ni wọn ko mọ ibi ti wọn wa bayi.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Boko Haram ta taba cewa ta musuluntar da 'yan matan wadanda mafi yawansu Kiristoci ne

Ijinigbe wọn lọdun 2014 mu ki awọn eeyan jankanjankan kaakiri agbaye pe fun itusilẹ wọn.

Ninu wọn la ti ri iyawo Aarẹ Amerika ana Michelle Obama.