Ìfipábánilòpọ̀: Abiamọ bú sẹ́kún nígbà tí ọkùnrin kan fi kẹ̀kẹ́ tan ọmọ rẹ̀ wọ yàrá

Ìfipábánilòpọ̀: Abiamọ bú sẹ́kún nígbà tí ọkùnrin kan fi kẹ̀kẹ́ tan ọmọ rẹ̀ wọ yàrá

Awọn abiyamọ meji, lasiko ti wọn n ba BBC Yoruba sọrọ, ni ibanujẹ, ẹdun ọkan ati omije gba oju wọn.

Wọn ni ọkunrin to fi tipa ba awọn ọmọ awọn lo pọ, tun si oju wọn si ibalopọ akọ si akọ taa mọ si ‘Homosexuality’ tabi ‘Gay’, eyi to se ajoji si awọn gan-gan.

Wọn salaye pe kẹkẹ ti Abdullahi naa, tii se ẹni ọdun marundinlọgọta ni, lo n mu kawọn ọmọde nifẹ lati maa rọgba yii ka, to si maa n lo eyi lati bawọn se asepọ akọ si akọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A gbọ pe lẹyin ti Abdullahi tan awọn ọmọ yii wọle tan, ti ọjọ ori wọn jẹ ọdun mọkanla, lo fi tipa ti wọn lu ibusun, to si fi tipa jẹ dodo ifẹ lara wọn.

Wọn ni o tun dunkoko mọ awọn ọmọde naa pe wọn ko gbọdọ sọ fun awọn obi wọn, tori ọjọ ti wọn ba sọ, ni wọn yoo ku.

Awọn obi mejeeji ni Abdullahi ti wa ni ahamọ awọn ẹsọ aabo ara ẹni ni aabo ilu, taa mọ si ‘Civil Defence’.