PDP: Lọgan ní a máa fún Ambode ni tíkẹ̀ẹ̀tì Gómìnà to ba dárapọmọ́ wà

SANWOLU, TINUBU ati Ambode

Oríṣun àwòrán, Idowu-Sowunmi

Àkọlé àwòrán,

O jọ bi igba pe aawọ laarin Gomina Ambode ati Asiwaju Tinubu ti pari

'Iwọ sáà tí sọ pé o fẹ tikẹẹti gómìnà labẹ ẹgbẹ́ òṣèlú wà, kíá làá fí fún ọ.'

Ọrọ ìdánilójú rè láti ọdọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP sí gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó Akinwunmi Ambode.

Agbẹnusọ ẹgbẹ PDP nílu Èkó Taofiq Gani ló lédè ọrọ yí nígbà tí o n ba BBC sọrọ nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kàn lọ́jọ́ Ajé.

Taofiq ní òṣèlú lọrọ to wa nilẹ yí ati wí pé ẹgbẹ́ àwọn n na ọwọ sí gbogbo àwọn tí ẹgbẹ òṣèlú APC dojú tí nílu Èkó.

''Ti Ambode ba wa bawa lóni ti a sì ṣẹ àgbéyẹ̀wò ti a ri wí pé tọ́kàn tókàn ló fi fẹ dárapọ mọ́ wà, a lè gbà wọlé. Awa kò ní Oludije bíi o ba o pa kánkan. Ìlọsíwájú ẹgbẹ́ ló jẹ wá lógún''

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Gomina Ambode ko ti ṣọrọ lori nnkan ti PDP sọ

Labẹ òfin ètò ìdìbò, anfààní ṣì wà fún ẹgbẹ́ òṣèlú láti parọ orúkọ oludije kí gbedeke ọjọ ti INEC fi sílẹ tó pé

Ohùn tá gbọ ní pé Gómìnà Ambode ti n palẹmo láti kẹrú rẹ kúrò ní Alausa lẹyìn tí ọ pàdánù tikẹti ẹgbẹ́ APC lati du ipo Gomina lọdun 2019.

Àkọlé fídíò,

Ko sọna ni APC ati PDP

Àkọlé fídíò,

Kola Ologbodiyan: Jẹgudu jẹra ni ijọba APC

Gani ṣo pe àwọn yóò gba ìlú ati ijo tí Ambode ba fí lè dára pọ mọ PDP nitori o ṣíṣe ríbi ríbi nílu Èkó gẹgẹ bí Gómìnà

Alága ẹgbẹ PDP náà tún sọ fún BBC pé àwọn olóṣèlú ẹgbẹ́ APC tí ọ n fapajanu kan tí n ṣé ìpàdé bonkẹlẹ pẹlú àwọn.

Gómìnà Ambode ti ọrọ náà kan ko tí fèsì sí ọrọ yí.

Oríṣun àwòrán, Idowu-Sowunmi

Àkọlé àwòrán,

Opo igba ni Gomina Ambode ti so pe itẹsiwaju ẹgbẹ APC lo jọ oun loju

Àkọlé fídíò,

Iwode fun Ochanya ti won ba lopo waye nilu Eko