Blac Chyna fẹ́ wá ta ìpara bórabóra Whitenicious ni Eko

Ghyna
Àkọlé àwòrán Ipara yii yoo fun obinrin ni à[wọ to pọn daadaa.

Àjọ NAFDAC ni àwọn n fojú si ìpara bórabóra ti Blac Chyna ọmọ ilẹ̀ America n kó bọ̀.

Ajọ yii lo n mojuto ọrọ ounjẹ àti oogun lilo ni Naijiria.

Monica Eimunjeze to jẹ oludari ẹka to n ri si àṣìlọ nkan ni NAFDAC ṣalaye fun BBC pé ileeṣẹ naa ko ni ọrọ lati sọ lasiko yii ṣugbọn NAFDAC wa lati daabo bo àwọn eniyan Naijiria ni.

Blac Chyna n ko ipara bórabóra bọ si Naijiria

Arábirin olókiki ọmọ Amẹrika kan, Angela White, ti gbogbo eniyan mọ si Blac Chyna n bọ nilu Eko ni ọjọ isinmi, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu yii, ṣugbọn oun to n gbee bọ ni orilẹ-ede Naijiria ni o ya ọpọlọpọ eniyan lẹnu.

Owo to tó aadọrun ẹgbẹrun naira ni ikan iru ipara yii yoo jẹ ni owo Naira.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Blac Chyna ṣe ipara tuntun

O fẹ wa ta ipara borabora rẹ ti o pe ni Whitenicious ni.

Lori ikanni rẹ lori Instagram, lo ti ṣalaye pe oun n ṣe agbajọwọ pẹlu awọn ti n ṣe ipara Whitenicious ni.

Blac Chyna to j'ẹ ẹni ọgbọn ọdun naa n pe awọn alatilẹyin rẹ ni orilẹ-ede Naijiria lati wa si ibi ayẹyẹ ti wọn yoo ti ṣi aṣọ loju ipara naa nilu Eko.

Image copyright @Blac Chyna/Instagram

O kọ sori Instagram pe, "Ẹyin ara Eko, ẹ wa pade mi nibi ti a o ti ṣi aṣọ loju ipara mi Whitenicious ni ọjọ Aiku ni ile itaja. Gbogbo eniyan ni a pe."

Inu agolo kekere kan ti awọn onibara yoo ra ni iye owo bii ẹgbẹrun lọna aadọrun naira.

Ṣugbọn eebu ni awọn ọmọ Naijiria fi n ki kaabọ o.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionParental Guidance: Ọdún méjì ni kí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ kíkọ́ ọmọ nípa ìbálòpọ̀
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Wọ́n ní kí n máa jẹ ewébẹ̀ láti dín ìtọ̀ súgà kù'