Taa ni Haleemat Busari tí yóò ṣe igbákejì Jimi Agbaje?

Haleemat Busari ti ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ aladani gẹgẹ bi amofin ati onimọ nipa okoowo.

Oríṣun àwòrán, @Jimi

Àkọlé àwòrán,

Haleemat Busari ti ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ aladani gẹgẹ bi amofin ati onimọ nipa okoowo.

Wọn bi Haleemat Yemisi Busari l'ọdun 1964 sinu idile Oloogbe Ahmed Giwa ati Oloogbe Mujibat Giwa, to jẹ ọmọọbabinrin Kosọkọ ti Isalẹ Eko.

O lọ sileewe alakọbẹẹrẹ nipinlẹ Eko, o si kẹkọ gboye imọ ijinlẹ ninu ede Gẹẹsi ni fasiti Ilọrin l'ọdun 1986. Lẹyin naa lo gboye ninu imọ ofin ni fasiti ilu Eko 1990.

O bẹrẹ iṣẹ amofin l'ọdun 1992.

Àkọlé fídíò,

Bọlanle Aliyu: N kò nílò bàbá ìsàlẹ̀ láti di gómìnà

Yatọ si wi pe o jẹ amofin, o tun kẹkọ gboye nipa òwò ṣiṣe lati ileewe ikọsẹ nipa okoowo, Lagos Business School, ni nkan bi ọdun 2005.

O ti ṣiṣẹ pẹlu awọn ileeṣẹ aladani gẹgẹ bi amofin ati onimọ nipa okoowo.

Lọwọlọwọ, o jẹ oludari ni ẹka banki nla kan ni Naijiria, to wa ni orilẹede Sierra Leone.

Lẹyin ti Jimi Agbaje kede rẹ gẹgẹ bi igbakeji rẹ ti wọn yoo jọ dije fun ipo gomina ipinlẹ Eko l'ọdun 2019, ni Busari fesi si yiyan ti wọn yan an.

Ninu ikede kan to fi sita loju opo Twitter rẹ o sọ pe ''ko si ohun to to ipe lati ṣiṣe iṣẹ sin Ọlọrun, ati orilẹede. Ati wi pe oun ko ṣaimọ riri anfaani ti wọn fun un.

Àkọlé fídíò,

Adetoun Ogunṣẹyẹ: ìrìnàjò ẹ̀kọ́ mi títí dé òkè kò rọrùn rárá