Malabu Deal: Ìgbẹ́jọ́ bẹ̀rẹ̀ lóri rìbá tí Eni, Mobil san fún Nàíjíríà

Oṣiṣẹ ile iṣẹ epo rọbi Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori owo epo rọbi

Ile ẹjọ kan ni ilu Milan lorilẹede Italy ti bẹrẹ si gbọ ẹsun iwa ajẹbanu ti wọn fi kan ile iṣẹ epo rọbi meji, Eni ati Shell lori owo epo to jẹ ki Naijiria padanu biliọnu mẹfa naira.

Ajọ kan to n jẹ The Campaign Global Witness ṣalaye pe, owo epo yii ti wọn ṣe ni ọdun 2011, ti jẹ ki Naijiria kuna ni ilọpo meji owo isuna ọdun kan fun eto ẹkọ ati ilera.

Wọn fi ẹsun kan ile iṣe epo Eni ati Shell pe wọn mọ pe owo riba ni owo ti wọn san fun orilẹede Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdedoyin: Tí mo bá rí Buhari, màá sọ fun kó rántí pé Ọlọ́run wà

Ṣugbọn awọn ile iṣẹ mejeeji lawọn ko jẹbi ẹsun ti wọn fi kan wọn.

Ẹjọ naa kan awọn oṣiṣẹ ajọ ọtẹlẹmuyẹ M16 ati FBI nilẹ Amẹrika, bẹẹ naa ni o kan aarẹ ilẹ Naijiria kan tẹlẹ, pẹlu awọn oṣiṣẹ kan ile iṣẹ epo mejeeji.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori owo epo rọbi

Ile ẹjọ kan lorilẹede Faranse ti sọ tẹlẹ pe, minisita tẹlẹ fun epo rọbi Dan Etete jẹbi ẹsun pe o kowo lọ silẹ okere, ati pe o fi owo ra ọkọ oju omi ayara bi aṣa lọna aitọ.

Ilẹ naa tun sọ pe Etete ni ẹgbẹlẹgbẹ owo bi ọgọrun biliọnu owo dọla ti o ko pamọ.

Ajọ Global Witness ti n ṣe iwadi fun ọpọlọpọ ọdun, lati mọ ẹni to fun ile iṣẹ epo Eni ati Shell lasẹ, lati maa wa epo ti wọn pe ni OPL 245 lagbegbe Niger Delta.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori epo rọbi ni Naijiria

Iwadi naa si gbe jade pe, mọkaruru wa ninu adehun ti wọn ṣe lati gbe lẹyin awọn ile isẹ epo mejeeji, ati pe orilẹede Naijiria le padanu owo to din diẹ ni biliọnu mẹfa($5.86bn).

Ṣe adehun wa abi ko si?

Ajọ campaigners ni wọn gbọdọ fagi le adehun kankan to ba tiẹ wa laarin orilẹede Naijiria ati ile iṣẹ epo mejeeji.

Ava Lee to n ba ajọ Global Witness ṣiṣẹ sọ pe, ilẹ iṣẹ Shell ṣe adehun lọna to jẹ pe Naijiria yoo kuna ere to yẹ ko ri latara owo epo naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọrọ lori owo epo rọbi

Orilẹede Naijiria lo ni ọrọ aje to lowo lori ju nilẹ Afirika, ṣugbọn ọpọ ọmọ orilẹede naa si n ba osi ati iṣẹ finra.