Ọlọpaa ni Abdullahi tó fipá bá ọmọdékùnrin méjì lò yoo foju ba ilẹ ẹjọ́

Àkọlé fídíò,

Ìfipábánilòpọ̀: Abiamọ bú sẹ́kún nígbà tí ọkùnrin kan fi tipá bá ọmọ méjì lòpọ̀

Arakunrin kan Abdullahi Garuba ti wọn fẹsun kan pe o fipa ba awọn ọmọdekunrin meji lopọ ni Ipinlẹ Eko ni awọn ọlọpaa ti foju rẹ han fun awọn oniroyin bayii.

Abdullahi to jẹ ni ọdun mejidinlọgọta ni awọn ọlọpàá ni o tan awọn ọmọdekunrin naa wọ inu ile rẹ ni ọjọ kẹwaa, osu kọkanla, ọdun yii.

Atẹjade kan lati ọwọ agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko, Chike Oti ni ọga ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko Edgal Imohimi ti gba awọn ọbi ni imọran wipe ki wọn ma ṣọ awọn ọmọ wọn.

Ọlọpaa ni Abdullahi yoo foju ba ilẹ ẹjọ́ laipẹ.

Awọn iya awọn ọmọ mejeeji ba BBC Yoruba sọrọ ni ibanujẹ, ti wọn si sọ ẹdun ọkan wọn pelu omije l'oju.

Wọn ni ọkunrin to fi tipa ba awọn ọmọ awọn lo pọ, tun si oju wọn si ibalopọ akọ si akọ taa mọ si ‘Homosexuality’ tabi ‘Gay’, eyi to se ajoji si awọn gan-gan.

Wọn salaye pe kẹkẹ ti Abdullahi naa, tii se ẹni ọdun marundinlọgọta ni, lo n mu kawọn ọmọde nifẹ lati maa rọgba yii ka, to si maa n lo eyi lati bawọn se asepọ akọ si akọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

A gbọ pe lẹyin ti Abdullahi tan awọn ọmọ yii wọle tan, ti ọjọ ori wọn jẹ ọdun mọkanla, lo fi tipa ti wọn lu ibusun, to si fi tipa jẹ dodo ifẹ lara wọn.

Wọn ni o tun dunkoko mọ awọn ọmọde naa pe wọn ko gbọdọ sọ fun awọn obi wọn, tori ọjọ ti wọn ba sọ, ni wọn yoo ku.

Àkọlé fídíò,

Iwode fun Ochanya ti won ba lopo waye nilu Eko

Awọn obi mejeeji ni Abdullahi ti wa ni ahamọ awọn ẹsọ aabo ara ẹni ni aabo ilu, taa mọ si ‘Civil Defence’. Ajọ alaabo naa ti fi Abdullahi ṣọwọ si awọn ọlọpaa.

Àkọlé fídíò,

Parental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀