Vibrator -Ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ mi ńpaná iṣẹ́ mọ́ mi lára'

Obìnrin pẹ̀lú àwòrán ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ nínú yin ojú rẹ̀ Image copyright Eve Lloyd Knight
Àkọlé àwòrán Ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ ti gbòde kan

Ọmọ ọdún mọ́kànlélógún ni Leanne nígbà tó kọ́kọ́ ra ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ rẹ̀ àkọ́kọ́.

O jẹ ohun didan gbiinrinn ti a ṣe latara kẹmika silikọọnu. O ni awọ okuta pẹlu bọtiini olododo goolu gẹgẹ bi o ṣe ṣalaye. Ko jọ nkan ọmọkunrin, o da yatọ, o dara gan ni.

O dagba ni abule lẹyin odi Birmingham, nilẹ England o ti da nikan wa fun ọdun meji nigba to wọ ọkọ oju irin lọ sinu igboro lọsan ọjọ abamẹta kan.

Lẹni ọdun mọkanlelogun, Leanne ko tii ṣe Leanne bi ẹni to fẹ ni ibalopọ ri rara.

"Ṣugbọn ọjọ lọjọ naa. Mo ti pinnu. Mo n lọ ra ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ ti mo ti n la ala rẹ tipẹ.

Wọn ti ja ibale rẹ lati ọdun kẹtadinlogun nigba ti yoo si fi pe ọdun mọkanlelogun, o ti ni ibalopọ pẹlu ọkunrin ti ko lonka sugbọn ajọṣepọ oun pẹlu gbogbo wn ko pẹ rara.

Ijakulẹ

O ti gbadun ibalopọ, sugbọn oriṣiriṣi ni iriri igbadun rẹ. "Mo gbadun bi mo ṣe maa n pade eniyan, bi mo ṣe maa n mu ara wọn wa lọna tabi ko jẹ awọn lo mu ara temi wa lọna.

Bó ṣe ń lọ ń dùn mọ mi ṣùgbọ́n mi ò kànlẹ̀ ní ìmọ̀lára ìtẹ́lọ̀rùn ìbálòpọ̀.

"Ó máa ń jẹ́ kí eré tó ṣáájú ìbálòpọ̀ ni mí lára", ó mí kanlẹ̀.

Bí ọdún ṣe ń gorí ọdún ni ìpòruru ọkàn m bá Leanne nítorí àìlè jí pépé imọ̀lára rẹ̀ fún ìbálòpọ̀.

"Gbogbo ìgbà tí mo bá ni ìbálòpọ̀ ni ọkàn mi máa ń bàjẹ́, mo máa ń dá ara mi lẹ́bi dípò ni ti mo bá lájọṣepọ̀. Mi ò fẹ́ sọ fún ẹnikẹ́ni nítorí àwọn ọ̀rẹ́ mi ma ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ bíi pé gbogbo ìgbà làwọn ma ń gbádùn ìbálòpọ̀.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Leanne kò gbádùn ìbálòpọ̀

Ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín, ó lahun sí ọ̀rẹ́ rẹ̀.

"Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni wí pé, nígbà náà mi ò tíì máa fi ojú ara ṣe bíi ẹni tó nílò ìbálòpọ̀". Inú ọ̀rẹ́ mi dùn pé, " lóòtọ́, oò tíì lè mọ níní ìmọ̀lára ìgbádùn ìbálòpọ̀ bí o kò bá tíì fi ojú ara ṣe bíi ẹni tó nílò ìbálòpọ̀ rí tí wàá ṣe bí ẹni ń bá ara rẹ̀ lájọṣepọ̀".

"Ìwọ́ ni wàá kọ́ ara rẹ láti dá a mọ̀ àti láti rẹra mọ́ ọ. bí o kò bá mọ bó ṣe ńrí, òó kàn máa tiraka lásán ni.

Ìgbádùn déé

Lọ́jọ́ àbámẹ́ta náà lọ́hun nílé, ó ṣí ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ rẹ̀ tuntun ló bá bẹ̀rl iṣẹ́.

"Ó gbà mí ní wakàtí kan ó lé kí n tó pàpà ní ìmọ̀lára kiní yìí... Ǹkan tí ara mi ma ń ṣe fúnra rẹ̀ láì nílò kí n rò ó tàbí mú u ṣiṣẹ́".

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀rẹ́ Léanne ní kó máa dá a ṣe pẹ̀lú ara rẹ̀.

Lákọ̀kọ́, ó run mí nínú kí afẹ́fẹ́ ìgbádùn tó fẹ́, ara mi wá ṣẹ̀'sẹ̀ balẹ̀, ọkàn mí wá tutù wẹ̀ẹ̀. Mo wá wò ó wí pé, ṣé èmi náà ni mò ń gbádùn eré ìbálòpọ̀ báyìí? Ó jẹ́ ìrírí ńlá.

Ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ ti ma ń ró kì lọ́kàn wa láti ìgbà ayé ọbabìnrin Victoria tí àwọn dókítà ṣe àgbéjáde rẹ̀ fún ìrànwọ́ àwọn obìnrin tí kò lè mára dúró.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán ìgbà ayé ọbabìnrin Victoria tí àwọn dókítà ṣe àgbéjáde rẹ̀ fún ìrànwọ́ àwọn obìnrin tí kò lè mára dúró

Ẹ̀rọ̀ fún fífẹ́ ìbálòpọ̀ gbogbo ìgbà

Ní ìgbà tí wọ́n rò wí pé béèyàn bá dé ìpele gbígbádùn ìbálòpọ̀ léè wò àìlèmáradúró.

Ó jẹ́ ohun ti Leanne ṣèrántí dáadáa: "Dájú dájú, inú mi kò dùn sùgbọ́n ọpẹ́ fún ìgbádùn ìbálòpọ̀.

Ìfilọ́ọ́lẹ̀ rẹ̀ lọ́dún 1980s ló sọ ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ di gbajúgbajà - ìrísí rẹ̀ jọ ti èkúte.

"Fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà, fẹ́lẹ́ fẹ́lẹ́ ni àwọn ǹkan ìseré ìbálòpọ̀ ma ń rí tojú ò sì leè rí i dáadáa" Stuart Nugent tó jẹ́ alámojútó àgbáyé ilé iṣẹ́ tó ń ṣe ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ ní orílẹ̀èdè Sweden, LELO sọ pé,

"Kò jẹ́ kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ máa ra ǹkan ìṣeré yìí. 'Sùgbọ́n bí ìrísí rẹ̀ ṣe wá rí bíi èkúte, ó fa ni mọ́ra ju àwọn ìṣeré ti ìṣájú lọ. Kódà lọ́dún 1998, ètò àgbéléwò 'Sex and the City' ya abala kan sọ́tọ̀ fún un láti kéde pé ó ti kúrò ní ǹkan ìṣeré lásán. Nìgbà bá bẹ̀rẹ̀ sí ní yípadà fún àwọn ènìyàn.

Mímú ara wà lọ́nà

Image copyright Eve Lloyd Knight
Àkọlé àwòrán Ó jẹ́ èèwọ̀ tẹ́lẹ̀ láti sọ̀rọ̀ ìgbádùn ìbálòpọ̀

Láàrin ọdún 2000 sí 2009, àwọn tó ń ṣe é bá bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe ẹ̀dà àti àwọ̀ oríṣiríṣi jáde. Ó ti wá sáre di ǹkan ìṣeré fún àgbàlagbà lọ́jà, ìrètí sì wà wí pé iye owó rẹ̀ yóò ju £22 billion ($29 billion) lọ títí ọdún 2020. Stuart s èyí nítorí wí pé wọn ti ń ṣe é jáde gkgẹ́ bí ohun èlò ìgbádùn. Ó ní láàrin ọdún márùn-ún sí mẹ́wàá, a ti di oníbarà tó ń fẹ́ ọjà ní mẹ́sàn-án mẹ́wàá.

"A ti wá mọ̀ nípa ǹkan ìgbàlódé à sì ń fẹ́ ohun tí yóò bá ìní wa pàdé gẹ́lẹ́ bó ti yẹ tó fi mọ̀ èyí tí à ń mú wọ inú yàrá.

Mímọ̀ ohun tó jọjú yìí ti wá dá oríṣiríṣi àti iye owó ọ̀tọ̀tọ̀ kalẹ̀. Ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ ń ṣiṣẹ́ bákan náa lára ni tẹ́lẹ̀ ṣùgbọ́n àwọn ilé iṣẹ́ ti ń wo onírúurú ìpele tí ara fi ń wà lọ́nà báyìí láti ṣe ọ̀tọ̀tọ̀.

Àwọn ojúlówó ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀, bí o bá ti gbé e lé ojú ara, yóò máamú ara rẹ wà lọ́nà láì kan ojú ara torí afẹ́fẹ́ ló ń lò kò si ni kanra.

Leanne sọ pé "ẹ̀gbẹ́ ibùsùn mi ni mo ma ń fi ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ mi sí ojoojúmọ́ sì ni mò ń lò ó". Ṣe ló dà bí ìgbésẹ̀ tó dára fún ìgbé ayé ìbálòpọ̀ mi".

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn tí wọ́n ń ṣe jáde nísisìyìí yàtọ̀ sí ojúlówó

Lẹ́yìn ọdún méje, ó ṣì ń lo ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ kan náà fún ìgbà díẹ̀ lọ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n níwọ̀n ìgbà tí ìfẹ́ bá ṣì wà níbẹ̀, ó ti bẹ̀rẹ̀ sí ni rò ó bóyá ó ń ṣèrànwọ́ fún ìgbádùn ìbálòpọ̀ rẹ̀ ní ọ̀nà mìíràn.

Ó ti pẹ́ ti mo ti mọ̀ wí pé mi ò lé gbádùn ìbálòpọ̀ tí mi ò bá lo ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ tó tọ́, kí n sì sun ìhà tí mo ti kọ́kọ́ wà.

Leanne ti wá pé ọmọ ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n báyìí pẹ̀lú ọ̀rẹ́ ìbálòpọ̀ rẹ̀ ọlọ́dún márùn-ún

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oríṣiríṣi ọ̀nà ni obìnrin fi lè gbádùn ìbálòpọ̀

Ṣé olólùfẹ́ mi fẹ́ràn rẹ̀ lásìkò ìbálòpọ̀ wa

Inú wọn máa ń dùn wọ́n sì ń gbádùn ìbálòpọ̀. Olólùfẹ́ mi kò bínú sí ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ mi, a ma ń lò ó nínú eré tó ṣáájú ìbálòpọ̀.

Lákọ̀kọ́, mo rò pé kò ni fẹ́ ẹ ni ṣùgbọ́n kò bínú sí i àyàfi ti pé mo máa fẹ́ gbádùn ìbálòpọ̀ lọ́nà mìíràn.

Pẹ̀lú gbogbo bí mo ṣe dán an wò nígbà tí a bá ń lájọṣepọ̀ tó wà níwájú mi, tí mo wà lórí rẹ̀ pẹ̀lú oríṣiríṣi ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀, mo ma ń sábà fẹ́ padà sí ọ̀rẹ́ mi àtijọ́.

Ó ń kọ mi lóminú pé mi ò lè ṣe láì lo ǹkan ìṣeré ìbálòpọ̀ mi. Ó ti kó sí mi lórí.

Image copyright iStock
Àkọlé àwòrán Àwọn ẹlòmíràn ò kí ń gbádùn ìbálòpọ̀ bí wọ́n ṣe fẹ́ pllú olólùfẹ́ wọn.