Òṣìṣẹ́ ìjọba ẹ̀ni ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta pokùn so ní Ekiti

Aworan okun ti awọn eeyan fi n pokun so Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Aworan okun ti awọn eeyan fi n pokun so

Ọrọ di boo lọ o yaa mi ni ileese oṣisẹ nipinlẹ Ekiti nigba ti oṣisẹ ijọba kan, ọgbẹni Abolarinwa Olaoye pokun so.

Oku arakunrin naa to lọmọ maarun ti o si n ṣiṣẹ ọlọdẹ pẹlu ijọba ipinlẹ Ekiti lawọn eeyan sadede ri nirọlẹ ọjọ iṣẹgun.

Ohun taa gbọ ni pe o fi aṣọ kan ṣe okun ti o si so o mọ ọrun rẹ eleyi to sokunfa iku rẹ.

Ọpọ awọn oṣiṣe ijọba to rọ yika oku rẹ ni kayefi ni iṣẹlẹ naa ti wọn si ṣe apejuwe ẹni ọdun mọkandinlaadọta yii gẹgẹ bi oniwa tutu.

Alupupu rẹ ti o gbe wa si ibiṣẹ ni ọjọ naa wa ni ẹgbẹ kan ti o gbe e kalẹ si.

Elizabeth Babalola to jẹ ana oloogbe naa ṣọ wi pe ogbẹni Olaoye a ma ṣiṣẹ oko dida ati ọkada lati le fi kun iye owo to n gba nibi iṣẹ ijọba to n ṣe.

Image copyright Toba Babalola
Àkọlé àwòrán Oun to mu ki arakunrin Olaoye pokunso ko ye ẹnikankan

Babalola salaye pe ni nnkan bi aago merin abọ ọjọ iṣẹgun ni Olaoye to jẹ ọmọ bibi ilu Igogo Ekiti, ni ijọba ibilẹ Moba,wa si ile oun ti o si n bọkan jẹ nipa ipenija aisiowo lọwọ ti o n ba finra.

Babalola ni ''ọrọ owo ile ati awọn gbese ti o jẹ lo n ran lẹnu nigba ti o wa si ọdọ mi ni ago mẹrin ọjọ iṣẹgun. O ni oun tun jẹ gbese ẹyawo owo ile ati ọkọ''

Nigba ti BBC Yoruba ba alukoro ọlọpa ni ipinlẹ Ekiti Caleb Ikechukwu sọrọ, o fidi ọrọ naa mulẹ pe lootọ ni wọn si ti gbe oku rẹ lọ si ile igbokupamọ si.

Caleb Ikechukwu ni lori ọrọ náà, iwadii ṣi n lọ lọwọ.