Ọsun Robbery: Ọwọ́ pálábá àwọn adigunjalè ṣégi ní Ilé -Ifẹ̀

Ọwọ́ pálábá àwọn adígunjalè ṣégì ní Ilé -Ifẹ̀ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Adígunjalè kùnà láti fọ́ báǹkì l'Ọsun

Ọwọ́ pálábá àwọn afurasi adigunjale ti ṣegi lọ́jọ́ Ajé nígbà tí wọn gbìyànjú lati kọlu ilé ìfòwópamọ kan ní agbègbè Lagere ílùú Ilé-Ifẹ ní ìpínlẹ̀ Ọsun, nígbà táwọn ará adúgbo to ri wọn dìde láti jà.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌfipábánilòpọ̀: Abiamọ bú sẹ́kún nígbà tí ọkùnrin kan fi tipá bá ọmọ méjì lòpọ̀

Ilé ìfowópamọ méje ló ni ẹ̀ka ní àdúgbò Lagere yii tàwọn adìgunjalè gúnlẹ̀ sí ní dédé aago mẹ́wàá òwúrọ.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣe ojú ẹ ṣe sọ, pé àwọn adigunjalè náà wọ àdúgbò nínú ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ Toyota Camry àti bọọsi kan ti wọn gbé sí ẹgbẹ́ báǹkì náà, tí wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí ní yìbọn sí inú afẹ́fẹ́ láti dẹ́rù ba àwọn ènìyàn.

Ẹ̀wẹ̀, àwọn agbófinró tí wọn fi sí ilé ìfowópaamọ àti àwọn ọlọ́dẹ àdúgbò ni wọn fìjà pẹ́ẹ́ta pẹ́lú wọn, èyí sì ló mú kí àwọn olè náà pẹ̀yìnda.

Agbẹ̀nusọ fún Ajọ ọlọpàá ní ìpínlẹ̀ Osun (SP) Folashade Odoro, náà fìdí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ àtí pé iṣẹ́ sì ń lọ lọ́wọ́ láti mú àwọn afunrasí adigùnjalè náà.