Adetoun Ogunṣẹyẹ: ìrìnàjò ẹ̀kọ́ mi títí dé òkè kò rọrùn rárá!

Adetoun Ogunṣẹyẹ: ìrìnàjò ẹ̀kọ́ mi títí dé òkè kò rọrùn rárá!

Ogunṣẹyẹ ròyìn ipa ti òbí rẹ̀ kó lórí ẹ̀kọ́ rẹ́ kó tó báa dé obìnrin àkọ́kọ́ ní Nàìjíríà.

Ẹ̀kọ́ ìwé fún ọmọbinrin ti n di itẹwọgba kariaye ṣugbọn iṣẹ ṣi pọ lati ṣe lori ilanilọyẹ fawọn òbí ọmọbinrin nilẹ Adulawọ.

Ọjọgbọn Adetoun Ogunṣẹyẹ to jẹ obinrin akọkọ to gboye ọjọgbọn ninu iṣẹ akadá ni Naijiria ba BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ lori ìrírí rẹ̀ lati ibẹrẹ.

O ni ko dẹrun rara lati figa gbaga pẹlu awọn ọkunrin nigba naa pẹlu bó ṣe jẹ pé iyara ikawe ni oun maa n wa nigba gbogbo.

Ọjọgbọn ti a bi lọdun 1926 yii mẹnuba bi ẹ̀kọ́ ṣe bẹrẹ ni Fasiti akọkọ ni Naijiria,iyén fasiti ọlọ́gbà-ẹranko nibi ti sánmọ́ntì gbé dunlẹ̀ ni Ibadan.

Adetoun ni àwọn ọmọbinrin marun un péré lo wa ninu ọgọrun un akẹkọọ ti wọn fi bẹrẹ fasiti naa to si jẹ pé oun nikan lobinrin nile iwe girama ti oun lọ.

O sọrọ lori iṣoro aisi aaye fun omobinrin lasiko naa ninu iṣẹ iwe kika nitori pe ọpọlọpọ awọn akẹkọọkunrin ti oun ti kọ sẹyin di ọjọgbọn ṣaaju òun.

Bayii, oju ti ń là pé kò si ọmo ti kò dara, atọkunrin atobinrin ló le di àjítan'náwò ti a ba ti kọ wọn ni ẹ̀kọ́ iwe ati ti ọmọluwabi.

Ẹ jẹ ki a da ọmọ pọ̀ tọ́ ni takọ-tabo ki itẹsiwaju ọmọbinrin naa le rọrun ju ti atẹyinwa lọ nitori pé 'gbogbo lọmọ'.

Àwọn kan tilẹ gbà pé ọmọbinrin lo maa n saaba tọju obi nigba ti àgba ba de lọjọ alẹ́.