Minimum Wage: Buhari gbọdọ̀ fi àbá owó osù tuntun sọwọ́ sáwọn asòfin

Iwọde ẹgbẹ oṣiṣẹ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn gomina lawọn o le san ọgbọn ẹgbẹrun Naira f'oṣiṣẹ

Sẹnetọ Rafiu Ibrahim, to n ṣoju ẹkun idibo Guusu ipinlẹ Kwara salaye pe, ileeṣẹ aarẹ gbọdọ kọkọ fi aba ofin ranṣẹ sile aṣofin fun ayẹwo.

O sọ eyi lasiko ti BBC Yoruba kan si lori ilana ti owo oṣu tuntun naa yoo gba, ko to o di sisan.

Sẹnetọ Rafiu salaye pe, igba ti aba ofin naa ba de iwaju awọn asofin, ni wọn yoo ṣe ayẹwo rẹ finifini, lẹyin eyi ni wọn yoo ṣe atunse si ofin to nii ṣe pẹlu owo oṣu oṣiṣẹ ni Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGrandma Maruwa: Ó yẹ kí obìnrin sisẹ́ láì wojú ọkọ kó tó jẹun

O sọ pe, bi aarẹ Muhammadu Buhari ba ṣe tete gbe aba ofin naa wa siwaju wọn, ni yoo sọ igba ti yoo di ofin, ti owo oṣu naa yoo si bẹrẹ si ni jẹ sisan. Amọ ko sọ ni pato iye ọjọ, ọsẹ tabi oṣu ti ilana ọhun yoo gba wọn.

Sugbọn ṣa, pe ile aṣofin buwọlu aba owo osu naa, ko ti i tumọ si pe yoo di sisan, nitori pe ile asofin mejeeji gbọdọ fi ohun ṣọkan lori rẹ, ki wọn to o gbe pada si ọdọ aarẹ.

Image copyright Garba Shehu
Àkọlé àwòrán Aarẹ Buhari nigba ti o n gba abọ iwadi igbimọ to ṣiṣẹ lori ẹkunwo owo oṣu oṣiṣẹ

Bakan naa ni o tun ṣe pataki, ki awọn ijọba ipinlẹ gba lati mu ofin naa lo.

Idi ni pe ọpọlọpọ awọn ipinlẹ lo ti sọrọ sita lasiko ti awọn oṣiṣẹ n ja fun owo oṣu tuntun, pe awọn ko ni le san ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira ti ẹgbẹ oṣiṣẹ n beere fun, bi ko ṣe ẹgbẹrun mejilelogun ataabọ Naira ti agbara awọn ka.

Èrò ọmọ Nàíjíríà sọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lórí ₦30,000 owó osù òsìsẹ́

Awọn ọmọ Naijiria ti fesi si igbesẹ Aarẹ Muhammadu Buhari lati gbe aba owo osu tuntun naa lọ si Ile Igbimọ Asofin lẹyin to tẹwọgba àbá ẹkunwo owó oṣù òṣìṣẹ́ ti igbimo naa gbe kalẹ.

Aarẹ Buhari sọ nipa igbese naa lẹyin ti ẹgbẹ́ òṣìṣẹ́ NLC fagile ìyansẹ́lódì ti wọn fẹ gunle ní Ọjọ́ Ìṣẹ́gun láti bèèrè fún àfikún owo oṣù òsìsẹ́ ní Naijiria.

Lara awọn ọmọ Naijiria to fesi si igbesẹ aarẹ naa gboriyin fun aarẹ Buhari nigbati awọn miran bu ẹnu atẹ lu pe ọna miran lati fa ẹkunwo owo osu sisan naa gun ni Aarẹ Buhari dawọ le.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGrandma Maruwa: Ó yẹ kí obìnrin sisẹ́ láì wojú ọkọ kó tó jẹun

John Agbaja sọ wi pe oun ni gbagbọ ninu Aarẹ Buhari lati sa ipa rẹ ki irọrun o le de ba awọn osisẹ lorilẹede Naijiria.

Amọ awọn miran parọwa si ẹgbẹ osisẹ lorilẹede Naijiria lati mọkanle nitori ọna ni yii lati ri wi pe won ko se ekunwo owo osu awọn osisẹ naa lasiko to tọ ati eyi to yẹ.

Àkọlé àwòrán Àwọn ọmọ Naijiria fèsì sí gbèǹdéke owó osú tí Ààrẹ buwọ́lù

Abubakar Musa nigba to n fesi si igbesẹ naa rọ awọn ọmọ Naijiria lati ri wi pe wọn fọwọsowọpọ pẹlu Aarẹ Buhari lati mu idagbasoke ba orilẹede Naijria.

Ààrẹ Buhari tẹ́wọ́gba àbá lórí ẹ̀kúnwó owó oṣù òṣìṣẹ́

Ìròyìn tó ń tẹ̀ wa lọ́wọ́ sọ pé Ààrẹ orileede Naijiria Muhammadu Buhari ti tẹwọgba àbá ẹkunwo owó oṣù òṣìṣẹ́ ti igbimọ to ṣiṣe lori rẹ jabọ fun un l'Abuja.

Nigba ti o n gba abọ iwadi naa ti olori igbimọ ọhun Amal Pepple gbe fun un, Aarẹ Buhari ni oun yoo ṣa agbara oun lati ri wi pe ilé aṣòfin mú ayípadà bá owó oṣù ti àwọn òṣìṣẹ́ n gba.

Agbẹnusọ ile iṣẹ Aarẹ Garba Shehu fi ẹkunrẹrẹ alaye ohun ti Aarẹ Buhari sọ nibi to ti tẹwọgba aba naa lede loju opo Twitter rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionASUU Strike: Bí àwọn kan se dunnú, làwọn kan fajúro

Ninu atẹjade naa Aarẹ Buhari ko sọ pato boya oun yoo buwọlu ẹgbẹrun lọna ọgbọn Naira ti awọn oṣiṣẹ n bere fun.

Sugbọn o fi ifarajin rẹ han lati fi abadofin lori ẹkunwo oṣiṣẹ rinlẹ lọjọ waju.

Image copyright @GarShehu

O ni bi ijọba ti n ṣe agbeyẹwo aba yi, oun rọ awọn oṣisẹ ati awọn asaaju wọn lati ṣe suuru di ọṣẹ to n bọ.

Image copyright @GarShehu
Àkọlé àwòrán Ero ọkan ọpọ ọmọ Naijiria ni wi pe Aarẹ Buhari yoo buwọlu ẹkunwo owo oṣu tuntun