Coffin Ghana: Òkú yóò lọ sílé ìkẹyìn pẹ̀lú afẹ́ tó kẹjẹgbẹ

Oniruuru aramọnda posi lo wa bayii, eyi to n sọ nipa igbe aye oku, ala to ni, itara rẹ fun nkan ati ipo to wa nigba to wa laye.

Àkọlé àwòrán,

O yẹ ka se ẹyẹ ikẹyin fun oku wa tilu tifọn. Posi ọkọ ọbọkun ọlọyẹ kan ree ti oku kan n ba lọ sọrun bii ibugbe ikẹyin.

Àkọlé àwòrán,

Orilẹede Ghana lo n pese eso koko julọ lagbaye, idi ree ti awọn mọlẹbi kan nigberiko se maa n fi owo pamọlati sin agbẹ onikoko sinu posi. Eyi si yaayi gbaa

Àkọlé àwòrán,

Posi yii lo n salaye iru ẹda ti oku ti wọn fi sin jẹ. O lee jẹ onisowo ata nigba aye rẹ, tabi ko jẹ ẹda kan ti ko gba gbẹrẹ, to tete maa n binu, ata wẹwẹ ẹda.

Àkọlé àwòrán,

Posi ọbọkun ọlọyẹ kan ree ti wọn n kan lọwọ. Eeyan to ba ti lo ọkọ ri tabi to jẹ olowo nigba aye rẹ ni wọn maa n fi posi ọbọkun ọlọyẹ sin. Eyi to n se afihan pe oku naa jẹ ọlọrọ nigba aye rẹ.

Àkọlé àwòrán,

Posi ọkọ ofurufu ree, oku ọmọde ni wọn maa fi n sin ni Ghana. Eyi ni wọn fi n se adura fun pe ki irinajo rẹ lẹyin aye yii yọri si rere

Àkọlé àwòrán,

Posi ile alarabara ni wọn fi n sin oku baba tabi iya onile to ba kọle, to si ya awọn eeyan lati gbe lai ni wọn lara. Eyi ni wọn fi n mọ riri awọn eeyan ti ko ko ile aye le aya.

Àkọlé àwòrán,

Posi ẹrọ amohunbugbẹmu (microphone) ree, awọn akọrin tabi akọroyin ni wọn fi n sin, eyi to safihan isẹ oojọ ti wọn yan laayo nigba ti wọn wa laye.

Àkọlé àwòrán,

Oniruuru awọn posi alarabara ree, eyi to ba wu eeyan kan ni yoo mu nibẹ. Okoowo naa si ti gbalẹ bayii ni orilẹ-ede Ghana

Àkọlé àwòrán,

Ọwọ lo n tun ara se. Posi ree to joko rekete yii, to si yaayi

Àkọlé àwòrán,

Isẹ aselaagun ni posi kikan jẹ, kii se ẹrọ lo n se awọn posi to jẹ oju ni gbese naa.