World Toilet Day: Onímọ̀ kan ní ìpèsè ilé ìgbọ̀nsẹ̀ nìkan kò lè tàn ipenija yí

Aworan ọmọde to n ya igbe ni ita gbangba Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orisisrisi aisan lawọn eeyan ma n ko latara yiyagbe sita

Ati oṣisẹ ilera ati ara ilu, ko si ẹni to ko fẹ ẹ mọ ipalara ti ṣiṣe igbọnse si ita gbangba n ṣe lawujọ.

Yala ni awọn ilu kekeeke tabi lawọn ilu nla bi Abuja, Eko tabi Port-Harcourt, ipenija yii jẹ ohun to n kọ awọn eeyan lominu.

Ninu iwadi kan ti Ajọ to n risi idagbasoke ọmọ wẹwẹ lagbaye, UNICEF gbe jade lọdun 2017, Naijiria wa ni ipo kẹji ninu awọn orileede ti ṣisẹ igbọnsẹ ni ita gbangba ti peleke.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Orileede India naa n ba ipenija igbẹ yiya ni ita gbangba finra

Pẹlu bi iṣesi yii ti ṣe gbale, ki ni awọn aburu to wa ninu ki eeyan ma yagbẹ si ita gbangba lalai bikita.

Ewu to wa ninu igbẹ yiya nita gbangba

A na ọwọ ibeere yi si onimo isegun ilera ayika ẹni, Dokita Olajire Olanrewaju, to si salaye fun ileese BBC Yoruba wi pe, ewu nla lo wa ninu ki awọn ara ilu ma yagbẹ sita gbangba.

'Yato si wi pe o fun Naijiria lorukọ buruku laarin awọn orileede to ku,iwa yi a ma ṣe ipalara fun ilera ati alafia ara ilu.'

Èwo ló pàtàkì jùlọ nínú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ àti ilé ìgbọ̀nsẹ̀?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iwa ṣiṣe gaa yi ko yọ agba naa silẹ

O salaye pe, pupo ninu awọn aisan ti o ma n ba ẹdọ inu ara jẹ, bii Hepatitis A ati Typhoid, maa n wọwa latara bi igbọnse ṣe ma n dapọ mọ omi mumu.

Dokita Olanrewaju ni, lawọn ipinlẹ bii Kebbi, Sokoto ati Zamfara nibi ti awọn ijọba wọn ko ti kọ ibi ara si kikọ ile igbọnse, orisirisi aisan a ma ba awọn ara ilu finra.

Ki lawọn wole wole n ṣe?

Dokita Olanrewaju ni, pelu bi nnkan ti ṣe ri lawujọ loni, o di dandan ki ijọba ṣe agbedide awọn oṣiṣe ilera ti yoo maa tọpinpin ibi ti awọn eeyan n ṣe ibẹrẹ si.

'Bi eeyan ba tapa si ofin, ọlọpa yoo mu iru ẹni bẹẹ, bi ara ilu ba wuwa aitọ nipa ayika, nibo lawọn wolewole wa ti yoo mu iru ẹni bẹẹ?'

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn wole wole kii mojuto ibi ti awọn eeyan ti n se ounjẹ lopọ awọn agegbe ni Naijiria

Dokita Olanrewaju ni, o di dandan ki ijọba pese ohun eelo to yẹ fun awọn oṣise ilera yii lati ṣe iṣẹ wọn.

"Ẹyin e woo nnkan ti ijọba Eko ṣe pẹlu ile ise to n ṣe ọṣẹ kan nipa bi wọn ti ṣe kọ ile iyagbe si awọn arin ọja kaakiri.

Iru igbese yi daa pupọ ti a ba fẹ dẹkun iwa ibaje ka ma yagbẹ sita gbangba."

O rọ awọn ara ilu naa ki wọn ri wi pe wọn mu imọtoto wọn lokunkundun.