Mo gbé tíkẹ́ẹ̀tì asòfin àgbà sílẹ̀ torí ètò ẹgbẹ́ - Gómìnà Kwara
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Abdulfatah Ahmed: PDP kò fi tíkẹ́ẹ̀tì mi fa ojú ẹnìkejì mọ́ra

Laipẹ yii ni ariwo ta pe gomina ipinlẹ Kwara, ẹni to jawe olubori ninu ibo abẹnu PDP, lati dibo lọ sile asofin agba, ti gbe tikẹẹti ẹgbẹ le asofin agba to n soju ẹkun Guusu Kwara, Rafiu Ibrahim lọwọ.

Nigba to n salaye nipa ohun to ri lọbẹ, to fi wa iru sọwọ, Gomina Ahmed ni ẹgbẹ oselu PDP lo n sanna bi ẹgbẹ naa yoo se ri ọwọ mu ninu idibo gbogbo-gboo to n bọ, eto ẹgbẹ si ni ohun tẹle, ti ohun fi gbe tikẹẹti naa silẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O fikun pe ọna lati fun awọn eeyan ni oore ọfẹ lati dije ninu ibo to n bọ, ni oun se gbe igbesẹ naa, ko ma baa dabi igba to jẹ pe ẹya to pọ julọ lo n pin ipo mọ ara wọn lọwọ.

Ahmed salaye pe, PDP ko gba tikẹẹti ile asofin naa lọwọ oun lati fi fa oju oju Sẹnatọ Ibrahim mọra ko maa ba kuro ninu ẹgbẹ, amọ ọna lati seto ẹgbẹ ko gunmọ lo fa igbesẹ yii.