Tani Kingsley Moghalu, ọ̀dọ́ tó fẹ́ jẹ ààrẹ?

àwòran Kingsley Moghalu Image copyright Facebook/KingsleyMoghalu
Àkọlé àwòrán ọpọ ọdọ Naijiria lo jade lati dupo arẹ lasiko yii

Kingsley Moghalu ni olùdíje fún ipò ààrẹ Nàìjíríà lábẹ́ àsìà ẹgbẹ oṣelu Young Progressives Party (YPP) ní ìbò ọdún 2019.

Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdíje fún ipò ààrẹ Nàìjíríà tó ṣe ìlérí pé òun yóò ṣe àtúntò (restructuring) orilẹ̀-èdè tó ní ènìyàn pò ní ilẹ̀ adúláwọ̀ tó bá di ààrẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Obìnrin ló ni ilé àti àdúgbò fún ìdí èyí wọ́n lè ṣe ìlú dáadáa'

Ìtàn ìgbésíayé Kingsley:

Wọ́n bí Kingsley Moghalu ní ọdún 1963.

Moghalu àti àwọn òbi rẹ̀ gbé ìgboro Geneva ní orílẹ̀-èdè Switzerland àti ìgboro Washington ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà fun igba pipẹ.

Láàrín ọdún 1970 sí 1980 Moghalu kàwé ní ilé ìwé girama ìjọba àpapọ̀ tó wà ní Umuahia, ìyen Federal Government College Umuahia.

Image copyright Facebook/KingsleyMoghalu
Àkọlé àwòrán Kingsley Moghalu ń ti ń káakiri gbogbo orílẹ̀-èdè Nàìjíríà fún ìpòlongo
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsinbajo: Ikẹnnẹ yẹ kó jẹ́ Mẹ́kà òṣèlú ni

Ní ọdún 1986 ni Moghalu gba oyè ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àkọ́kọ́ LLB lóríi òfin ní fásitì Nììjíríà, (UNN), tó sì lọ́ sí ilé ẹ̀kọ́ agbẹjọ́rò tó wà l'Ékó, Nigerian Law School.

Moghalu gba oyè ìjìnlẹ̀ ẹlẹ́ẹ̀kẹjì ní ilé ìwé ìmọ̀ òfin Fletcher ní Fáṣitì Tufts l'Ámẹ́ríkà níbi tó ti jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ lá bẹ́ ètò ẹ̀kọ́ Gillespie àti olùrànlọ́wọ́ lórí ìwádìí nípa ètò ìṣúná àti ìṣèlú orilẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ní ọdún 1992.

Lẹ́yìn ìgbà náà ni Moghalu gbà oyè ìjìnlẹ̀ elẹ́ẹ̀kẹẹ̀ta (Ph.D) lórí ìṣèlú orílẹ̀-èdè sí orílẹ̀-èdè ní London School of Economics tó wà ní fásitì London.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionìpàdé ìtagbangba ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò pẹ̀lú àwọn olùdíje sípò gomina ní ìpínlẹ̀ Eko.

Bákan náà ó gbà oyè olọ́kanòjọ̀kan ní fásitì Havard àti ti Pennsylvania.

Moghalu ṣe igbákejì gómìnà bánkì àpapọ̀ Nàìjíríà (CBN) láti ọdún 2009 sí 2014.

Láti ìgbà náà a kò gbọ́ nǹkan púpọ̀ nípa Moghalu mọ́ títí tó fi gbé àpótí ìbò.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption2019 Elections: Èrò àwọn ọmọ Nàíjíríà se ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lóri ètó àlùfáà tàbí ìmámù lásìkò ìbò
Image copyright Facebook/KingsleyMoghalu
Àkọlé àwòrán Awọn mẹkunnu naijria ṣetan lati dibo lọdun 2019

Ó ní ìgbàgbó pé ètò ẹ̀kọ́ tó pé ye àti ètò ìsúná fún àwọn onísòwò ló lè tán ìṣẹ́.

Kingsley fẹ́ kí àwọn dókítà Naìjíríà má lọ ṣiṣẹ́ lókè òkun mọ́n.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionMurphy Elégungun Rọba: Mo fẹ́ di ẹnití egungun rẹ rọ jùlọ ní àgbáyé

Ẹ̀tò àtúntò (restructuring) tí Kingsley gbà lérò

Ó ń fẹ́ kí wọ́n pín Nàìjíríà sí ọ̀nà mẹ́fà gẹ́gẹ́ lábẹ́ ìsàkóso ìjọba àpapọ̀.

Ó fẹ́ kí wọ́n pa gbogbo ìpínlẹ̀ mẹ́rìndínlógójì tó wà ní Nàìjíríà rẹ́.

Ó fẹ́ kí gbogbo ìpínlẹ̀ kọ̀ọ̀kan nínú mẹ́fà máa bọ́ 'rarà.

Image copyright Facebook/KingsleyMoghalu
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀tọ̀ ni nkan tí wọ́n sọ fún ẹbí rẹ̀, iṣẹ́ aṣẹ́wó ni wọ́n fi n ṣe

Moghalu Kingsley fẹ́ kí gbogbo ìpínlẹ̀ l'ágbára lórí nǹkan àlùmọ́nì tó wà lábẹ́ wọn.

Ó fẹ́ fi òpin sí títa nǹkan àlùmọ́ọnì láì yí wọ́n padà sí nǹkan tó lówó lórí.

Ó fẹ́ kí wọ́n ya ẹ̀sìn kúrò lára ìṣẹ̀lú

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionObasanjo: Atiku kìí se Áńgẹ́lì, àmọ́ yóò se dáadáa ní ìlọ́po méjì ju Buhari lọ