Olùkọ́ ni mí tẹ́lẹ̀, ebi ló sọ mí di awakẹ̀kẹ́ Márúwá - Grandma Maruwa
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Grandma Maruwa: Ó yẹ kí obìnrin sisẹ́ láì wojú ọkọ kó tó jẹun

Asamọ ọrọ kan lo ni, ‘isẹ ni isẹ n jẹ, ẹni to ba jale nikan lo ba ọmọ jẹ’.

Bẹẹ ni ọrọ ri pẹlu mama agba kan, Ọlayinka Ọnabanjọ, ti wọn n pe ni ‘Grandma Maruwa’, ẹni to jẹ akikanju obinrin to n wa Maruwa nilu Ibadan.

Lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, Grandma Maruwa ni, bo se n pẹ pupọ ki ijọba to san owo osu awọn olukọ, eyi to n mu ebi pa oun, lo ta oun ni idi kan lati dara pọ mọ ẹgbẹ awọn awakọ, ẹka ti Maruwa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O wa gba awọn obinrin nimọran lati mase maa woju ọkọ wọn, ki wọn to jẹun tori iwuri nla ni ti ọwọ meji ba n sisẹ.

Bakan naa lo tun rọ wọn lati wa isẹ se, ki wọn lee gbiyanju ipa tiwọn naa nidi eto ẹkọ awọn ọmọ wọn.