Aregbesola: Ó se bẹbẹ ní ọdún mẹ́jọ tó fi sèjọba l‘Ọ́sun

Arẹgbẹsọla n juwọ si awọn eeyan latinu ọkọ Image copyright @raufaregbesola

Ariṣe la ri ka, arika si ni baba iregun, Yoruba ni ohun taa ba se loni, ọrọ itan ni yoo da bo dọla.

Loni ọjọ Kẹtadinlọgbọn osu Kọkanla ọdun 2018 ni irinajo ijọba ọdun mẹjọ Gomina Rauf Arẹgbẹsọla dopin, ti ijọba tuntun ti Gboyega Oyetọla yoo si gberasọ.

Lasiko igba ti Gomina Rauf Aregbesola ṣe ijọba, ọpọ nnkan lo mu ba isejoba ipinlẹ Ọsun, ṣugbọn ohun to kọju si ẹnikan gẹgẹ bi Yoruba ti ṣe n sọ, ẹyin lo kọ si ẹlomiran.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Bi awọn kan ṣe n kan saara si Arẹgbẹsọla fun iṣẹ ribiribi to ṣe nigba to jẹ Gomina, lawọn miran n bẹnu atẹ lu ijọba rẹ pe ki lo se gan?

Image copyright @raufaregbesola

Agbeyẹwo awọnohun ti Arẹgbẹsọla gbe ori aleefa se lọọkọkan.

1) Eto pipese ounjẹ fun ọmọ ileewe:

Fun awọn obi ti o ni ọmọ nileewe alakọbẹrẹ nipinlẹ Osun, yoo ṣoro diẹ ki wọn to le gbagbe Aregbesola fun eto ipese ounjẹ lọfẹ fun awọn akẹẹkọ ileẹkọ alakọbẹrẹ to wa ni ipele kilaasi kinni si ikẹrin, ti oloyinbo n pe ni basic 1-4

Image copyright @raufaregbesola

Bi o tilẹ jẹpe awọn eeyan kan ko fara mọ iru igbesẹ yii, ti wọn si ni owo to n tako ipese ounjẹ yii pọ ju, paapa lasiko ti ọrọ aje Naijiria ko fara rọ, sibẹ awọn akẹkọ to n jẹun ko ni gbagbe Arẹgbẹsọla.

Eto ipese ounjẹ naa gbajumọ debi wi pe, ijọba apapọ Naijiria ya lo, to si di eto ti ijọba apapọ naa n ṣe lati pese ounjẹ fun awọn akẹkọ lawọn ipinlẹ jakejado Naijiria.

Image copyright @raufaregbesola

2) Obitibiti Gbese:

Ọpọ eeyan ati awọn ọmọ ẹgbẹ oselu alatako, to fi mọ awọn osisẹ ijọba ipinlẹ Ọsun lo n mu igbe bọnu lọpọ igba pe Rauf Arẹgbẹsọla jẹ gbese to pọ.

Koda, eyi ni wọn lo se akoba fun ijọba rẹ lati ri owo osu awọn osisẹ san fun ọpọlọpọ osu, ti awọn osisẹ ni Ọsun si n ba idaji owo osu wọn.

Sugbọn lero ti Ọgbẹni, gbese ayọ ni oun jẹ si wọn lọrun ni ipinlẹ Ọsun, tori awọn akanse isẹ ribiribi ti oun fi gbese naa se wa nilẹ bii ẹri maa jẹ mi niso.

Ẹ́ wo fidio ohun ti Gomina Arẹgbẹsọla sọ lori gbese to jẹ ni ipinlẹ Ọsun:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionArẹgbẹṣọla: Kò sí ìjọba tí kìí jẹ gbèsè

3) Ipese oju Ọna:

Bi wọn ba beere wi pe, bawo ni ijọba Aregbesola ti ṣe jẹ gbese to pọ kalẹ, lara ohun ti ‘Ogbẹni’ maa n tọka si ni wi pe, ohun pese oju ọna ati awọn ohun amayedẹrun fun ara ilu.

Ẹni to ba si rin yika tibu-tooro ipinlẹ Ọsun, yoo foju ganni ọpọ isẹ atunse awọn oju popo ati lila opopona tuntun to waye nibẹ.

Image copyright @raufaregbesola

Lara awọn oju ọna to jẹ manigbagbe ti Arẹgbẹsọla pese ni ti awọn oṣiṣẹ, oju ọna Gbongan ati bẹbẹ lọ.

Image copyright @raufaregbesola

Awọn Oṣiṣẹ́ fẹyinti ti ko dunnu si Aregbesola:

Ara ko rọ̀ okun, bẹẹ ni ko rọ adiẹ fawọn osisẹ fẹyinti lawọn akoko kan lasiko isejọba Rauf Arẹgbẹsọla, to si jẹ pe ija loni, asọ̀ lọla ni ijọba atawọn osisẹfẹyinti n se titi ti ijọba naa fi wa sopin.

Lọpọ igba ni iporogan maa n waye, tawọn osisẹfẹyinti yoo si gba oju popo kan lati se iwọde pe ki ijọba Arẹgbẹsọla san owo osu awọn.

Lasiko ọkan ninu awọn iwọde yii, awọn osisẹfẹyinti kan ba BBC Yoruba sọrọ nipa ohun ti wọn n la kọja, ẹ gbọ wọn:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀwọn oṣiṣẹ feyinti ni Osun ṣé iwọde

Atunse Ile Ekọ:

Lọpọ igba ni ijọba ipinlẹ Ọsun labẹ Arẹgbẹsọla ati ẹgbẹ oselu rẹ, APC, maa n tọkasi ọpọ iyipada rere to de ba awọn ile ẹkọ nigba ti Aregbesola ṣe ijọba.

Won ni saaju ki Aregbesola to de ori aleefa, ipinlẹ Osun ko ni awọn ileewe igbalode to se fi yangan.

Yoruba ni iroyin ko to afojuba, ọkan lara awọn ile iwe ti ijọba Aregbesola pese, ti wọn si maa n tọka si ree:

Image copyright @raufaregbesola
Àkọlé àwòrán Osogbo High School

Lara awọn aseyọri to tun wa ni akọsilẹ fun ijọba Arẹgbẹsọla lẹka ipese eto ẹkọ ni ipese ọpọn imọ (IPAD) fawọn akẹkọ ile ẹkọ girama.

O si daju pe awọn akẹkọ ileewe Girama nipinlẹ Osun ko ni gbagbe Gomina Aregbesola laelae lori ipese ọpọn imọ.

Ipese ọpọn imọ yii ni wọn ni yoo mu ki eto ẹkọ wọn tubọ ja gaara sii, bi o tilẹ jẹ pe iroyin kan n ja ranin-ranin nigba kan pe awọn eeyan kan n fi apa janu pe owo ti wọn fi ra ọpọn imọ yii kọja sisọ, ti ko si tun sisẹ pẹ, ti wọn fi kọsẹ silẹ.

Image copyright @raufaregbesola

Sugbọn bi o tilẹ jẹ pe ijọba Arẹgbẹsọla sa ipa rẹ lati mu ki eto ẹkọ muyanyan lasiko rẹ, sibẹ akọsilẹ fihan pe ajorẹyin si ni ina eto ẹkọ jo nipinlẹ Ọsun.

Fun apẹẹrẹ, laarin awọn ipinlẹ mẹrindinlogoji tawọn kẹkọ ti kọ idanwo Waec lọdun 2018, ipinlẹ Ọsun ṣe ipo kọkandinlọgbọn .

Bi onirese Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹsọla ko ba si wa fingba mọ nipinlẹ Ọsun, awọn eyi to ti fin silẹ ko lee parun, tawọn eeyan ipinlẹ naa yoo si maa ranti rẹ fun awọn ohun to gbe se laarin ọdun mẹjọ to fi se ijọba.