Nigeria Elections 2019: Bàbá rẹ̀ àgbà ni Adegoke Adelabu Pẹnkẹlẹmẹ́sì

Image copyright Adebayo_adelabu

Agbo ile Oke Oluokun ni adugbo Kudẹti nilu Ibadan ni wọn ti bi Adebayọ Adelabu lọjọ kejidinlọgbọn osu Kẹsan ọdun 1970.

Aderibigbe Adelabu ni orukọ baba rẹ, ti baba rẹ agba, Adegoke Adelabu, ti gbogbo eeyan mọ si ‘Pẹnkẹlẹmẹsi’ nigba aye rẹ, si jẹ gbaju-gbaja agba oselu nilẹ Ibadan.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIgba ọtun de fawọn afọju ninu eto idibo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionGrandma Maruwa: Ó yẹ kí obìnrin sisẹ́ láì wojú ọkọ kó tó jẹun

Awọn ile-ẹkọ ti Adebayọ Adelabu lọ

Adebayọ lọ si ileẹkọ alakọbẹrẹ Ibadan Municipal Government (IMG), to wa ni adugbo Agodi nilu Ibadan, laarin ọdun 1976 si 1982, ko to morile ile ẹkọ girama Lagelu Grammar School lọdun 1982 nibi to ti jade iwe mẹwa lọdun 1987.

Adebayọ gba oye imọ ijinlẹ akọkọ, Isọri kinni (First Class) ninu imọ nipa isiro owo (Accountancy), nile ẹkọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ nilu Ile Ifẹ, to si jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn akọsẹmọsẹ oluṣiro owo lorilẹede Naijiria, ICAN.

Adebayọ Adelabu Image copyright Adebayo_Adelabu

Awọn ileeẹ ti Adebayọ Adelabu ti isẹ bii oluiro owo

Ileeṣẹ oluṣiro owo kan to jẹ tilẹ okeere amọ ti ẹka rẹ fidi kalẹ si orilẹede Naijiria, ti wọn pe ni PriceWaterhouseCoopers ni Adebayọ ti kọkọ ṣisẹ ni kete to jade nile ẹkọ fasiti.

Ọdun meje gbako lo lo nile isẹ naa, to si dari oniruuru ẹka lab ileesẹ ọhun nilẹ yii ati loke okun.

Lọdun 1999 lo gba aye lati lọ ṣare sisẹ pẹlu banki apapọ ilẹ wa (CBN), fun ọdun kan pere, nibẹ lo si ti ko ikọ kan sodi eyi to ṣe atunto banki agba naa, eyi ti wọn pe akori rẹ ni akanse isẹ ‘Project Eagles’.

Adebayọ Adelabu Image copyright @BayoAdelabu

Ọdun 2009 lo fi ileesẹ PriceWater silẹ gẹgẹ bii Alakoso eto ayẹwo iwe owo, to si lọ dara pọ mọ banki olokoowo First Atlantic.

Lẹyin eyi lo tun lọ ṣiṣẹ ni Standard Chartered Bank, to si di ipo Oludari fun ẹka isuna ati aato banki naa fun ẹkun iwọ oorun Afrika mu, ti ọọfisi rẹ si wa nilu Eko ati Abuja.

Banki yii lo wa titi to fi di Oludari agba fun First Bank of Nigeria lọdun 2009, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn si ni nigba to de ipo giga ọhun.

Adebayọ Adelabu Image copyright @Adebayo_Adelabu

Aarẹ ana, Goodluck Jonathan lo yan Adebayọ bii igbakeji Gomina fun banki agba ilẹ wa loṣu keji ọdun 2014, ipo yii si lo wa to fi fẹyin ti.

Irinajo oelu Adebayọ Adelabu

Yatọ si pe gbaju-gbaja olokoowo ni Adebayọ, to si ni ileesẹ aje kaakiri ilu Ibadan, o tun jẹ eekan ti ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyin lagbo oṣelu nipinlẹ Ọyọ.

Ogunjọ oṣu Kẹfa ọdun 2018 lo si yọju sita bii oloselu lasiko to fi erongba rẹ han nileesẹ gbe oṣelu APC lati dije ninu ibo abẹle ẹgbẹ naa fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ.

Adebayọ Adelabu Image copyright @BayoAdelabu

Adebayọ lo jawe olubori ninu ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ ninu ibo abẹnu to waye lọgbọjọ oṣu Kẹsan-an ọdun 2018 gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu naa.