Premature Ovarian Failure: 'Ǹkan oṣù mi sọnù mo bá rò pé ó ti doyún'

Ǹkan oṣù mi sọnù mo bá rò pé ó ti doyún Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ǹkan oṣù mi sọnù mo bá rò pé ó ti doyún

Ẹni ọgbọ̀n ọdún ni ọ̀nà ti dí pa fún Evans. Ó kọ àkọsíll fún ètò BBC 100 Women nípa ìṣòro àìrọ́mọbí tó dé báa lójijì àti bó ṣe gba ìròyìǹ náà.

"Ǹkan oṣù mi ò fíbẹ́ẹ̀ ki mọ́, ó ti ń ri fẹ́lẹ́ fẹ́lẹ́ fún ǹkan bíi ọdún méjì, ṣùgbọ́n nígbà tí mo fi tó àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera ní ìlú mi New Zealand wọn kàn sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀ léréfèé bíi pé ògùn tí mò ń lò ló kàn fà á.

Nígbà tó pé oṣù kan géérégé tí mi ò rí ǹkan oṣù mi, mo bá ìdùnú lọ sọ́dọ̀ dókítà pé bóyá mo ti lóyún. Ó ti pé ọdún kan tí mo ṣègbéyàwó a sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ń sọ̀rọ̀ ọmọ bíbí ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionIVF: Ìyá ìbejì se IVF mẹ́ta lókè òkun, ìkẹrin tó se ní Nàíjíríà, ló fi bímọ

Ṣùgbọ́n nínú ẹja nbákàn, ẹja ni àyẹ̀wo oyún bí; kìí ṣe oyún. Dókítà mi ṣe àyẹ̀wò ẹ̀jẹ̀ ó sí wá ṣalàyé fún mi pé ibi tó yẹ kí hòmóònì mi wà kọ́ ló wà. Ló bá kọ̀wé gbé mi lọ sí ọ̀dọ̀ dókítà akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nípa hòmóònì ni wọ́n bá sọ fún mi pé àìlèbímọ ló ti yáa dé sí mi lára. Mi ò ms pé ẹyin ìbímọ lè tètè dáwọ́ iṣẹ́ dúró ní ọjọ́ orí yìí - ó jẹ́ ìyàlẹ́nu òjijì.

Láyé òde òní, ìgbàgbọ́ nínú obìnrin sọ fún wa pé a lè ní ohun gbogbo tí a fẹ́ bí a ṣe fẹ́ ẹ àti àkókò tí a fẹ́ ẹ. Ṣùgbọ́n irọ́ yìí kó bá wa lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbà tí ìṣẹ̀lẹ̀ ohun tí a kò rò bá bọ́ sọ́nà èyì tí a rò.

Image copyright Nicole Evans
Àkọlé àwòrán Nicole àti ọkọ rẹ̀ lọ́jọ́ ìgbéyàwó

Mo mọ̀ pé tó bá jẹ́ ní ti mọ̀lúmọ̀ọ́ká ni, bí àìlèbímọ mọ́ obìrin tó yẹ kó bẹ̀rẹ̀ ní ààdọ́ta ọdún ó lé bá fí àwọn ìṣòro kọ̀ọ̀kan hàn, ó ṣeé fojú fò dá. Mi ò fìgbà kan mọ̀ rárá pé oreọ̀fẹ́ àtibímọ obìrin leè bẹ̀rẹ̀ sí ní dínkù láti ọgbọ̀n ọdún.

A pinu láti fi ẹyin ìbímọ ẹlòmííràn tí wọ́n ń pè ní IVF èyí tí ọ̀rẹ́ dáadáa kan pèsè mo sì rò ó pé yóò jẹ́ ìdáhùn sí gbogbo ìṣòro wa. Ṣùgbọ́n pàbó ló já sí. Eléyìí dun gbogbo àwọn tó kópa gaan ni.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption67 year old mother: Mo kojú ọ̀pọ̀lọpọ̀ àìsàn fún ọdún 35 lẹ̀yín ìgbéyàwò

Lẹ́yìn ọdún kan, ọ̀rẹ́ mìíràn yọ̀nda láti ràn wá lọ́wọ́ ṣùgbọ́n lákokò yìí mi ò fẹ́ kọ́kọ́ gbà. Mo ní èyí ni yóò jẹ́ IVF ìkẹyìn tí ìjọba yuóò kówó lé lórí fún mi, ọkàn mi wá balẹ̀.

Ni a bá gbìyànjú IVF ẹlẹ́ẹ̀kejì nítorí mo ti wá pé ọdún méjìlélọ́gbọ̀n. Àkókò kò dúró.


Kí ni Menopause?

  • Menopause jẹ́ ìpele kan láyé obìnrin tó jẹ́ pé ní ìlànà ìlera, ó máa ń wáyé nígbà tí kò bá rí ǹkan o'sù rẹ̀ mọ́.
  • Ǹkan oṣù lè máa ṣe ṣégeṣège láwọn oṣù kọ̀ọ̀kan kó tó di pé ó dá.
  • Àwọn àmì mìíràn ni ìgbóná ara láìròtẹ́lẹ̀, àìfọkàn sí ǹkan, orí fífọ́, kíkó àyà sókè, àìnífẹ̀ẹ́ púpọ̀ sí ìbálòpọ̀ mọ́ àti àìrórun sùn.
  • Menopause máa ń ṣẹlẹ̀ láàrin ọdún marùn ún-lélógójì sí márùn ún-léláàdọ́ta ṣùgbọ́n ní UK, ọdún mọ́kànléláàdọ́ta.
  • Bíi obìnrin kan nínú ọgọ́rùn ún tí ọjọ́ orí wọn kò tíì tó ogójì ló máa ń la ìpele menopause yìí kọja èyí tí wọ́n tún ń pè ní premature ovarian insufficiency.

Orísun: NHS UK


Ó ba ni nínú jẹ́ pé ìgbìyànjú lẹ́ẹ̀méjì tí a ṣe láti bímọ kò doyún a ò sì ní owó àti ohun tí a nílò fún ìkẹta.

Mí ò lè dojú kọ kí n lọ gba ọmọ aláìlóbìí. Lẹ́yìn tí wọ́n ti tì mí láti se é. Màa ṣẹ̀ṣẹ̀ tún wá bẹ̀rẹ̀ omíì nípa ìbáṣepọ̀ wa, iṣẹ́, ìdílé, ìsúná. Lótitọ́ mo mọ̀ pé ó ṣe pàtàkì ṣùgbán mi ò lè dojú kọ ọ́ pẹ̀lú gbogbo ìka àlébù tí ojú mi ti rí.

Ọkàn mi dàrú. Ìdàmú ọkàn ti àwọn ọmọ tó yẹ kó jẹ́ tiwa ṣì wà níbẹ̀ kò sí bí a ṣe fẹ́ gbé e kúrò lọ́kàn tó. Ìdàmú ọkàn yìí sì wà lára mi títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan. Mo lò ó pẹ̀lú ọ̀rẹ́ mi kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ, nígbà tó lọ tán, mo rí i pé èrò láti bí ọmọ tèmi ti lọ. Ó ti parẹ́.

Image copyright Nicole Evans
Àkọlé àwòrán Nicole tó ti lé lógójì ọdún báyìí

Mi ò lè ṣàlàyé ju pé mo gbàgbọ́ pé Ọlọ́run ló mú ìrònú ọjọ́ pípẹ́ kúrò lọ́kàn mi. Mo sì wá bojú wẹ̀yìn mo rí i pé ó ní èrò tó dára míì fún mi - mo súnmọ ọ síi.

Ọ̀pọ̀lọpọ̀ dókítà ni kò mọ pé àìlèbímọ mọ́ máa ń yá. Mo ti bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ obìnrin sọ̀rọ̀ nínú ẹgbk onírànwọ́ tí mò ń darí, nígbà tí wọ́n sọ fún dókítà wọn pé ǹkan oṣù wọn ń ṣe ṣégeṣège, wọn kàn máa ń kọ̀wé gbé wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ ni.

'Àṣírí ọkọ mi tú sími lọ́wọ́, ṣé mo le dáríjì í?'

Ó jẹ́ ǹkan ìdùnú láti má náwó àti ṣíṣe wàhálà ǹkan oṣù lóṣooṣù. Ṣùgbọ́n kò tíì mọ́ra láti wà nínú ipò yìí.

Àìlèbímọ tó tètè dé ṣeéṣe kó fún mi ní ẹ̀fọ́rí, ṣùgbọ́n ó túnbọ̀ tú àṣírí pé ètò ìlera léè pèsè ìdáhùn sí ohun gbogbo.

Àwọn ojú òpó ayélujára tí ó jọ èyí

BBC kò mọ̀ nípa àwọn nnkan tí ó wà nínú àwọn ojú òpó ayélujára ní ìta