Ayàwòrán Obama: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi àti ìyá mi pa èbi mọ́nú kí n tó jẹ́ èèyàn

Ayàwòrán Obama: Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi àti ìyá mi pa èbi mọ́nú kí n tó jẹ́ èèyàn

Ilumọọka ayaworan agbaye to ba BBC sọrọ ni aworan ti oun maa n ya dabi ijiroro laarin isẹ ọna, iha ti oun kọ si ati oju ti ọkọọkan awọn eeyan fi woo.

Bakan naa lo ni aworan oun maa n se ajọyọ iru eeyan ti alawọ dudu jẹ́, ilakaka wa nigboro ati ohun ti a lee se.

O fikun pe isẹ ọna oun da bi idahun si ero gbogbo eniyan ati aṣa iwọsọ awa alawọ dudu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gbaju-gbaja ayaworan naa tun sọ pe ọpọ igba ni iya oun ti fi ara jin fun oun ni kekere lati ri pe oun ya aworan oun, tawọn si la ọpọ isoro kọja.

O ni o gba oun ni ọdun mẹta toun fi fi aworan aarẹ Barrack Obama ti oun ya, se oku oru, amọ ọpẹ lo ja si lẹyin o rẹyin.