O tó ìdá méjì àwọn ènìyàn àgbáyé to wà nínú ewu àìsàn ibà

O tó ìdá méjì àwọn ènìyàn àgbáyé to wà nínú ewu àìsàn ibà

Iṣẹ iwadii yii yoo wulo ni papakọ ofurufu àti awọn ibudokọ lati fi gbogun ti itankalẹ aisan ibà lagbaye.

Ojọgbọn Steve Lindsay ti fasiti Durham ni ilẹ̀ United Kingdom, lo ṣe agabtẹru iwadii naa nibi ti wọn ti lo ìbọ̀sẹ̀ àwọn ọmọde mẹta lati orilẹ-ede Gambia.

O fidi ẹ mulẹ pe bi ẹfọn to n fa àìsaǹ ibà ṣe maa n gboorun naa ni o ti hande pe àwọn ajá naa n gboorun.

Ọjọgbọn Steve fidi ẹ mulẹ pe kẹmikaa kan maa n jade lára ẹni to ba ni aisan ibà ni eyi ti awọn ajá naa le gbọ oorun rẹ lara eniyan.

Ìbọ̀sẹ̀ àwọn ọdọmọde naa ni wọn lò fun iwadii yii ni eyi ti àwọn aja naa gba meje ninu mẹwaa dàadáa.