Black Friday 2018: Afẹ́fẹ́ káràkátà tuntun tó fẹ́ wọ Nàìjíríà

Àkọlé fídíò,

Black friday

Ọpọ ọmọ Naijiria ni wọn ji ni ọjọ Ẹti si pọpọ-ṣinṣin ẹdinwo gọbọi lori awọn ọja kaakiri awọn gbajugbaja ile itaja lorilẹ-ede Naijiria.

Koda ọrọ naa kan gbogbo agbaye pẹlu eleyi ti wọn n pe ni "Black Friday"

Ọpọ ni o si maa n lo anfani eto ayajọ ẹdinwo 'Black Friday" naa lati fi ra awọn ọja opin ọdun sile.

Ẹdinwo ọja yii a maa fa wọlu-kọlu ni ọpọ awọn ile itaja nitori ọpọ ero ti o fẹ ra ọja lowo pọọku.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi o tilẹ jẹ pe pupọ awọn ọmọ orilẹ-ede yii ni wọn kopa, ọpọ ni ko lee sọ ni pato, bi eto Black Friday yii ṣe bẹrẹ.

Kini o faa ti wọn fi n pe ayajọ yii ni black Friday?

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ni o si maa n lo anfani eto ayajọ ẹdinwo 'Black Friday" naa lati fi ra awọn ọja opin ọdun sile

Lai deena pẹnu, bi eto ẹdinwo ọja, black Friday ṣe bẹrẹ ṣi ṣokunkun pẹlu oniruuru itan lori bi o ṣe bẹrẹ ṣe n gba aye kan.

Ọkan lara awọn itan black Friday ti o gba igboro kan ju ni pe pupọ awọn ọlọja ti wọn kii ri ọja ta pupọ ni wọn maa n ri ọja ta ni ọjọ ti o ba tẹlẹ ọjọ idupẹ ni orilẹede Amẹrika. Awọ dudu si ni awọ ti wọn maa fi n ṣe apẹrẹ pe aje n bu igba jẹ nigba ti awọn pupa fihan pe ọja ko ta to bi wọn ti fẹ.

Awọn miran ṣalaye pe ilu Philadephia ni orukọ yii ti bẹrẹ laarin ọdun 1950 si 1960.

Àkọlé àwòrán,

Ọpọ ni o si maa n lo anfani eto ayajọ ẹdinwo 'Black Friday" naa lati fi ra awọn ọja opin ọdun sile

Ohun ti itan yii sọ ni pe awọn ọlọpaa atawọn awakọ ni wọn maa n lo o Black Friday lati fi ṣe apejuwesunkẹrẹ-fakẹrẹ ọkọ ti o maa n waye lasiko ti awọn to wa raja ba fọn si oju popo ni ọjọ ẹti, (Friday) ṣaaju ifẹsẹwọnsẹ bọọlu laaarin ikọ ọmọogun oriilẹ ati ọmọogun oju omi eleyii ti o maa n waye ni ọjọ abamẹta nigba naa.

Bi o tilẹ jẹ pe a ko lee sọ ni pato bi o ṣe bẹrẹ, ṣugbọn ohun kan ti a lee fi ọwọ rẹ sọya ni pe ogunlọgọ awọn ọmọ orilẹede Naijiria ni wọn ti n dara pọ mọ eto yii bayii.

Ni ilu Ibadan n ṣe ni awọn ero wọ ni kẹtikẹti lọ sawọn ile itaja ti o ṣe eto naa.

Ni ibudo itaja igbalode Shoprite, ẹsẹ o gbero pẹlu bi awọn eeyan ṣe bo ibẹ lati ra awọn ohun elo ti awọn alaṣẹ ibudo itaja naa ti kede ni ẹdinwo.

Kini awọn eeyan sọ nipa rẹ?

Àkọlé àwòrán,

Bakan naa ni awọn ọja bii ẹrọ ibanisọrọ, ororo, ohun elo iṣura ara obinrin pẹlu maa n ta pupọ

Ọkan lara awọn eeyan to lọ ra ọja nibẹ, Adeọla Ọdọle to ba BBC News Yoruba sọrọ ṣalaye pe igba keji niyi ti oun n kopa ninu ayajọ ẹdinwo ọja Black Friday nibẹ.

"Ko si ẹni ti ko fẹran ẹdinwo nitori ko si owo nilu, ṣugbọn nigba ti wọn kede rẹ ni mo fi wa. Fun apẹrẹ, oro ti a n ra ni ẹgbẹrun meji naira ni wọn ta ni ẹgbẹrun meji o din igba naira. Bakan naa ni ohun mimu milo ti wọn n ta ni ẹgbẹrun kan ni wọn ta ni ẹgbẹrin naira. Ara ohun ti o faa ti awọn eeyan fi pọ yanturu niyi."

Ajyajọ yii ko mọ pẹlu awọn ibudo itaja nikan. Awọn ileeṣẹ itaja ori ayelujara bii Konga, Jumia ati bẹẹbẹẹ lọ pẹlu ti dara pọ mọ ayaju yii pẹlu oniruuru eto ẹdinwo ọja bii ọja kolọ-n-lẹ ko dowo Flash sales ni Jumia ati Konga yakata.

Àkọlé àwòrán,

Ni ilu Ibadan n ṣe ni awọn ero wọ ni kẹtikẹti lọ sawọn ile itaja ti o ṣe eto naa

Awọn ọja wo ni o n ta julọ ni ayajọ ẹdinwo Black Friday?

Oṣiṣẹ ileeṣẹ Jumia kan ti o ba BBC Yoruba sọrọ ṣalaye pe"asiko yii ni iye awọn ti o n ra ọja maa n pọ nitori ẹdinwo ori ọja." O ni awọn ohun elo ile bii ẹrọ ifọṣọ (washin machine) ati mohunmaworan ni o maa n ta julọ lasiko yii.

Bakan naa ni awọn ọja bii ẹrọ ibanisọrọ, ororo, ohun elo iṣura ara obinrin pẹlu maa n ta pupọ.

Àkọlé fídíò,

Chef Adefunkẹ: Òórùn ewé tí wọ́n n pọ́n ìrẹsì ọ̀fadà si jẹ́ adùn lọ́tọ̀

Àkọlé fídíò,

Fanny gbà kádàrá lórí àwọn orin rẹ̀ kí wọn to ṣe alakọkọ lọdun 2012