DJ Cuppy: Kíni àwọn èèyàn ń sọ nípa orin rẹ̀ tuntun 'Charge Up'?

cuppy ati baba ẹ Image copyright @Cuppymusic
Àkọlé àwòrán Pẹlu ayọ ni DJ Cuppy fi n sọrọ orin rẹ tuntun lai naani èrò awọn eniyan

Gbajugbaja olorin ni DJ Cuppy, ẹni ti ọpọlọpọ n royin owó baba rẹ pe o to ọmọ naa dárà to ba wùú.

Yatọ si pe o jẹ ọmọ baba olowo, Fẹmi Ọtẹdọla, Florence Ifẹoluwa Ọtẹdọla, ti ọpọ mọ si DJ Cuppy ti lami-laaka lagbo ariya lorilẹ-ede Naijiria, ilẹ Afirika ati kaakiri agbaye.

Ni kete to gbe awo orin 'Charge Up' yii sita ti àwọn eniyan sì bẹrẹ si ni sọrọ nipa rẹ kaakiri ẹrọ ayelujara ni o ti fun orukọ ara rẹ lorukọ tuntun lataari pe awọn eniyan n ṣi orukọ rẹ pe.

Iṣẹ aforindanilaraya nibi ariya ti oyinbo n pe ni Disc Jockey (DJ) ni DJ cuppy yan laayo lẹyin to kẹkọ gboye imọ ijinlẹ Akọkọ ni ọdun 2014.

Image copyright DJCUPPY
Àkọlé àwòrán Orin naa ti pin awọn olufẹ DJ Cuppy si oniruuru ero ati esi lori boya orin naa dun tabi ko dun

Amọṣa kii ṣe tori eyi ni ẹnu ṣe n kun DJ Cuppy bayii, bikoṣe nitori awo orin tuntun to gbe jade ni ọjọ ẹti, eyi to pe akọle rẹ ni, Charged UP.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTony Elemelu Foundation: Gbogbo okòwò ló ní ìdojúkọ

Ọrọ ti awọn eeyan n sọ nipa rẹ kọja ohun ti gbajugbaju aforindanilaraya nibi ariya naa n reti nitori pupọ awọn eeyan ni wọn ti tabuku orin naa.

Image copyright @cuppymusic
Àkọlé àwòrán Ohun ti o ba wù ni lo lè gbiyanju ẹ nigba to ba wu eeyan

Amọṣa, awọn kan pẹlu luu l'ọgọ ẹnu fun iṣẹ ọpọlọ naa.

Image copyright DJ Cuppy
Àkọlé àwòrán Ọmọ baba olowo, Fẹmi Ọtẹdọla ni DJ Cuppy
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption#Oshimole: Àwọn aṣáájú APC kò mọ ohun ti wọ́n n ṣe lásìkò yí

Related Topics