Ọọnìrìsà ṣe ìfilọ́lè àpérò ọlọdọodun àwọn lóbalọba láti pẹ̀tù sááwọ̀ wọn

Àkọlé àwòrán Ọọni ti Ifẹ pe apero awọn lọbalọba

Awọn ladelade-loyeloye to le ni ọgọrun un lo kora jọ pọ silu Ile-Ifẹ fun akanṣẹ eto apero to da lorii imubọsipo ogo awọn lọbalọba ilẹ Yoruba. Lọjọ Iṣẹgun ni Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja Keji gbalejo awọn Ọba alade naa ni gbagede igbalejo Ife Grand Resort to wà nilu Ile-Ifẹ.

Àkọlé àwòrán Ọrọ àwọn lọbalọba ilẹ Yoruba gba apero

Ipade naa lo da lorii fifi opin si aawọ laarin awọn Ọba ilẹ Yoruba pẹlu ifojusun lati bomirin iṣọkan laarin wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌọni Ogunwusi Adeyẹye pe fun itọju awọn ọdọ

Ninu ọrọ rẹ, alaga igbimọ to ṣeto ipejọpọ naa, Ẹlẹ́rìnmọ̀ ti Ẹ̀rìnmọ̀, Oba Michael Odunayo Ajayi ṣe alaye fún BBC Yoruba pe lati aye atijọ ni awọn lọbalọba ti n kora jọpọ fun ipade, sugbọn ko ri bẹẹ mọ laye ode oni nitori ija "emi ju , iwọ ko ju mi" to n waye laarin awọn ọba alade.

Àkọlé àwòrán ọọni Ifẹ pe apero idagbasoke asa Yoruba

O fi kun ọrọ rẹ pe eyi lo mu ki Ọba Ẹnitan Ogunwusi ṣe agbekale apero naa fun itẹsiwaju gbogbo ilẹ Yoruba. Lara Ọba alade to kora jọpọ sibi apero naa ni, Ọọni Ile Ifẹ, Ọba Ẹnitan Ogunwusi, Ọjaja keji, Elerinmo of Erinmo, Oba Michael Odunayo Ajayi, Olupe ti Ipe Akoko, Oba Oludo Ido Ijesha, Oba Jegun Okitipupa ati bẹẹbẹẹ lọ.

Àkọlé àwòrán Aṣa ati iṣe Yoruba kuro ni keremi

Awọn lọbalọba yii gbagbọ pe lẹyin apero yii, orí adé kọọkan a tun mọ iwa to yẹ ni hihu lawujọ ti ko ni maa tabuku ba ipo ọba ilẹ̀ Yoruba.

Wọn tun gbagbọ pe, gbogbo ija to n ṣẹlẹ laarin awọn lọbalọba yoo dinku lẹyin ti gbogbo wọn ba ti fọrọ jomitooro ọrọ tan.

Opolopo awọn ogidi ọmọ Yoruba lo ti n gabgbe ipo pataki to yẹ ki ori ade wà lawujọ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionParental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÌran kan si ìkejì ló n gbèrò láti ṣe ìrú ìgbéyàwo àjùmọ̀ṣe 'Shao' fọ́mọ wọn

Related Topics