Ìtàn Mánigbàgbé: Ọlabisi Ajala gun ọ̀kadà yíká àgbáyé, tó sì dé orílẹ̀-èdè 87

Olabisi Ajala Image copyright Keystone-France
Àkọlé àwòrán • Asọ iran Yoruba, taa mọ si Agbada ati Sokoto ni Ajala wọ lori kẹkẹ to fi rin yika agbaye

N jẹ ẹyin ti gbọ nipa ‘Ajala the Traveller’ tabi Ajala Travels’ ri?

Ọpọ eeyan lo maa n da asa nipa ẹnikan to rin irinajo afẹ yika gbogbo agbaye pẹlu alupupu lasan, taa mọ si Ọkada, ti wọn si maa n pe ẹni to ba n ti ilu kan si ekeji ni orukọ onitọun.

Ọmọ ilẹ kaarọ oojire ni ọkunrin to da ara yii, orukọ rẹ a si maa jẹ Moshood Ọlabisi Adisa Ajala, ti gbogbo eeyan mọ si Ajala Travels.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIreti Yusuf: Ìsòro àti fẹjọ́ sùn ló ń mú kí ìwà ìfipábánilòpọ̀ gbilẹ̀ si

Bi o tilẹ jẹ pe Ọlabisi Ajala ti fi ilẹ bora bii asọ, sibẹ o yẹ ki iran iwoyi mọ ohun kan tabi meji nipa rẹ nitori bi ọmọ ko ba ba itan, yoo ba arọba.

Awọn koko ohun to si yẹ kẹ mọ nipa Ajala, the Traveller ree:

 • Orilẹ-ede Ghana ni wọn bi si, amọ to lọ sile ẹkọ Baptist Academy nilu Eko ati Ibadan Boys‘ High School, ni orilẹ-ede Naijiria
 • Idile olobinrin pupọ lo ti wa, iyawo mẹrin ni baba rẹ ni, to si bi ọmọ mẹẹdọgbọn ọmọ
 • O lọ soke okun lẹni ọdun mejidinlogun lati kọ isegun oyinbo ko lee yi awọn ọmọ Naijiria lọkan pada nipa lilo oogun abẹnu gọngọ
 • Ọdun 1952 ni Ajala di ilu mọọka nigba to fi kẹkẹ lasan rin orilẹ-ede Amẹrika ja, eyi to toto ẹgbẹrun meji ati ọọdunrun maili nigba naa
 • Asọ iran Yoruba, taa mọ si Agbada ati Sokoto ni Ajala wọ lori kẹkẹ to fi rin yika agbaye, eyi to fẹ fi yi ero ọkan awọn alawọ funfun pada pe ihoho ni awọn alawọ dudu maa n rin tabi so ewe mọ ara
 • Irinajo agbaye ti Ajala se yii jẹ ko di gbaju-gbaja loke okun, ti wọn si n pe e sinu awọn ere Sinima bii White Witch Doctor, to si n jẹ orukọ Ọla nibẹ
 • Orilẹ-ede mẹtadinlaadọrun (87) ni Ajala fi ọkada de jake-jado agbaye laarin ọdun mẹfa
 • Awọn orilẹ-ede bii Israel, India, Australia, Iran, Russia, Ghana, Cyprus, Egypt ati bẹẹ bẹẹ lọ ni Ajala de, to si pade awọn eeyan nla-nla to fi mọ awọn olori orilẹ-ede naa
 • Aya pupọ ni Ajala ni, bo se fẹ dudu, lo fẹ pupa, koda o kọ ọmọ si oyinbo kan lọrun, eyi to di ọrọ ileẹjọ
 • Losu kẹta ọdun 1953 ni Ajala koju ẹsun iwe yiyi, ole jija ni ipinlẹ Califonia, eyi to ni oyinbo kan lo gba oun
 • Ajala lọ sẹwọn ọdun kan, ti wọn si di lapanyaka kuro ni orilẹ-ede Amẹrika, paapa nitori pe ko lọ si ile ẹkọ to wa fun mọ nilẹ Amẹrika
 • O gun ori opo ẹrọ alatagba to to ọgọrin ẹsẹ bata, to si n dunkoko pe oun yoo jabọ silẹ, eyi to fi n fi ẹhonu han tako bi wọn se le ni Amẹrika
 • O tun bẹrẹ si ni yan ounjẹ lodi lati fi ẹhonu han, lẹyin o rẹyin wọn gbe lọ si ilu London, ti wọn ko si gbe wa silẹ Naijiria mọ
 • Ajala pada si Amẹrika lọdun 1954 pẹlu aya rẹ alawọ funfun, Hermie Aileen amọ ti obinrin naa kọ silẹ lori ẹsun pe o n ko obinrin pupọ
 • Ọdun 1955 lo tun fẹ iyawo miran, ti se osere ori tẹlifisan, ẹni ọdun mọkandinlogun
 • Ajala pada si ilẹ Naijiria lẹyin ọpọ ọdun loke okun, o dagba, aisan rọlapa, rọlẹsẹ si mu, amọ ko si owo fun lati tọju ara rẹ
 • Ọjọ keji osu keji ọdun 1999 ni Ọlabisi Ajala ki aye pe o digbose nile iwosan ijọba to wa ni Ikẹja.

Bi o tilẹ jẹ pe Onirese Ọlabisi ọmọ Ajala ko fin igba mọ, amọ eyi to ti fin silẹ ko lee parun, nitori a ko tii ri eeyan miran to fi Ọkada rin yika agbaye mọ bii Ajala.

Ẹ jẹ ki awa naa sa ipa wa, lati fi ipa tiwa han lawujọ agbaye nitori arise ni arika, ohun ta ba si se ni oni, ọrọ itan ni yoo da, bo ba di ọla.