Operation Velvet: Ilé ẹjọ́ alágbéèká bẹ̀rẹ̀ láti fìyà jẹ́ awakọ̀ tó bá rúfin

Operation Velvet: Ilé ẹjọ́ alágbéèká bẹ̀rẹ̀ láti fìyà jẹ́ awakọ̀ tó bá rúfin

Operation Velvet jẹ́ akitiyan iléèṣẹ́ ọlọ́pàá, FRSC, LASTMA, ati VIO láti maa yẹ iwe ọkọ̀, ìwé ìrìnnà awakọ̀ wò.

Alukoro àjọ ẹ̀ṣọ́ aláàbò lójúpópó ní ìpínlẹ̀ Eko, Morakinyọ Ọlalekan ṣàlàyé fún BBC pé ètò nàá wà láti tún maa ṣe àyẹ̀wò ipò tí ọkọ̀ wà, kó tó di wí pé wọ́n gbe e sójú pópó.

Tó fi mọ́ fífi ojú àwọn awakọ̀ tó bá rú òfin ìrìnnà, ba ilé ẹjọ́ alágbèéká láàrin ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹwàá sí ọjọ́ kẹta, oṣù Kọkànlá, ọdún 2018.