Jide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Jide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Ìjìyà síse ayédèrú isẹ́ onísẹ́ kò kún tó- Jide Kosọkọ

Ilumọọka osere tiata, Ọmọọba Jide Kosọkọ, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ ni, kii se owo ori ti ijọba n gba lori awọn osere lo yẹ ko jẹ ijọba lọgun nikan, bikose igbaye-gbadun awọn pẹlu.

O ni, o yẹ ki ijọba gba awọn lọwọ pasan awọn eeyan to n se ayederu isẹ awọn.

Eyi ko ṣẹyin pe ti ijiya to gbopọn ba wa fun wọn, ijọba gan an yoo tubọ ri owo to pọ si i lẹka isẹ tiata.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Jide Kosọkọ tun n fẹ ki ijọba gbe isẹ tiata larugẹ, nipa kikọ abule ere sise, taa mọ si Film Village fun wọn.

O ni eyi to fi mọ sise iranlọwọ fun awọn alagbata ati awọn olokooowo to n ta fiimu wọn sita a tun jẹ ki iṣẹ naa rọrun sii.

Kosọkọ tun rawọ ẹbẹ sijọba lati gbe owo kalẹ fawọn osere tiata.

O ni eyi yoo le jẹ ki wọn ba awọn akẹẹgbẹ wọn lagbaye pe, tawujọ agbaye yoo si maa gbe osuba fun awọn osere ni Naijiria pẹlu.

Ta ni jide Kosọkọ?

A bi ọmọọba Jide Kosọkọ ni ọjọ kejila, oṣu kinni, ọdun 1954 ni erekuṣu Eko nipinlẹ Eko ni guusu Naijiria.

O kawe ni ile ẹkọ gbogbo niṣẹ ikọni niṣẹ imọ ẹrọ ti Yaba College of Technology, ni ipinlẹ Eko.

Ọdun 1964 lo bẹrẹ ere ṣiṣe gẹgẹ bi ọmọde pẹlu ere Makanjuọla ti wọn n ṣe lori mohunmaworan nigba naa.

O ti kopa ninu ere ede oyinbo ati ti Yoruba to pọ.

Jide Kosokọ gbe Karimat ati Henriatta ni iyawo.

Wọn ṣe abiyamọ fun un ki ọlọjọ to de.

Oríṣun àwòrán, @others

Àkọlé àwòrán,

Lati kekere ni mo ti bẹrẹ ere ṣiṣe- Jide Kosokọ

Diẹ lara awọn ere ti Ọmọọba Kosọkọ ti ṣe ni Aṣiri nla, The Department, Gidi Up, Last Flight to Abuja, The Figurine, Jenifa ati bẹẹ bẹẹ lọ.