#Queen Dihya: Obinrin tó gbógun tàwọn agbésùnmọ̀mí ni Algeria

#Queen Dihya: Obinrin tó gbógun tàwọn agbésùnmọ̀mí ni Algeria

Asiko tijọba Roomu àti Byzatine n yipada ni akọni obinrin yii jade sita.

Obabinrin Dihya gbèjà àwọn eniyan Algeria lai nani pe obinrin ni oun lasiko ti awujọ ko tii maa foju alakikanju wo ọmọbinrin.

O koju awọn musulumi agbesunmọmi to n gbogun ti awọn eniyan rẹ.

Bayii o ti di awokọṣe obinrin ti awọn eniyan Algeria n ya aworan rẹ kaakiri ogiri ni gbangba ti wọn si ti sami ayẹyẹ ọdun rẹ nipa ere oniṣe lati ọdun 2003.

Awọn akikanju obinrin bii Obabinrin Idia, Mary Slessor, Efunṣetan Aniwura, Iyalode Ẹfunroye Tinubu, ati bẹẹ bẹẹ lọ lo ti jà fún ominira àwọn eniyan wọn lati ọdun pipẹ sẹyin.