Òbìnrin mánigbàgbé mẹ́ta nínú ìjọba tiwantiwa láti 1999

Ngozi Okonjo-Iweala, Dora Akunyili, Oby Ezekwesili Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Lati igba ti orilẹede Naijiria ti pada si iṣejọba tiwantiwa, oniruru awọn obinrin lo ti sa ipa ti wọn

Lati ọdun 1999 ti orilẹede Naijiria ti pada si iṣejọba tiwantiwa, oniruru awọn obinrin lo ti ṣa ipa ti wọn ninu idagbasoke iṣejọba tiwantiwa ti gbogbo agbaye si mọ kale-kako.

Mẹta ninu wọn ree. Awọn obinrin ti ina orukọ wọn ko fi igba kan ku lati igba ti iṣejọba tiwantiwa ti bẹrẹ.

Ọjọgbọn Dora Akunyili

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Akunyili ku ni ọjọ keje oṣu kẹfa ọdun 2014 lẹyin to ba aisan jẹjẹrẹ finra fun ọpọlọpọ igba

Ọjọgbọn Dora Akunyili jẹ ọmọ ipinlẹ Anambra, ṣugbọn ilu Markurdi ni ipinlẹ Benue ni wọn bii si ni ọjọ kẹrinla oṣu keje, ọdun 1954.

Igba ti o di ilumọọka fun awọn ọmọ orrilẹede yii ni asiko ti aarẹ orilẹede nigba naa, Oluṣẹgun Ọbasanjọ yan an gẹgẹ bii oludari agba fun ajọ to n gbogun ti ilokulo ounjẹ, ohun mimu ati ogun lorilẹede Naijiria, NAFDAC laarin ọdun 2001 si 2008.

Aṣeyọri ti Ọjọgbọn Dora Akunyili ṣe lasiko naa kuro ni kekere nitori oun lo mu igba ọtun wọ eto gbigbogun ti ayederu oogun oloro lorilẹede Naijiria nigba naa. Koda awọn awujọ agbaye gbogbo ni wọn kan sara si fun iṣẹ takuntakun ti o ṣe nigba naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Dora Akunyili lo gbe eto Nigeria...good people, great nation jade fun atunṣe orukọ Naijiria

Labẹ iṣejọba aarẹ Naijiria ti o di oloogbe, Musa Yaradua ni wọn ti yan an gẹgẹ bii minisita fun eto iroyin ati ibanisọrọ lọdun 2008 si 2010.

Lasiko ti aarẹ Yaradua di oloogbe, ti igbakeji rẹ, Goodluck Jonathan si rọpo rẹ, yii gan an ni Dora Akunyili gbe akanṣe eto kan kalẹ to pe ni 'Re-branding Nigeria Project' fun atunṣe orukọ ati iyi orilẹede Naijiria.

Nigba naa ni o gbe akori, Nigeria...good people, great nation jade.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu idanilẹkọ kan ti o ṣe ni ilu Eko ni ibẹrẹ ọdun 2018, aarẹ ana Oluṣẹgun Ọbasanjọ ni, eeyan kan to gburo iwa olootọ Dora lasiko to fi wa ni ileewe kan ni ilẹ Gẹẹsi lo fi ọrọ rẹ to oun leti ti oun fi yan an.

Lẹyin ti o kuro ni ijọba, Ọjọgbọn Dora Akunyili wa lara awọn ti wọn yan fun igbimọ apero ti ijọba apaps gbe kalẹ fun agbeyẹwo ẹhonu awọn ẹya lorilẹede Naijiria.

Akunyili ku ni ọjọ keje oṣu kẹfa ọdun 2014 lẹyin to ba aisan jẹjẹrẹ finra fun ọpọlọpọ igba.

Ọjọgbọn Ngozi Okonjo-Iweala

Image copyright @NOIweala
Àkọlé àwòrán Ọkan lara awọn eekan to lagbara labẹ iṣejọba aarẹ Ọbasanjọ laarin ọdun 2003 si 2006 ni Okonjo-Iweala

Ọjọgbọn Ngozi Okonjo-Iweala jẹ minisita ijọba meji lorilẹede Naijiria-2003 si 2006 labẹ aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ, 2011 si 2015 labẹ iṣejọba aarẹ Goddluck Jonathan.

Banki agbaye ni Ọjọgbọn Ngozi Okonjo-Iweala ti n ṣiṣẹ ki aarẹ Oluṣẹgun Ọbasanjọ to pe e wa sile wa ṣe minisita fun eto iṣuna lorilẹede Naijiriaoun ni obinrin akskọ ti yoo ṣe minisita fun eto iṣuna ati minisita fun ọrọ ilẹ okeere lorilẹede Naijiria.

Image copyright @NOIweala
Àkọlé àwòrán Pupọ ọmọ orilede Naijiria ni ko ni gbagbe minisita 'alaṣọ ankara' yii pẹlu gele 'ipakọ o gbọ ṣuti' rẹ

Ọkan lara awọn eekan to lagbara labẹ iṣejọba aarẹ Ọbasanjọ laarin ọdun 2003 si 2006 ni Okonjo-Iweala, o si ko ipa ribiribi ninu bi awọn igbimọ orilẹede agba kan lagbaye ṣe wọgile gbese biliọnu mejidinlogun dọla, $18bn ti orilẹede Naijiria jẹ ṣaaju igba naa.

Pupọ ọmọ orilede Naijiria ni ko ni gbagbe minisita 'alaṣọ ankara' yii pẹlu gele 'ipakọ o gbọ ṣuti' rẹ.

Ọmọwe Obiageli "Oby" Ezekweseli

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ohun ti ọpọ awọn ọdọ mọ Obiageli Ezekwesili fun ni ipa rẹ gẹgẹ bii aṣiwaju ẹgbẹ #BringBackourGirls

Ohun ti ọpọ awọn ọdọ mọ Obiageli Ezekwesili fun ni ipa rẹ gẹgẹ bii aṣiwaju ẹgbẹ to n ja fun itusilẹ awọn akẹkọ ileewe giram kan ni Chibok ipinlẹ Borno, ti awọn ọmọogun Boko haram ji gbe ni ọdun 2014, #BringBackourGirls.

Bakan naa lo tun lewaju ẹgb kan to n ja fun ilana iṣejọba rere, 'Red Card'

Lara awọn ipo ti o ti di mu ninu iṣejọba orilẹede Naijiria lati igba ti saa iṣejọba tiwantiwa yii ti bẹrẹ ni amugbalẹgbẹ pataki fun aarẹ Ọbasanjọ lori amojuto iwe eto iṣuna, minisita fun ohun alumọni ati minisita feto ẹkọ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Oniruuru awọn aarẹ orilẹede Afirika ni o ti ṣiṣẹ fun gẹgẹ bii olubadamọran ptataki

Lasiko to fi jẹ minisita feto ẹkọ ni Oby, gẹgẹbi ọpọ ṣe maa n pe e, ṣe eto atunto ẹka eto ẹkọ lorilẹede Naijiria ninu eyi ti spọ awọn orilẹede Afirika mira ti ya lo bayii.

Oniruuru awọn aarẹ orilẹede Afirika ni o ti ṣiṣẹ fun gẹgẹ bii olubadamọran ptataki.

Nibayii, Ọmọwe Oby Ezekwesili ni oludije ipo arẹ fun ẹgbẹ oṣelu Allied Congress Party of Nigeria, ACPN fun idibo apapọ ọdun 2019 lorilẹede Naijiria.