Ilé isẹ́ ológun nílò onímọ nípa kíkọjú Boko Haram -Temitope Olodo

'Ọmọogun Nàìjírí Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán 'Ọmọogun Nàìjíríà

Orilẹede Naijiria nilo ile isẹ ologun to gbamuse fun idibo ọdun 2019 ki awọn agbeegbe ti Boko Haram ti sọsẹ le dibo ni irọwọrọsẹ.

Onimọ nipa eto abo lagbaye, Temitope Olodo lo salaye pe ile isẹ ologun nilo lati gba awọn onimọ nipa kikoju ikọ adunkokomọni lọna igbalode.

Temitọpe ninu ọrọ rẹ sọ wi pe Naijiria ko ni awọn onimọ to le sọ gbogbo bi awọn Boko Haram se n rin, ati ibi ti wọn ba n rin si, ki wọn ba le maa fi iroyin to yẹ lede fun awọn ọmogun to n koju Boko Haram.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBeautiful Nubia: Kò sí wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ láàgbáyé tí kò ní ọwọ́ ẹ̀sìn lábẹ́nú

Lori ọrọ ti adari awọn osisẹ ologun Naijiria sọ pe Boko Haram ti n lo ohun ija drone, onimọ nipa eto abo naa fi kun un wi pe ile isẹ ologun ofurufu Naijria nilo lati gba awọn eniyan si isẹ ti yoo ran wọn lọwọ lati lo awọn ohun ija igbalode ati imọ ẹrọ fun ibanisọrọ.

Tẹmitọpe Olodo ni "awọn ọmọ ikọ Boko Haram ko koju awọn ọmọogun Naijiria pẹlu ohun ija igbalode, sugbọn wọn lo "armour tank" pẹlu ibọn lati wọ inu baraaki wọn lati koju ija si wọn".

"Wọn nilo agbada satalite ti yoo ma sọ igba ati akoko bi awọn Boko Haram se n gbero lati koju wọn".

"Ati wi pe wọn nilo ‘anti-drone’ lati jagun naa lai si iru isẹlẹ to pa ọgọọrọ awọn ologun Naijiria mọ".

Ti a ko ba gbagbe, ọdun to koja ni ijọba apapọ lorilẹede Naijiria, sọ wi pe awọn yọ biliọnu Dọla kan kuro ninu apo ijọba apapọ lati lẹ ra ohun ija igbalode fun awọn ọmọogun.

'Ọmọọgun 23 ló kú ní Metele, 31 farapa ní ìkọ̀lù Borno'

Ile isẹ ologun lorilẹede Naijria ti sọ wi pe eniyan mẹtalelogun lo ku ninu ikọlu ti awọn ikọ Boko Haram ṣe si ibudo ọmọ ogun kan lagbeegbe Metele ni ipinlẹ Borno, ti mọkanlelọgbọn si farapa.

Ikọlu to waye ni Ọjọ Kejidinlogun, Osu Kọkanla, ọdun 2018 ni ọpọlọpọ iroyin sọ wi pe o mu ẹmi ọmọọgun to to ọgọrun lọ, ti ọpọlọpọ si di awati, ṣugbọn ile iṣẹ ologun sọ wi pe ko si otitọ ninu iroyin naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAbdulfatah Ahmed: PDP kò fi tíkẹ́ẹ̀tì mi fa ojú ẹnìkejì mọ́ra

Ninu atẹjade ti ọga awọn ọmọọgun ilẹ Naijiria, Ọgagun Tukur Buratai fi lede gba ọwọ Ọgagun Sani Usman ni lootọ ni ikọ Boko Haram se ikọlu si awọn ọmoọgun ni Ọjọ Keji ati Ọjọ Kẹtadinlogun, Osu Kọkanla, ọdun 2018 ni agbeegbe Kukawa, Ngoshe, Kareto ati Gajiram.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBeautiful Nubia: Kò sí wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ láàgbáyé tí kò ní ọwọ́ ẹ̀sìn lábẹ́nú

Usman ni awọn ọmọogun Naijiria bori ikọ Boko Haram,sugbọn ọmọogun mẹrinlelogun ni ẹmi wọn lọ si ikọlu naa, ti mejila si farapa ninu ikọlu naa.

Wo ìdí tí Boko Haram fi ń pa ọmọogun Nàìjíríà

Iku ọwọọwọ awọn ologun Naijiria ti o n koju ikọ agbebọn Boko Haram ti n kọ ọpọ lominu.

Oniruuru ikọlu ti Boko Haram ti gbe kọlu awọn ọmọogun Naijiria ni o jasi iku ọpọ ọmọogun lọpọ igba.

Iroyin awọn ọmọogun ti wọn ku laipẹ yii lẹyin ti awọn agbebọn Boko Haram ya bo ibudo wọn ni ilu Metele ni ipinlẹ Borno, ti fa ọpọ ẹhonu lorilẹede Naijiria ati agbaye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdedoyin: Tí mo bá rí Buhari, màá sọ fun kó rántí pé Ọlọ́run wà

Amọṣa, ẹni to ti fi igba kan ri jẹ ọgagun agba ileeṣẹ ologun lorilẹede Naijiria, Ajagunfẹyinti Marthin Luther Agwai ni, bi awọn ologun ṣe n ku iku ọwọọwọ naa ko le ṣai ri bẹẹ nitori irufẹ ogun ti wọn gba ikọni fun yatọ si eyi ti wọn n koju lọwọ.

Ajagunfẹyinti Marthin Luther Agwai ṣalaye pe, ogun kọju simi ki n kọju si ọ ni awọn ọmọogun Naijiria kọ nipa rẹ, kii ṣe eyi ti wọn n ba awọn Boko Haram ja lọwọ.

Image copyright Nigeria army
Àkọlé àwòrán Iku ọwọọwọ awọn ologun Naijiria ti o n koju ikọ agbebọn Boko Haram ti n kọ ọpọ lominu

"Ṣe ki n maa parọ fun yin, ọfọ nla ni pe a padanu iye awọn ọmọogun to pọ to bayii"

Amọ o ni ko yẹ kawọn ọmọ orilẹede Naijiria sọ ireti nu ninu ijafafa awọn ologun orilẹede yii, pẹlu afikun pe bi yoo ṣe ri niyi nitori irufẹ ogun ti wọn n ja lọwọ.

"Bi aja ba bu eniyan jẹ, kii ṣe iroyin ṣugbọn ni ọjọ ti eniyan ba yi oju pada lati bu aja jẹ ni ariwo yoo ta. Iroyin kii pọ lori iye awọn agbebọn Boko Haram ti awọn ologun ti pa tabi mu si ahamọ?"

"Idi ni pe aja lo n bu eniyan jẹ nigba yẹn. Ojuṣe ti a n reti lọwọ awọn ologun niyi."

Image copyright Nigeria army
Àkọlé àwòrán Agwai ni ko si ologun ṣe lee ja iru ija yii ti wọn ko ni fara gba ọta.

O ni ko si bi awọn ọmọogun yoo ṣe maa ja ogun bayii lai ni fara kaaṣa ikọlu awọn agbebọn yii.

Ibeere lori biliọnu kan dọla owo ilẹ Amẹrika ti Buhari beere lati na lori ọmọogun

Ni ibẹẹrẹ ọdun 2018 ni aarẹ Buhari buwọlu biliọnu kan dọla owo ilẹ Amẹrika fun rira awọn nnkan ija ogun fun awọn ologun lati koju Boko Haram.

Ni gba naa, kii ṣe ede aiyede kekere lo waye laarin ẹka aṣofin, ẹka iṣakoso ati awọn alatako, paapaa julọ ẹgbẹ oṣelu PDP, to fi mọ igun kan laarin awọn ọmọ orilẹede yii.

Nibayii ti ọrọ ikọlu ati pipa awọn ọmọogun ti wa n di lemọlemọ bayii, ọpọ lo ti n ṣe ibeere pe nibo ni owo naa wọlẹ si ati pe kini wọn n fi awsn ohun ija ogun ti wọn ra ṣe ti o fi di pe awọn agbebọn yii n gbẹyẹ mọ awọn ọmọogun lọwọ lẹnu ọjọ mẹta yii.

Nibo lo kan?

Image copyright Nigeria army
Àkọlé àwòrán Oniruuru iroyin lo ti jade ni pa iye awọn ọmọogun ti wọn ku ni pato ninu ikọlu naa

Lẹnu oṣu diẹ bayii lemọlemọ ni ikọlu awọn ologun lorilẹede Naijiria lati ọdọ awọn agbebọn Boko Haram yii.

Awọn ibudo ologun lawọn ilu bii, Metele (November 18), Kekeno (September 23), Mainok, Gajiram, Gashigar (September 25), Damsak (September 12), Zari (August 30), Garunda (August 8) ni awọn agbebọn yii ti kọlu.

Bi awọn onwoye kan si ti n sọ, ikọlu wọnyii ni batani bi o ti n lọ eleyii ti o mu ki wọn maa beere pe nibo lo tun kan bayii?

Akọroyin kan, Ahmad Salkida ṣalaye lori ikanni twitter rẹ pe ọwọ ti awọn ikọ agbebọn yii fi n gba awọn eeyan tuntun si agbo wọn n fẹ amojuto.

O ni lọwọ yii ipo akọkọ ni ikọ agbebọn Boko Haram ti wọn n pe orukọ rẹ ni ISWAP laarin awọn ẹgbẹ agbesunmọmi ati agbebọn lagbaye.

SERAP ní kí Buhari gbé Dasuki, Jonathan lọ síwaju kóòtù àgbáyé

Image copyright Nigeria army
Àkọlé àwòrán Buhari ni ijọba yoo pese oun ija to peye fun awọn ọmọ ogun Naijiria

Iṣẹlẹ bi awọn Boko Haram ṣe kọlu ikọ ọmọogun Naijiria laipẹ yii ti wọn si pa pupọ ninu wọn ti di eyi ti eeyan lee sọ pe gbogbo agbaye ti gbọ.

Oniruuru gbọyisọyi lo si ti ti ara rẹ jade lagbo oṣelu, awujọ orilẹede agbaye ati laarin awọn sms orilẹede Naijiria funrawọn.

Ni ọjọ abamẹta ni aarẹ Buhari funrarẹ pẹlu bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa ti o si tẹnumọ ipinnu ijọba rẹ lati rii pe aabo wa fun tẹrutọmọ lorilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Èmi kì í ṣe olórí tí kò bìkítà nípa ọmọlẹ́yìn rè-Ààrẹ Buhari

Pín fídíò 'ayédèrú' kó o ríjà ológun Nàìjíríà

Amọṣa, ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan kan ti o fi orilẹede Naijiria ṣe ibugbe ti ke gbajare sita pe ko yẹ ki ọrọ naa ms bẹẹ, ayaafi ki aarẹ tete gbe iwadi kalẹ lati tan ina wadi bi wọn ṣe n na gbogbo owo ti wọn n ya sọtọ fun nina lẹka abo ati ileeṣẹ ologun ninu eto iṣuna orilẹede Naijiria bẹrẹ lati ọdun 1999 si 2018.

Image copyright Nigeria army
Àkọlé àwòrán Ikẹdun Ààrẹ Buhari yí n wáyé lẹyìn bí ọjọ máàrún tí ìròyìn ìṣẹlẹ ikọlù àwọn ọmọ ogún pẹlú ìkọ Boko Haram wà ye

SERAP ni ni ibi ti ọrs de duro bayii ti awọn ọmọ ogun orilẹede Naijiria wa n ku iku ọwọọwọ loju ija, o to ki aarẹ dari gbogbo ẹsun iwa ijẹkukjẹ to niiṣe pẹlu nina owo to yẹ fun rira nnkan ijagun fun awọn ologun lorilẹede Naijiria si iwaju kootu agbaye, ICC.

Ninu lẹta kan ti o kọ ṣọwọ si aarẹ Buhari, ajọ naa ni, "ẹgbẹlẹgbẹ biliọnu naira ni a ti ya sọtọ fun ileeṣẹ ologun lati daabo bo orilẹede yii ṣugbsn ko jọ bi ẹni pe eyi ti ni ipa kankan ninu ipa awọn ọmọogun Naijiria lati dojukọ awọn agbebọn BokoHaram atawọn iks agbebọn miran lorilẹede Naijiria."

Image copyright Nigeria Army
Àkọlé àwòrán SERAP ní kí Ààrẹ Buhari darí gbogbo àwọn ìwé ẹ̀sùn ìkówójẹ tí ó bá rọ̀ mọ̀ ríra ohun èlò ológun ránṣẹ́ sí kóòtù àgbáyé

Ajọ naa woye pe bi ọrs ṣe ri bayii, ti awọn ologun ko lee wawọ kilanko awọn agbebọn naa bọlẹ, o fihan pe ejo lọwọ ninu pẹlu bi wọn ṣe n ṣe awọn owo ti wọn ya sọtọ labẹ iṣuna orilẹede Naijiria fun ẹka aabo.

Ààrẹ Buhari kẹ́dùn lórí ikú àwọn ológun ní Metele

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Eyi kii ṣe igba akọkọ ti Buhari yoo ma kẹdun pẹlu awọn ọmọ Naijiria lori ipaniyan

Lẹyin nnkan bi ọjọ maarun ti iroyin pe ikọ Boko Haram ṣe iku pa awọn ọmọ ogun Naijiria,Aarẹ Muahmmadu Buihari ti ba awọn ọmọ Naijiria kẹdun lori iṣẹlẹ naa.

Ikẹdun rẹ ti o wa ninu atejade kan ti agbẹnusọ ileeṣẹ Aarẹ Garba Sheu fi sita lọjọ Aiku so pe ''inu Aarẹ Buhari bajẹ pupọ lori iṣẹlẹ iku awọn ọmọ ogun ni abule Metele lọwọ Boko Haram''

Aarẹ Buhari so ninu atejade naa pe ''ko si olori kankan ti yoo kawo pọnyin ti yoo si ma wo bi awọn agbesunmọmi yoo ṣe ma ṣeku pa awọn ọmọogun rẹ''

O ni ohun n ṣe ipade pẹlu awọn olori ọmọogun lati ri wi pe awọn koju Boko Haram.

Buhari ni ijọba yoo pese oun ija to peye fun awọn ọmọ ogun Naijiria.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ija laarin awọn ologun Naijiria ati ikọ Boko Haram ti n lọ ti pẹ

O tẹsiwaju wi pe oun 'ṣetan lati fun awọn ọmọ ogun wa ni gbogbo iranwọ ti yoo mu wọn ṣe iṣẹ wọn bo ti ṣe yẹ'

Lai pe yi ni iroyin gbode nipa iku awọn ọmọogun Naijiria lọwọ ikọ Boko Haram ni abule Metele ni ipinlẹ Borno.

Iṣẹlẹ naa mu ki ara ilu bẹnu atẹ lu ijọba Buhari ti o ni oun ti dẹkun agbara ikọ Boko Haram.

Ile ise ologun ko sọ pato iye ọmọogunto ku ninu ikọlu naa sugbọn awọn iroyin kan ni wọn le ni ọgọrun.

Fidio orisirisi ni o si ti gba ori ayelujara nibi ti awọn ọmọ ogun ti n ke gbajare si Aarẹ Buhari lati wa wọrọkọ fi sada lori bi awọn olori wn ko ti ṣe ra nnkan ija fun wọn lati koju Boko Haram.

Ilé iṣẹ́ ológun orílẹ̀èdè Nàìjíríà ti ní lóòtọ́ ni ikọ̀ Boko Haram kọ lu àwọn ológun tí wọ́n sì pa lára wọn ní Metele, ìjọba ìbílẹ̀ Abadam, ìpínlẹ̀ Borno.

Ọ̀rọ̀ tó jáde láti olú ilé iṣẹ́ ológun Nàìjíríà sọ pé ìkọlù tí àwọn ẹsin ò kọ'kú Boko Haram ṣe sí ọ̀wọ́ ogun 157 Task Force Battalion wáyé ní ọjọ́ kejìdínlogún oṣù kọ́kànlá ṣùgbọ́n kò sọ iyé ọmọ ogun tó kú.

Àwọn oníròyìn sì ti bábá gbé e síta wí péó lé ni ààdọ́rin ọmọ ogun tí wọ́n ti pa tó fi mọ́ olórí ọ̀wọ́ ogun náà, fídíò rẹ̀ sì ti gba gbogbo orí ẹ̀rọ ayélujára.

Ibi ìpamọ̀ ohun ìjagun púpọ̀, ta ìbọn àti ohun èlò àwọn ológun ni ikọ̀ Boko Haram kó lọ lákokò ìkọlù yìí tó wáyé ni Metele, ìjọba ìbílẹ̀ Abadam ní ìpínlẹ̀ Borno.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà kò tíi fo hùn lórí ìròyìn náà

Ìbò tó ń bọ̀ ló fa ìkọlù Boko Haram àti ọmọ ogun

Ọga ileeṣe ọtẹlẹmuyẹ DSS tẹlẹ lorilẹede Naijira Mike Ejiofor ti sọ pe ibo to n bọ lọna lo jẹ ki ikọlu Boko Haram pẹlu awọn ọmọ ogun Naijiria pọ si lẹnu lọọlọ yii.

Ejofor to ba BBC sọrọ yii lẹyin ti ara awọn ẹgbẹ agbesumọmi Boko Haram, Islamic State West Africa Province(ISWAP) pa ọpọ ọmọ ologun ti wọn si tun ko nnkan ija wọn lọ.

O fikun ọrọ rẹ pe Boko Haram ko ni gbagbọ ninu eto ijọba awa-ara-wa, eleyi lo jẹ ki wọn maa da rukerudo silẹ ki ẹru le maa ba awọn eeyan ṣaaju idibo ọdun 2019.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ejiofor tilẹ tun sọ pe o ṣeeṣe ki awọn ọmọ ologun ti Boko Haram pa ju iye ti ile iṣẹ ọmọ ogun Naijiria fi lede lọ, nitori wọn o ni fẹ ki awọn ọmọ ologun ti wọn si n ja kaya soke.

Awọn ile iṣẹ ologun Naijiria kọ lati sọrọ nigba ti BBC kan si wọn lori ọrọ yii.

Boko Haram ti fi ẹmi ọpọ ọmọ ogun orilẹede Naijiria ṣofo lati bi ọdun meji wa sẹyin, bo tilẹ jẹ pe ijọba ni ohun ṣẹgun agbesumọmi Boko Haram

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà kò tíi fo hùn lórí ìròyìn náà

Boko Haram pa ọmọ ogun Nàìjíríà mẹ́tàléláàádọ́ta

Ìròyin tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ láti ìpínlẹ̀ Borno tó wà ní àríwá Nàìjíríà ń sọ wí pé Boko Haram ti pa ọmọ ogun Nàìjíríà àti àwọn àgbẹ̀ mẹ́tàléláàádọ́ta' láàrin ọjọ́ mẹ́ta.

Súgbọ́n iléeṣẹ́ ologun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kò tíì sọ ǹkankan nípa ìròyìn náà.

Ilé iṣẹ́ ìròyìn AFP fidi ẹ mulẹ lati ọdọ àwọn ológun kan tí wọ́n sọ wí pé ìkọ̀ Boko Haram pa, ó kéréjù, sọ́jà mẹ́tàlélógójì ( 43) ní oko Metele tí kò jìnǹa sí ẹnu aàlà orílẹ̀-èdè náà àti orílẹ̀-èdè Nìjẹ́r ní ọjọ́ Àìkú.

Ológun náà sọ pé: "Wọn pa àwọn ọmọ ogun wa, lẹ́yìn náà ni wọn gba bárékè wa nígba tí a dáná fún rawa yá.

Sọ́jà náà ṣe àfikún pé àwọn ológun ti wo inú igbó láti wá àwọn sọ́jà tí wọn sọnú lẹ́yìn ìkọlù náà.

Àwọn ọmọogun aráìlú fi tó iléeṣe AFP létí pé ikọ̀ Boko Haram náà wa ọkọ̀ bíi ogún (20), wọn kò sì rí ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọ ogun míràn títí tí àwọn ikọ̀ Bko Haram náà fi dòyì ká bárékè náà tí wọn sì kó nǹkan ìjagun lọ́ ."

Ní ọjọ́ náà ni Boko Haram kọlu oko Gajiram láàárọ̀ kùtù-kùtù. Oko náà tó máìlì mọ́kàndínláàádọ́ta (49 miles) sí Maiduguri, olú ìlú ìpínlẹ̀ náà.

Ará oko náà sọ fún iléese AFP pé àwọn Boko Haram àti ológun náà jà fún wákàtí díẹ̀.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Boko Haram n gbẹbo laarin awọn orilẹ ede ilẹ Adulawọ