John Mahama: Kò sí àní-àní pé Ilẹ̀ Ifẹ̀ ni orírun àgbáyé

Ọọni ati John Mahama n sọrọ
Àkọlé àwòrán,

Ọọni ile ifẹ ni iṣọkan Afirika ṣe pataki

Ọọni ile ifẹ ,Adeyẹye Ogunwusi ti ṣalaye pe aala ilẹ to wa laarin awọn orilẹ-ede kaakiri ilẹ Afirika ko lee pa ina iṣọkan ti o wa laarin awọn eeyan rẹ.

Ni ọjọbọ ni Ọọni sọ ọrọ yii lasiko ti o n gbalejo aarẹ ana Orilẹ-ede Ghana, John Mahama ni ile Oodua ni ilu Ile Ifẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọọni Ogunwusi ni ki ọlaju awọn alawọ funfun to dé, ko si aala ilẹ orilẹ-ede si orilẹ-ede ni ilẹ Afirika, "ẹbi kan ṣoṣo ni gbogbo eeyan ilẹ yii."

"Inu mi si dun pe awọn eeyan kan loni ko sinmi tabi kaarẹ lati rii pe ilẹ Afirika ṣi duro gẹgẹ bii ẹbi kan naa.

Àkọlé àwòrán,

Aarẹ Mahama ni lati igba ti oun ti jẹ akẹkọ ni oun ti gba pe, pataki ni ọrọ Ilẹ ifẹ laarin itan agbaye

Ninu ọrọ rẹ, aarẹ orilẹ-ede Ghana tẹlẹ, John Mahama ni oun gba pe ilẹ ifẹ ni orirun aṣa ilẹ Afirika.

Aarẹ Mahama ni lati igba ti oun ti jẹ akẹkọọ ni ohun ti gba pe, ẹni maa pẹgan ajanaku laa sọ pe oun ri kini kan firi lori ọrọ Ilẹ ifẹ ati itan agbaye.

Àkọlé àwòrán,

Mahama kan sara si Ọọni fun ipa rẹ lori iṣọkan Afirika

"Gẹgẹ bii akẹkọ nipa itan, mo ti kọ ẹkọ, mo si tii kaa ninu iwe pe Ifẹ ni ni orirun eniyan, ipo ti o si wa laarin itan agbaye ko kere rara."