Àwọn ìgbà tí àwọn ọmọ Ọbasanjọ ti takò ó ní gbangba

Obasanjo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Gbenga Ọbasanjọ fi ẹsun kan pe o n ba iyawo oun ni ibalopọ

O jẹ ohun ti ko wọpọ ki ọmọ tako baba tabi iya rẹ nilẹ Yoruba, nitori pe aṣa ati iṣe Yoruba gbagbọ pe obi ẹni jẹ ọlọrun kekere fun ni, ati pe ọmọ to ba gboju soke wo awọn obi rẹ n tapa si ọrun ara rẹ ni.

Sugbọn ninu idile aarẹ tẹlẹ fun Naijiria, Olusẹgun Ọbasanjọ, kiiṣe ẹẹkan tabi ẹẹmeji ni awọn ọmọ rẹ ti tako o tabi gbena woju rẹ ni gbangba.

Gbenga Ọbasanjọ fi ẹsun kan an pe o n ba iyawo oun lopọ

Igba akọkọ ni ti ọkan lara awọn ọmọ Ọbasanjọ gbena woju rẹ ni gbangba ni ọdun 2008.

Ọkan lara awọn ọmọ rẹ ọkunrin, Olugbenga Ọbasanjọ fi ẹsun kan baba rẹ ni gbangba pe o n ni ibalopọ pẹlu iyawo oun.

Gbenga fi ẹsun kan iyawo rẹ, Mojisola Olayemisi Amope, to jẹ ọmọ gbajugbaja oloselu, Ọtunba Alex Ọnabanjọ, pe oun ni ibalopọ pẹlu Ọbasanjọ lati le ri iṣẹ agbaṣe gba lọwọ ijọba.

Gbenga Ọbasanjo

Oríṣun àwòrán, Olugbenga O. Obasanjo/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Nile ẹjọ nibi ti Gbenga ati iyawo rẹ ti fẹ ẹ tu ara wọn ka lo ti fi ẹsun naa kan baba rẹ gẹgẹ bi ẹri l'ọdun 2008.

Ati pe baba oun san 'owo iṣẹ agbere'' fun iyawo oun nipa gbigbe ọpọlọpọ iṣẹ akanṣe fun ileeṣẹ rẹ, Bowen and Brown, nileeṣẹ to n mojuto ipese epo rọbi ni Naijiria, NNPC.

Nile ẹjọ nibi ti Gbenga ati iyawo rẹ ti fẹ tu ara wọn ka lo ti fi ẹsun naa kan baba rẹ gẹgẹ bi ẹri l'ọdun 2008.

Ìdáhùn Ọbasanjọ

Sáájú àbẹ̀wò Gbenga sí oko Olóyè Ọbasanjọ to n jẹ Otta Farm, ọfiisi Aarẹ ti y ara wọn kuro ninu oun ti Gbenga sọ eleyi to jẹ ki ọplọp ro wi pe lati ile iṣẹ Aarẹ lawn ọrọ rẹ ti ṣẹ wá.

Ninu atẹjade ile iṣẹ Aarẹ, wọn tẹnu mọ ọ pe itiju nla gbaa ni ọrọ ti Gbenga sọ o si buru jai.

Amin iyasọtọ kan

Dokita Iyabọ Ọbasanjọ naa gbena woju rẹ

Igba keji ni ti akọbi rẹ, Iyabọ Ọbasanjọ to ti figba kan jẹ kọmisana fun eto ilere ni ipinlẹ Ogun.

Iyabọ kọ lẹta gbọọrọ kan to pe ni 'Lẹta gbangba si baba mi.''

Àkọlé fídíò,

'Òṣìṣẹ́ Bánkì ni mí l'Amẹ́ríkà kí n tó bẹ̀rẹ̀ Tíátà'

Ninu lẹta ọhun to kọ, to si di kika ninu awọn iwe iroyin jakejado Naijiria, Iyabọ fi ẹsun wiwu iwa atobi ma ṣe e bawi, ti ki i gbọ imọran ẹlomii lori ohunkohun to ba fẹ ẹ ṣe.

Lẹta rẹ naa waye lẹyin ti Oloye Ọbasanjọ kọ lẹta kan si aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Goodluck Jonathan, lati bu ẹnu ẹtẹ lu iṣakoso rẹ.

Iyabọ Ọbasanjọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

O kọ lẹta naa lẹyin ti Ọbasanjọ kọ lẹta kan si aarẹ tẹlẹ ni Naijiria, Goodluck Jonathan, lati bu ẹnu ẹtẹ lu iṣakoso rẹ.

Iyabọ sapejuwe baba rẹ ninu lẹta naa to kọ l'ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kejila, ọdun 2013, sọ pe opurọ, ọlọgbọn ẹwẹ, ati alagabangebe, to fẹ wa ni iṣakoso titi lai.

Ati pe kii ṣe baba daada, nitori awọn ko jẹ anfaani rẹ gẹgẹ bi baba.

Lẹta Iyabọ ọhun fa awuyewuye ni asiko naa, ti ọpọlọpọ si n sọ pe 'lẹta ti iyabọ kọ ṣeeṣe ko jẹ apejuwe itẹlẹ idi ẹni, kii ri ni ti.''

Ìdáhùn Ọbasanjọ

Ẹwẹ, nkan bi ọdun kan lẹyin ti Iyabo kọ lẹta atẹjade rẹ si Ọbasanjọ, Aarẹ tẹlẹ ri, Olusgun Ọbasanjọ da esi pada si i to si fi ẹsun kan an pe ijọba Aarẹ Goodluck Jonathan lo kọ ọ si oun lati kọ lẹta naa.

Ninu awọn ọrọ t sọ lori iroyin kan, Ọbasanjọ ni wọn ti kilọ fun oun tẹlẹ pe ijọba Jonathan yoo kọ ọmọ oun obinrin meji lati ṣe iṣẹ idọti, oun si kilọ fun wọn.

Amin iyasọtọ kan

Juwọn Ọbasanjọ ṣatilẹyin fun Aarẹ Buhari ti baba rẹ tako

Juwon Obasanjo ati Buhari

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad

Eyi to tun n waye laipẹ yii ni ọmọ rẹ ọkunrin mii, Juwọn Ọbasanjọ, to n ṣatilẹyin fun Aarẹ Muhammadu Buhari lati dije fun saa keji.

Koda o ṣabẹwo si Aarẹ Buhari nile aarẹ to wa niluu Abuja lọjọ kinni, oṣu Kọkanla, ọdun 2018, lati jẹjẹ atilẹyin rẹ.

Saaju ni baba rẹ, Ọbasanjọ, ti bu ẹnu atẹ lu iṣakoso Buhari, to si gba a nimọran lati ma dije fun ipo fun igba keji.

Bakan naa ni Ọbasanjọ bu ọwọ lu oludije fun ipo aarẹ labẹ ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic Party, PDP, Atiku Abubakar.