Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun ṣèlérí láti gba Ọṣun fún Buhari

Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun
Àkọlé àwòrán Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọṣun

Gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun, Gboyega Oyetọla ti ṣe ileri lati mu itẹsiwaju de ba awọn aṣeyọri ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ naa.Ọyetọla se alaye ọrọ ọhun lẹhin to bura gẹgẹ bii gomina tuntun nipinlẹ Ọṣun ni papa iṣere ilu Ọṣogbo lọjọ Iṣẹgun.

Àwọn ìròyìn mìíràn tí ẹ lè nífẹ̀ẹ́ sí:

O kede ipinnu rẹ lati bomirin itẹsiwaju ipinlẹ Ọṣun lati ileto de ileto, ile iṣẹ si ile iṣẹ, ile ẹkọọ si ile ẹkọọ, titi t'anfani iṣejọba rere yoo fi de ori eeyan kọọkan to n bẹ nipinlẹ naa.Gomina tuntun naa tẹsiwaju wipe awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun yoo ni iriri iṣejọba to ni eto rere fun tẹrutọmọ, nipase awokọṣe awọn adari to ni ifojusun ati ọgbọn atinuda bii Oloye Ọbafẹmi Awolọwọ, Oloye Bisi Akande, Oloye Bọla Tinubu ati Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla.

O fi da awọn oṣiṣẹ ati oṣiṣẹ fẹhinti loju wi pe owo oṣu wọn yoo maa jẹ gbigba lasiko, gẹgẹ bo ṣe fi kun ọrọ rẹ wi pe ijọba tuntun yoo mu ọrọ itọju awọn oṣiṣẹ lọkunkundun."Lati le ṣe atunṣe ọrọ aje ipinlẹ Ọṣun, a o ṣe akanṣe apero lori eto ọrọ aje ki o to di opin oṣu mẹrin akọkọ ninu ọdun kinni iṣejọba wa.A o rii daju wipe owo oṣu awọn oṣiṣẹ n jẹ sisan lasiko, bẹẹ sini a o maa ṣe itoju awọn oṣiṣẹ ati oṣiṣẹfẹhinti botitọ ati botiyẹ.

PDP: Gómínà fìdí-hẹẹ́ ni Oyetola, ó ń lọ ilé láìpẹ́ẹ

Ẹgbẹ́ oṣelu PDP ti ní ìjọba fìdí-hẹẹ́ ni Gómínà tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ búra fún ní Ìpínlẹ̀ Ọṣun, Gboyega Oyetola fẹ́ gùn lé nítorí kò tọ́ lójú àwọn ará ìlú.

Alága ẹgbẹ́ náà ní Ọṣun Soji Adagunodo sọ nínú àtẹjáde kan lórí gbígba ọpá àṣẹ Oyetola, wípé olè jíjà ìbò tó gbé Oyetola wọlé ní o fẹ̀ẹ́ burú jù láti ìgba tí Naijiria ti padà sí ìjọba tiwantiwan ni 1999.

O sọ wípé, "Àjọ àwọn agbẹjọ́rò Naijiria (NBA), ìjọba Amẹrika, Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ati EU ni wọ́n rí bí ìbò náà ṣe wáye. Àwọn ará ìlú pàápàá ti dájọ́ fun ìjọọba tuntun yì.

"A lérò wípé ilé ẹjọ́ yóò ṣe ẹ̀tọ́ lórí ọ̀rọ̀ náà láti gbé ipò náà fún Sẹ́nétọ̀ Ademola Adeleke tí ó yẹ fún."

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOsun Election Results 2018: Adeleke sọ pé PDP yóò gba ipò gómìnà rẹ̀ padà nílé ẹjọ́