#Fake News: Irọ́ ni! Ọmọ ọdọ̀ Ọpẹ Bademosi kò kú

Ope bademosi/facebook.com

Oríṣun àwòrán, Ope bademosi/facebook.com

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọlọpàá sọ wípé ọmọ̀ ọ̀dọ̀ Sunday Adefonou Anani ti jẹ́wọ́ pé òun ló pa ọ̀ga rẹ̀, Ọpẹ Bademọsi, tó wà nínú àwọran yìí

Ọgbà ẹ̀wọ̀n ti ilu Eko sọ pé irọ gbáà ni pe Sunday Anani tó jẹ́ ọmọ ọ̀dọ̀ tó ń dáná fún Oloye Ọpẹ Bademọsi ti gbẹ́mìí mì.

Nigbà tó bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀, agbẹnusọ fún ọgbà ẹ̀wọ̀n ìpínlẹ̀ Eko, Rotimi Oladokun ni kò sí ẹyọ òótọ́ kankan nínú ìròyìn òfégè tí àwọn ilé iṣẹ́ ìròyìn kan ń gbé jáde pé ọmọ ọ̀dọ̀ náà ti kú.

Oloye Ọpẹ Bademọsi tí wọn sọ pe ọmọ ọdọ rẹ ẹ gun pa lagbegbe Ikoyi ni ipinlẹ Eko laipẹ yii ti wọ kaa ilẹ lọ bayii.

Ọjọ Ẹti , ọjọ kẹtalelogun, osu Belu ni ẹbi, ara ati ojulumọ pejọ pọ ti wọn si sin oku oloye naa ni Ipinlẹ Ondo, tii ṣe ilu oloogbe naa.

Oríṣun àwòrán, LIB

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ondo ni olóògbé Bademosi

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ile ẹjọ fọmọ ọdọ satimọle

Ile ẹjọ Majisireti to wa ni agbegbe Igbosere nipinlẹ Eko ti paṣẹ pe ki Sunday Anani, wa ni ẹ̀wọ̀n fun ọgbọnjọ.

Wọn fi ẹsun kan Sunday pe ogun ọga rẹ, Ọpẹ Bademọsi pa lasiko to fẹ ja oloogbe l'ole nile rẹ to wa ni Ikoyi nipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò,

Wọ́n rò pé mo ya wèrè ni Saudi lẹ́yìn ikú ọkọ mi

Iwe iroyin Punch jabọ pe ẹni to n rojọ tako Sunday, J.I. Eboseremene, bẹbẹ pe ki Onidajọ O.O Ọshin gba ki ẹni ti wọn fi ẹsun kan an wa ni ọgba ẹwọn fun bi oṣu kan, lati le faaye gba iwadi to munadoko.

Wọn ti wa sun igbẹjọ si ọjọ kejidinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2018.

'Ọmọ ọdọ Ọpẹ Bademọsi jẹwọ pe oun l'oun pa ọga oun'

Ọmọ ọdọ to n da ina ounjẹ fun Oloye Ọpe Bademosi ti jẹwọ wi pe oun lo pa ọga rẹ lẹyin to jaa lo le.

Ile isẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Eko lo fi eyi lede ninu atẹjade kan pe afurasi naa ti orukọ rẹ n jẹ Sunday Adefonou Anani jẹwọ lẹyin ti ẹrọ ayaworan ikọkọ(CCTV) fihan wi pe oun lo pa ọga rẹ.

Oríṣun àwòrán, LIB

Àkọlé àwòrán,

Ọmọ ọ̀dọ̀ ni wọ́n fi ẹ̀sùn kàn pé ó pa Oloye Bademosi

Gẹgẹbi ọrọ afurasi naa, lẹyin ọjọ kẹta ti wọn gba a si ibisẹ ni o pinu lati ja ọga re lole, ti o si wo ibusun ti ọga rẹ lati bere owo lọwọ rẹ, lẹyin ti iyawo rẹ jade kuro ni ile laarọ kutu, amọ ti o sọ wi pe oun koni owo nile lati fun ọmọ ọdọ naa.

Oríṣun àwòrán, Facebook

Àkọlé àwòrán,

Ilé isẹ́ ọlọ́pàá ní ìpínlẹ̀ Èkó ní Sunday Adefonou Anani jẹ́wọ́ lẹ́yìn tí ẹ̀rọ ìgbàlódé fihàn wí pé òun ló pa ọ̀gá rẹ̀.

Àkọlé fídíò,

Somalia: 'Wọ́n pàṣẹ fún mi láti dá Ramla dúró ká tò lè ṣe igbeyàwó'

Lẹyin naa ni ọmọ̀ ọdọ naa sọ ọga rẹ mọ igi ibusun, ko to di wi pe ọga naa gbiyanju lati gba ara rẹ silẹ, eleyi ti o jasi iku, lẹyin ti o gun ọga rẹ lọna mẹta.

Kọmisọnna Ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Edgal Imohimi, dupẹ lọwọ awọn ara ilu fun suuru wọn ati wi pe wọn yoo gbe ọmọ ọdọ naa lo si ile ẹjọ laipẹ.Ondo: 'Kò sẹlẹ̀rí ní ìtàn Ondo ká fagilé ọdún Ekimogun'

Ajọ to n risi idagbasoke ilu Ondo ni ipinlẹ Ondo, ODC ti kede wi pe ọdun Ekimogun ko ni waye ni ọdun yii.

Alaga ipolongo fun ọdun Ekimoogun ti 2018, Alhaji Yemi Adewetan, labẹ asẹ Osemawe ti ilu Ondo, ti ba BBC Yoruba sọrọ lori igbese ti ko i tii waye naa lati ọdun mọkanlelọgbọn ti ọdun Ekimogun ti bẹrẹ.

Yemi Adewetan sọ pe iku Lotin ti ilu Ondo, Oloye Ope Bademosi lo fa a ti awọn fi fagile ọdun Ekimogun ti ọdun yii.

Ọdun Ekimogun jẹ ayẹyẹ asa ati igbelaruge ilu Ondo, ti tọmọde ati agba lati ilu okeere si ma n pejọ lati se ayẹyẹ yii.

Àkọlé fídíò,

Ìnú mi kìí dùn nígbà trí mo ń ṣiṣẹ́ ni bánkì tó ìgbà ti mo bẹ̀rẹ̀ mẹkáníìkì

Adewetan fikun wi pe ibanujẹ ọkan lo jẹ fun awọn lẹyin isekupani Oloye Bademosi ni inu ile rẹ ni ilu Eko , ati wi pe ọna lati daa lọla ni awọn ṣe fagile ọdun naa.

Ninu ọrọ rẹ, Oloye Bademosi jẹ ọkan googi lara awọn to kọkọ bẹrẹ ọdun naa ni ọgbọn ọdun sẹyin.

Yemi Adewetan wa parọwa si awọn ọmọ bibi ilu Ondo lati fọwọwọnu lori bi wọn se fagile ọdun Ekimogun ti ọdun yii.

Bakan naa lo gbadura fawọn eniyan ilu Ondo loke okun pe, wọn a ko ire oko dele layọ ati pe Olodumare ko ni jẹ kiru eyi ṣẹlẹ mọ ni Ondo.

Oríṣun àwòrán, Femi Joseph

Àkọlé àwòrán,

Afurasí alásè gún ọ̀gá rẹ̀ pa

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọgbẹni Joseph sọ pe awọn ọlọpaa ti fi afurasi naa ranṣẹ si ilẹ iṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Eko nibi ti iṣẹlẹ naa ti ṣẹ.

Ibanujẹ nile Oloye Ọpẹ Bademọsi

Ibanujẹ nla gbaa ni iku Oloye Ọpẹ Bademọsi jẹ fun ẹbi ati ara bi wọn ṣe peju-pesẹ si ile olóògbé naa. Ikọ̀ BBC Yoruba ṣe àbẹ̀wò sí ilé Olóyè ìlú Ondo tí wọ́n furasí pé ọmọọ̀dọ̀ gún pa, fọ́fọ́ si ni ó kún fún àwọn abánikẹ́dùn.

Bi àwọn mọ̀lẹ́bí ṣe ń rẹ ìyàwò olóògbé lẹ́kún, bẹ́ẹ̀ ni awọn ọmọ olóògbé ń ṣe ìdárò rẹ̀.Awakọ oloogbe sọ fun BBC Yoruba pe ọjọ Aiku ni oun ati ọga oun mu afurasi alase naa to jẹ ọmọ orilẹede Togo,wa lati Ondo, ti wọn si fura si pe o gun ọga rẹ pa lọjọ kẹrin.

Àkọlé fídíò,

Ìjà ọlọ́pàá àti alápatà ni Bodija gbẹ̀mí Sulia aláìṣẹ̀ ni UCH

''A gbaa ko maa dana ounjẹ fun ẹbi, amọ oṣeni laanu pe a ko ṣayẹwo rẹ, ka to gbaa s'iṣẹ nitori pe a niloo rẹ ni kiakia."

Gẹgẹ bi awakọ naa ṣe sọ, Iyawo oloogbe lọ si ile ifowopamọ laarọ Ọjọru ti iṣẹlẹ yii ṣẹlẹ, lo fi jẹ wipe Oloye ati alase ti wọn furasi pe o pa oloogbe nikan ni o wa ninu ile.

Oríṣun àwòrán, Ope bademosi/facebook.com

Àkọlé àwòrán,

Àwọn ọlọpàá sọ wípé ọmọ̀ ọ̀dọ̀ Sunday Adefonou Anani ti jẹ́wọ́ pé òun ló pa ọ̀ga rẹ̀, Ọpẹ Bademọsi, tó wà nínú àwọran yìí

Nigba ti iyawo oloogbe dele ti ori Oloye ninu agbara ẹjẹ ti wọn ti gun pa, ni o kigbe sita. Awakọ naa sọ ọ di mimọ wipe kete ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ni oun ti pe awọn ọlọpa ni ẹka ti Yaba ni Ondo.

Ọwọ wọn si ti tẹ awọn ọmọkunrin to mu alase naa wa fun oloogbe Bademusi.

Àkọlé àwòrán,

Àwọn èèyàn ń lọ ṣàbẹ̀wò sí àwọn mọlẹ́bí olóògbé náà

Bakan naa, awọn agbofinro si ti mu ẹgbọn-kunrin afurasi ọhun. Awọn abanikẹdun si ti n bọwọlu iwe iforukọsilẹ ikẹdun nile Oloogbe to wa ni agbegbe Park view, Ikoyi niluu Eko.

Nigba aye rẹ, oun ni Alaga ileesẹ CreditSwitch Technology, to wa nilu Eko.

Àkọlé àwòrán,

Awọn abanikẹdun si ti n bọwọlu iwe iforukọsilẹ ikẹdun nile Oloogbe to wa ni agbegbe Park view, Ikoyi niluu Eko.

Nigba t'oun naa fidi iṣẹlẹ naa mulẹ fun BBC, Akọwe agba fun ẹgbẹ Ondo Development Committee, Alufa Damilọla Akinwale, sọ pe awakọ Oloye Bademọsi lo pe ọọfisi ileeṣẹ naa ni owurọ Ọjọru pe ọga oun ti ku. Ati pe alase to ṣẹṣẹ gba sile lo ṣeku paa.

Ohun ti a tun gbọ ni pe alase ti o n ba oloogbe naa ṣiṣẹ tẹlẹ lo ṣe eto bi alase tuntun naa ṣe darapọ mọ awọn oṣiṣẹ abẹle fun oloogbe Ọpẹ Bademọsi.

Ipe wa si alukoro ileeṣẹ ọlọpa nipinlẹ Eko, Chike Oti, lati fidi iṣẹẹ naa mulẹ, ko ti i so eso rere, pẹlu bi o ṣe ṣeleri lati kan si akọroyin wa to pe e.

Sugbọn a gbọ pe oṣiṣẹ alaabo to n sọ ile naa, to jẹ pe ọjọ kan naa l'oun ati alase ọhun jọ bẹrẹ iṣẹ lọjọ kan naa, ti wa lagọ ọlọpa lori ọrọ naa.

Bakan naa la gbọ pe wọn ko mọ ile tabi ọna alase ọhun to ti salọ bayii.