Pasuma: Mọ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlórun fún oríire ọjọ́ ìbí òní

Alabi Pasuma Image copyright Instagram
Àkọlé àwòrán Pasuma ní nínú gbogbo ìlú àgbáyé, òun kò lè lọ kọrin ní Saudi Arabia ko si iye owo tí wọ́n lè gbé sílẹ̀.

Gbajugbaja olorin Fuji ati osere tiata, Wasiu Alabi Pasuma ti ọpọ eniyan mọ si "Ọ̀gáńlá" ti dupẹ lọwọ Ọlọrun fun oriire ọjọ ibi ọdun mọkanlelaadọta loke eepẹ.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, Osu kọkanla, ọdun 1967 ni wọn bi Pasuma ni agbeegbe Mushin, ni Ipinlẹ Eko, ti o si dagba si ipinlẹ Kwara, lorilẹede Naijiria.

Ni oju opo ikansiraẹni Instagram rẹ ni Pasuma ti fi ero rẹ han wi pe gbogbo ilọsiwaju ati ibugbooro ti oun ti la kọja, Ọlọrun lo gbe oun leke.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Gbajugbaja olorin Fuji naa fikun ọrọ rẹ pe ijakunlẹ nigba miran maa n fihan wi pe, eniyan ẹlẹran ara ni oun, ati wi pe Ọlọrun nikan lo ju gbogbo ẹda lọ.

Ọkan lara awọn gbajugbaja elere tiata Yoruba, Dayo Amusa naa ba Pasuma yọ ayọ ọjọ ibi rẹ lori ẹrọ ikansiraẹni Instagram.

Ti a o ba gbagbe, lasiko to n ba BBC sọrọ lori Facebook Live, Pasuma sọ pe orilẹede Canada ni oun yoo ti se ayẹyẹ ọjọ ibi oun ti ọdun 2018.

Bakan naa, ni ọdun 2018 ni ilu Georgia, lorilẹede Amẹrika fun Pasuma ni iwe igbelu ọmọ onilẹ ati asoju ilẹ naa.

Awọn awo orin ti Wasiu Alabi Pasuma ti gbe jade

 • Ọga Nla
 • Ọmọ Butty
 • Iyale Ọkan
 • Mushini
 • Ọtunba Fuji
 • Ahọn Lẹgbon Ẹyin
 • Olorukọ topọ
 • Abẹgi Anu
 • Ability
 • Sabaka Night
 • Bus Stop to Bus Stop
 • So Far So Good

Àìrí nǹkan ṣe ló ń fa ìjà èmi àti Sàheed Oṣupa- Pasuma

Gbajugbaja olorin Fuji, Alhaji Wasiu Alabi ti ọpọ eeyan mọ si Pasuma ti ni ko si ohunkohun ti o lee mu ki oun gbe ode ere orin lọ si orilẹ-ede Saudi Arabia.

Ninu ọrọ rẹ pẹlu BBC news Yoruba ni ileeṣẹ rẹ nilu Eko ni Pasuma ti sọ ọrọ yii.

Image copyright @NigeriaNewsWeb
Àkọlé àwòrán Amọṣa, Pasuma ni ko si iye owo to lee mu oun lọ si Saudi Arabia lọ kọrin nitori 'ile adura ni'

Ọkan lara awọn ololufẹ Pasuma lo fi ibeere ṣọwọ si i lórí ètò Facebook Live pẹ̀lu Pasuma ni wi pe awọn n reti rẹ ni orilẹ-ede naa lati wa fi orin da awọn laraya nitori awọn n ri bira ti aṣiwaju elere fuji naa n da lara kaakiri awọn orilẹ-ede agbaye ati pe igba wo gan an lo n bọ wa kọrin ni Saudi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLábẹ́ odò! Ìgbéyawó yìí lárinrin

Amọṣa, Pasuma ni ko si iye owo to lee mu oun lọ si Saudi Arabia lọ kọrin nitori 'ile adura ni'

"A maa n wa gba adura ni Saudi Arabia ni. Ti a ba ti wá sí Saudi, a wa sin Ọlọrun ni. Ẹyin ti Saudi, ẹyin ti Jedah ẹ gbagba nnkan to n jẹ pe a wa kọrin o. Bi ẹgbẹ ba ti ri wà ni Saudi, mo wa ki anọbi Muhammad ni, mo wa rọgba yi Kaaba lati wa dupẹ ore ti Ọlọrun ṣe kí n si tun beere omiiran ni. Ilẹ mimọ ni"

Lori ajọṣepọ to wa laarin oun ati Gbajugbaja Olorin fuji miran, Saheed Oṣupa, Pasuma ni iṣẹ ti pọ lọwọ awọn bayii ju ki awọn mejeeji máa ta'hun orin sira.

"Ko si nnkan kan laarin wa. Emi le maa ro o bayii pe ko si wahala, mi o le gba ẹnu rẹ sọrọ pe ko si wahala. Sugbọn nitori pe o ti pẹ ti mo ti gbọ pe o sọrọ nipa Pasuma, iṣẹ ti pọ lọwọ rẹ bayii, ko s'aye. O ti to bi ọdun kan bayii ti a ti gbọ pe Saheed kọrin ba Pasuma tabi Pasuma kọrin ba Saheed. Iṣẹ ti pọ lọwọ awa mejeeji, ko si aye."O fi kun un pe igbaradi ti wa fun ṣiṣe ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mokanlelaadọta oun ni orilẹ-ede Canada.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kọkanla tii ṣe ọjọ ibi rẹ ni ayẹyẹ alujo náà yóò sì waye.