Buhari, Saraki, PDP, Obaseki àti àwọn èèkàn ṣelédè lẹ́yìn Anenih

tony Anenih

Oríṣun àwòrán, @PDPOFFICIAL

Àkọlé àwòrán,

Anenih rèwàlẹ̀ àsà lẹ́ni ọdún 85

Alága ìgbìmọ̀ aláṣẹ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party (PDP) nígbà kan rí, Olóyè Tony Anenih tó rèwàlẹ̀ àsà lẹ́ni ọdún márùndínláàdọ́rùn ní àwọn èèkan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tí ń ṣelédè lẹ́yìn rẹ̀.

Anenih, ti wọn ló ṣàìsàn fún ìgbà díẹ̀ ló kú sí ilé ìwòsàn Cedar Crest l'Abuja.

Ààrẹ Muhammadu Buhari fí ọ̀rọ̀ ìbánikédùn rẹ̀ ránṣẹ́ sí àwọn ẹbí Anenih pẹ̀lú ìjẹ́rìí pé Anenih ló ayé rẹ̀ láti sin Nàìjìríà.

Buhari to fí ìwé ìkíni sọ́wọ́ nínú àtèjáde kan ti olùbádàmọ̀ràn rẹ̀ lóri ìròyìn, Femi Adesina fọ́wọ́sí ní adarí tòótọ́ ní Anenih tó sì ti kó àwọn ipa ribiribi nínú ètò òṣelú orílẹ̀-èdè Nàìjiríà

Àkọlé fídíò,

Mike Ifabunmi: Òrìṣà ló gbè wà jù ni Brazil

Àwọn míì náà n dárò Anenih pé:

Ààrẹ ìlé-ìgbìmọ̀ àṣòfin Bukola Saraki, ìgbákejì rẹ̀, Ike Ekweremadu náà bá àwọn ìdílé Anenih kẹ́dùn lásìkò tí Saraki ń sọ̀rọ̀ lórí ikú Anenih láti ori ìfọ̀rọ̀ ránṣẹ́ rẹ̀ lórí ayélujára rẹ̀.

O sàlàyé pé àwọn yóò sàfẹ́rí Anenih púpọ̀ nírú àsìkò yìí.

Nínú ìkíni tirẹ̀ ìgbákejì ààrẹ ilé ìgbìmọ aṣòfin gbóríyìn fún Anenih to sì bá àwọn ẹbí rẹ̀ kẹ́dùn ẹni ire tó ti lọ, ó sàlàyé pé Anenih ṣe ìwọn to lè ṣe lórí ètò òṣèlú orílẹ̀-èdè yìí.

Ìtàn ìgbésí ayé Anenih ni ṣókí:

A bí Anenih ní inú oṣù kẹjọ ọdún 1933, ní Uzenema-Arue, Uromi, ó wọ iṣẹ́ ọlọpàá Nàìjíríà ní ọdún 1951 ní ìpínlẹ̀ Benin.

Ó lọ kọ́lẹ̀jì ọlọpàá ní Ikẹja níbí ti wọn ti yàn-án fún ìtẹ̀síwajú ẹkọ rẹ̀ ní Bramshilll Police College ní Basingstoke, England ní 1966 àti International Police Academy, Washionton DC ní 1970.

Ó ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ bíi ẹṣọ̀ Gómìnà àkọkọ lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún Dokita Nnamdi Azikiwe.

Ó jẹ́ àlága ìpínlẹ̀ National Party of Nigeria láàrín 1981 sí 1983.

Oun ní alága ẹgbẹ́ òṣèlú Social Democratic Party láti ọdún 1992 sí ọdún 1993 àti ọmọ ìgbìmọ tó rí si ètò òfin lọdún 1994

Anenih darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Movement èyí ti ọgágun Musa Yar'Adua dá sílẹ̀

Lẹ́yìn náà ló darapọ̀ mọ Peoples Democratic Party tó tún jẹ mínísítà lásìkò ààrẹ Olusegun Obasanjọ.

Àkọlé fídíò,

Túnbọ̀sún Ọládàpọ̀: Òǹkọrin ni etí Ọba láti sọ òdodo