FGM: Obìnrin igba mílíọ̀nù(200m) ló ti farakásá abẹ́ dídá

Ohun èlò ìdábẹ́ Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Abẹ́ dídá fún obìnrin sì tún wọ́pọ̀ l'Afirika

Awọn kan si tun n dabẹ fun ọmọbinrin nilẹ Afirika bi ilanilọyẹ lori ewu to wa ninu rẹ ṣe ti tan kalẹ to.

Ajajagbara fun obinrin kan, Ketcha Pertulla Enzigha sọ pe abẹ dida fun ọmọbinrin si tun wọpọ ni apa ariwa orilẹede Cameroon bo tilẹ jẹ pe ajọ iṣọkan agbaye n ke fawọn eeyan lati dẹkun rẹ.

Eleyi lo mu ki ijọba ilẹ Gẹẹsi gbe ọgọta miliọnu o le mẹrin owo dọla silẹ lati fi dẹkun abẹ dida fun ọmọbinrin kaakiri ilẹ adulawọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ sí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionṢe wahala wá ti ọkọ bá kọ̀ láti fún aya tó ti kọ̀ silẹ lára ogún rẹ?

Orilẹede Naijiria naa wa lara awọn orilẹede ti yoo jẹ anfani owo iranwọ yii.

Ijọba ilẹ Gẹẹsi fẹ ki abẹ dida ko di ohun igbagbe nilẹ Afirika laarin ọdun mejila si asiko yii.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Abẹ́ dídá fún obìnrin sì tún wọ́pọ̀ l'Afirika

Owo naa tun wa fun didena abẹ dida fun awọn ọmọ ilẹ Gẹẹsi ti wọn ba lọ silẹ okere.

Ajọ iṣọkan agbaye sọ pe abẹ dida fun ọmọbinrin le ṣakoba fun oju-ara rẹ, koda o le yi pada.

Iwadi ajọ iṣọkan agbaye sọ pe awọn ọmọbinrin to to igba miliọnu ti wọn si wa laaye bayi ni wọn ti dabẹ fun.

Gẹgẹ bi Iwadi naa tun ṣe sọ, aṣa abẹ dida yii wọpọ ni bi ọgbọn lorilẹede, ṣugbọn kii ṣe ilẹ adulawọ ni gbogbo wọn wa.