Hijab Crisis: Fásitì Ibadan ní kò sí ohun tó yípadà pẹ̀lú ìwọṣọ akẹ́kọ̀ọ́ ISI

International School
Àkọlé àwòrán Wamuwamu ni awọn ẹṣọ aabo duro lẹnu ọna abawọle ẹkọ naa, ti wọn ko si fi aye gba ikọ iroyin BBC Yoruba lati wọle.

Eto ẹkọ ti bẹrẹ ni pẹrẹwu nile ẹkọ 'The International School' to n bẹ ninu ọgba fasiti ilẹ Ibadan, lẹhin ọṣẹ kan ti wọn ti gbe ilẹkun ile ẹkọ naa ti lori awuyewuye to waye nipasẹ awọn akẹkọ kan to wọ Hijab lọ sinu kilaasi wọn.

Awọn alakoso ile ẹkọ naa koro oju si awọn akẹkọ ti o hu iru iwa yii, ti wọn si tẹnumọ pe, ofin ile ẹkọ naa ko fi aye gba iru rẹ.

Eyi lo mu ki awọn obi to jẹ ẹlẹsin Islam gbena woju awọn alakoso ile ẹkọ naa pẹlu alaye wi pe, awọn akẹkọ lẹtọ lati mura nilana ẹsin ti o ba wu ọkan wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionAdedoyin: Tí mo bá rí Buhari, màá sọ fun kó rántí pé Ọlọ́run wà

Ede-aiyede naa lo fa bi wọn ṣe gbe ilẹkun ilẹ ẹkọ naa ti lati le dena ija ẹsin ti o ṣeeṣe ko waye, bi eefin ọrọ ọhun ba ru ju bo tiyẹ lọ.

Sugbọn lẹhin ọkanojọkan ifẹhonu han lati ọdọ awọn alẹnulọrọ ati awọn ipade to waye laarin awọn obi ati alakoso ile ẹkọ naa, eto ẹkọ ti bẹrẹ pada lowurọ Ọjọ Aje.

Awọn obi ati alagbatọ ṣi n mu awọn ọmọ wọn wọle lọkọọkan-ejeeji, bẹẹ si ni ko si ẹni to wọ Hijab wọle ninu awọn akẹkọ naa.

Àkọlé àwòrán Ede-aiyede lo se atiwaye bi wọn ṣe gbe ilẹkun ilẹ ẹkọ naa ti lati le dena ija ẹsin

Ninu iwe ti aṣoju igbimọ alakoso ile ẹkọ naa, Ọjọgbọn A.A Aderinto kọ ranṣẹ si awọn obi saaju iwọlẹ naa, o dupẹ lọwọ wọn fun ọgbọn, oye ati suuru ti wọn mu lo lasiko ti aawọ naa waye.

Botilẹ jẹ wi pe ko sọ boya ile ẹkọ naa ti fi aye gba lilo Hijab tabi bẹẹkọ, ọrọ rẹ kun fun arọwa si awọn obi lati mase fi aye gba ohunkohun ti o le da omi alafia ile ẹkọ naa ru, pẹlu alaye pek, ohun ti o tọ ni ifọwọsọwọpọ ti o le mu itẹsiwaju ba ile ẹkọ naa.

Àkọlé àwòrán Ile ẹkọ 'The International School, UI' ti wọle pada lẹhin rogbodiyan ọlọsẹ kan gbako lori ọrọ Hijab

Wamu-wamu ni awọn ẹṣọ aabo duro lẹnu ọna abawọle ileẹkọ naa, ti wọn ko si fi aye gba ikọ iroyin BBC Yoruba naa lati wọle.

Bakan naa si ni gbogbo igbiyanju lati ba awọn obi ati alakoso ile ẹkọ naa sọrọ ja si pabo lasiko ti a ṣe akojọpọ iroyin yii.