Bolanle Ninalowo: Fíìmù àkọ́kọ́ mi ló jẹ́ ẹṣin iwájú fún mi báyìí

Bolanle Ninalowo: Fíìmù àkọ́kọ́ mi ló jẹ́ ẹṣin iwájú fún mi báyìí

Gbájúgbajà ni Bolanle Ninalowo, lóòtọ́ kò pẹ́ tó bẹ̀rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òṣèré Yollywood, inú rẹ̀ dún bí ó ṣe ti m'ókè.

Ninalowo jẹ́ ọmọ bíbí Ikorodu ní ìpínlẹ Eko.

Ó gbé ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún ọdún mẹ́ẹ̀dógùn kó tó kó lọ sí Chicago ni orílẹ̀-èdè America níbi tí ó tún gbé fún ọdún mẹ́ẹ̀dógún mìíràn.

Bẹẹ ori lo mọ iṣẹ aṣela ni ọrọ eniyan ri, onikaluku kan n gbiyanju ni

Oríṣun àwòrán, @iamnino_b

Àkọlé àwòrán,

Bolanle Ninalowo

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Yàtọ̀ fún eré tíátà, ó tún ní ilé iṣẹ́ ọkọ̀ títà léyìí tó jẹ́ òwò ìdílé rẹ̀.

Bàbá rẹ̀ ti fi gbogbo ìgbà jẹ́ oníṣòwò ọkọ̀ òun sì ló fi iṣẹ́ náà lé òun àtàwọn ọmọ ìyà rẹ̀ lọ́wọ́.

Bolanle Ninalowo ti gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì ẹ̀yẹ látàrí ìjáfáfá rẹ̀ nínú iṣẹ́ tíátà.

Oríṣun àwòrán, @Ninalowoofficial

Àkọlé àwòrán,

Bolanle Ninalowo: Fíìmù àkọ́kọ́ mi ló jẹ́ ẹṣin iwájú fún mi báyìí

Bolanle gba awọn ọdọ Naijiria ní imọran pẹ ki wọn tẹpa mọ iṣẹ ki wọn ma sọ ireti nu ti ọwọ wọn ko bai tii tẹ ohun ti wọn n le pa.