Ilé iṣẹ́ ológun Nàìjíríà korò ojú lórí fídíò ayédèrú

Aworan ọmọ ogun Naijiria Image copyright Getty Images

Ileesẹ ologun lorileede Naijiria ti faraya lori bi awọn eeyan ṣe n pin fidio ati aworan ti wọn pe ni ayederu kaakiri lori iku awọn ọmọogun ti Boko Haram pa ni Borno.

Ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ lori Facebook,wọn ni awọn ko kọ lati wọ ẹni ti o ba n pin iru iroyin ayederu bẹẹ lọ si ile ẹjọ.

Atẹjade naa salaye pe awọn iroyin bẹẹ ''a ma mu irẹwẹsi ọkan ba awọn ọmo ogun ti o si le ko ipalara ba akitiyan lati koju awọn ọmọ ikọ Boko Haram.''

Laipẹ yi ni awọn ọmọ ikọ Boko Haram ṣigun lọ ba awọn ọmọ ogun Naijiria labule kan ti wọn n pe ni Metele nipinlẹ Borno.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Awọn ọmọogun Naijiria ati ikọ Boko Haram ti n gbena wo ju ara wọn ti pẹ

Kete ti iroyin iṣẹlẹ naa lu si ẹrọ ayelujara ni awọn eeyan bẹrẹ si ni ko iriwisi orisirisi, lẹyin naa ni fọnran fidio kan lati ọdọ awọn ọmọ ikọ Boko Haram naa runa si ọrọ naa.

Aarẹ Buhari lara ipinu rẹ nigba to gba ijọba, sọ wi pe ohun yoo koju Boko Haram sugbọn lẹyin ọdun mẹta ti o de ori alefa,kaka ki ewe agbọn Boko Haram de,niṣe ni o n le koko si.

Awon aworan ayederu wo nileese ologun nsọ?

Ẹgbẹ oselu PDP to jẹ alatako APC ko tile jẹ ki ọrọ naa pẹ nilẹ ki wọn to gbe aworan kan ti o ruju sita.

Aworan yi jade si oju opo Twitter wọn lati bẹnu atẹ lu Aarẹ Buhari lori iku awọn ọmọ ogun ṣugbọn iwadi fi han wi pe aworan naa ki ṣe ti awọn ọmọ ogun to ku ni Metele.

Ọjọgbọn kan ni fasiti lorileede Amerika ti o tun jẹ akoroyin naa fara kasa ninu a n gbe iroyin ayederu yi ka.

Loju opo rẹ o fi aworan kan sita ti o ro wi pe o jẹ aworan awọn ọmọ ogun to n ke irora lori iku awọn akegbe wọn ni.

Ko pe pupo ti awọn eeyan pe akiyesi rẹ si aworan naa wi pe aworan awọn osere Kannywood lofi sita to pe ni aworan awọn ọmọ ogun Naijiria.

Beebẹ lorisirisi awọn aworan ati fọnran fidio ti awọn eeyan se alabapin wọn lasiko ti isẹlẹ ikọlu awọn ọmọogun Naijiria yi waye.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Kaka ki ewe agbọn Boko Haram dẹ

Àwọn agbébọn kan tí wọ́n funrasí pé Boko Haram ní wọ́n ti jí ọmọbìnrin mẹ́ẹ̀dógún gbé ní agbègbè Diffa tó wà ni ilà oòrùn Gúsù orílẹ̀èdè Niger.

Wọ́n jí àwọn ọmọbìnrin náà ní ìlú Toumour tó wà ní ẹnu ààlà orílẹ̀èdè náà àti Nàìjíríà ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí alákóso ilú Toumour náà ṣe fìdí ọ̀rọ̀ ọ̀hún múlẹ̀ fún iléeṣẹ́ ìròyìn Reuters.

Boukar Mani Orthe sọ pé àwọn agbébọn bíi àádọ́ta ni wọ́n kọlu ìlú náà, tí wọ̀n sì gbé àwọn ọmọbìnrin náà lọ.

Ní Ọjọ́bọ, àwọn agbébọn kan kolu ìlú Toumour ọ̀hún tí wọ́n sì pa èèyàn mẹ́jọ nínu àwọn òṣìṣẹ́ ará ilẹ̀ Faransé kan tí wọ́n ṣe ẹ̀rọ omi ọlọ́wọ́ fún àwọn àtìpọ́ tó sá àsálà kúrò níbi ìjà Boko Haram ní agbègbè náà.

Agbègbè Diffa ní orílẹ̀èdè Niger ti ń rí ìkọlù Boko Haram, láti osù kejì ọdún 2015 ti wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kolu agbègbè náà.

Nínú oṣù kínní ni wọ́n pa àwọn ológun Niger méje nígbà tí Boko Haram kolu ìlú Toumour.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ibúdó àtìpó pọ̀ ní ẹnu ààlà Nàìjíríà àti Niger