Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ lórí iná tó sọ nileeṣẹ EFCC

Olú iléeṣẹ́ EFCC Image copyright @officialEFCC
Àkọlé àwòrán Lai pẹ yi ni wọn kọ olú iléeṣẹ́ tuntun fun EFCC kò le gba gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ àjọ nàá tó wà ní ìlú Abuja.

Ajọ to n gbogun ti iwa jẹgudujẹra lorilẹ-ede Naijiria, EFCC, ni awọn yoo bẹrẹ iwadii ohun to fa ina to sọ ni ọọfisi wọn kan lAbuja.

Ina naa to sọ lẹka ajọ naa to wa ladugbo Wuse 2, lAbuja la gbọ pe o bẹrẹ lalẹ ọjọ Aje.

Atejade kan ti ajọ naa fi sita lati ẹka to n ri si ọrọ iroyin sọ pe ọpẹlọpẹ awọn panapana to yara pa ina naa, ọtọ ni nnkan ti a ko ba máa sọ.

Bakan naa ni wọn ni ori ko awọn oṣiṣẹ meji kan yọ lọwọ ijamba ina ọhun

Ajẹ ké lana ọmọ ku loni

O jọ gáté kò jọ gàté lọrọ to wa nilẹ yi pẹlu pe ko tii ju ọjọ mẹrin lọ ti Aarẹ Buhari paṣẹ pé kajọ EFCC ṣe iṣiro gbogbo owo ti o ti ri gba ti ina fi sọ ni ile ti wọn n ko ifitonileti si.

Irufẹ iṣẹlẹ ina bayi ko jẹ tuntun ni Naijiria paapa julọ ti ọrọ ba ti niiṣe pẹlu ki awọn eeyan wa ṣe iṣiro owo tabi ti iwadii kan ba n lọ lọwọ.

Bi a ko ba gbagbe iru ina bayi sọ ni ọọfisi ajọ to n mojuto ere bọọlu lorile-ede Naijiria, NFF lọdun 2014.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIna jo ọja binukonu lọjọta

Iwadii kan n lọ lọwọ nigbana naa lori ẹsun jẹgudujẹrati wọn fi kan awọn alaṣẹ ajọ naa.

Ko tii daju boya ejo lọwọ ninu pẹlu iṣẹlẹ ti EFCC yi ṣugbọn ireti wa wi pe ti iwadii ẹkunrẹrẹ ba waye, ohun to sokunkun nipa ijamba ina yi yoo di mimọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionCar Race: Elizade àti Akeredolu kópa nínú ìdíje eré sísá ni Ondo