Àwọn jàndùkú dáná sún ọkọ̀ níwájú ilé aṣòfin Akwa Ibom

aworan ọkọ ti wọn sọ ina si Image copyright @OfficialPDPNig

Ẹgbẹ́ òṣèlú People's Democratic Party (PDP) ti tọka si Senẹtọ Godswill Akpabio gẹgẹ bi igi wọrọkọ ti dana ru ni ile asofin ipinlẹ Akwa Ibom.

Wọn ni aawọ to n waye nibi ti awọn kan ti sọna si ọkọ niwaju ile asofin ipinlẹ naa ko sẹyin rẹ.

Oju opo Twitter ẹgbẹ naa ni wọn fi ọrọ yii si lọjọ Iṣẹgun.

Iroyin to tẹwa lọwọ sọ wi pe wahala to n waye ni ile asofin naa ko sẹyin bi awọn asofin kan lati inu ẹgbẹ oṣelu APC ti ṣe fẹ yọ olori ile asofin naa to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP.

Saaju ni olori ile to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP, Nofiok Luke, ti kede wi pe aga awọn asoju marun to fi ẹgbẹ PDP silẹ lọ si APC ti sofo.

Ọrọ yi ko dun mọ awọn asoju yi ninu ti o si da wahala sil nile asofin ohun.

Image copyright @OfficialPDPNig
Àkọlé àwòrán Nse Etuen to jẹ ọmọ ẹgbẹ APC ko awọn asofin sọdi lati yọ olori ile to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP

Lọwọ lọwọ bayi olori ile asofin meji lo wa ti awọn alatilẹyin wọn sin jijọ woya ija lori ẹni ti o jẹ ojulowo olori ile .

Bi olori ile kan ṣe n pe ijoko lati fi yọ ikẹji rẹ naa ni awọn ti ẹgbẹ kan yoku naa n ṣe bẹ.

Nse Ntuen ni olori ile ti o wa lati inu ẹgbẹ APC,Nofiok Luke ni olori ile to wa lati inu ẹgbẹ PDP.

Ki lo kan Akpabio ninu ọrọ yi

Godswill Akpabio to fi igba kan jẹ Gomina ipinlẹ Akwa Ibom to si jẹ Seneto to n soju agbegbe iwọorun ariwa ipinlẹ naa kuro ninu ẹgbẹ PDP lai pe yi lọ si APC.

Igbese rẹ yi lo fa ti awọn ọmọ ile asofin to ri gẹgẹ bi olori wọn naa ti ṣe tele kuro ninu ẹgbẹ PDP lo si APC.

A ko ri aridaju wi pe oun lo wa nidi rukerudo to waye sugbọn olori ile asofin naa to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP n naka abuku si ẹgbẹ oselu APC pe awọn ni wọn fẹ da ile ru

A gbo pe Gomina ipinlẹ Akwa Ibom Emmanuel Udomm yọju si ile asofin lọjọ iṣẹgun nigba ti awọn asofin ọmọ ẹgbẹ APC ati olori wọn asofin Nse Ntuen n ṣe ijoko lati yọ olori ile to jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP.

A pe alukoro ile ise ọlọpaa nipinlẹ naa Odiko Macdon lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ sugbọn ko gbe ẹrọ alagbeka rẹ