AFRIMA: Davido, Falz, Ambọde gba àmì ẹ̀yẹ olórin Afíríkà

Davido Image copyright Davido
Àkọlé àwòrán Agba olorin takasufe, 2Baba lo gba ami ẹyẹ orin takasufe to gbayi julọ ni ilẹ Afirika

Awọn gbajugbaja akọrin smọ orilẹede Naijiria Fakọyọ nibi eto ami ẹyẹ fawọn olorin nilẹ Afirika, AFRIMA to waye ni ilu Accra, orilẹede Ghana.

Davido ni wọn fun ni ami ẹyẹ akọrin to gbayi julẹ pẹlu awo orin rẹ FIA. Bakan naa lo tun gba ami ẹyẹ akọrin ti ko lẹlẹgbẹ lẹkun iwọ oorun Afirika.

Tiwa Savage gba akọrin obirin ti ko lẹlẹgbẹ lẹkun iwọ oorun Afirika pẹlu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ilumọọka asọrọdorin, Rapper Falz ni wọn fun ni ami ẹyẹ olorin Rap ti o pegede julọ ni Afirika.

Image copyright @falzthebahdguy
Àkọlé àwòrán Orilẹ̀èdè Ghana ni àmì ẹ̀yẹ náà ti wáyé

Ko tan sori awọn olorin nikan, gomina ipinlẹ Eko, Akinwunmi Ambode pẹlugba ami ẹyẹ fun ipa ti o n ko lori idagbasoke aṣa ati irinajo afẹ, paapaa julọ gẹgẹ bii olugbalejo eto ami ẹyẹ ọhun laarin ọdun 2014 si 2017.

Agba olorin takasufe, Innocent Idibia ti gbogbo eniyan mọ sí 2Baba lo gba ami ẹyẹ orin takasufe to gbayi julọ ni ilẹ Afirika.

Image copyright tufaceidibia1
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ àmì ẹ̀yẹ ni 2Baba ti gbà

Amọsa, gbogbo awọn olorin Naijiria to gba ami ẹyẹ yii ni ko sí nibi ti eto naa ti waye lorilẹede Ghana, to jẹ ẹlẹkaarun iru rẹ.