Ọlọ́pàá Abuja: Deji Adeyanju àtàwọn méjì míràn fẹ́ dá ìlú rú

Ọga ọlọpaa orilẹede Naijiria Image copyright Nigeria police force
Àkọlé àwòrán Ileeṣẹ Ọlọpaa mu Adeyanji atawọn meji miran ṣaaju iwọde wọn

Ileeṣẹ ọlọpaa lorilẹede Naijiria ti ṣalaye idi ti wọn fi mu gbajugbaja ajafẹtọ ọmọniyan kan, Deji Adeyanju ati awọn meji miran ni ọjọru.

Ninu alaye kan ti o ṣe ninu atẹjade kan to fi sita, ileeṣẹ ọlọpaa ni igbimọ pọ huwa ọdaran, ibanilorukọ jẹ kikọ eti ikun si ofin ati dida alaafia ilu laamu wa lara idi ti wọn fi mu ajafẹtọ naa.

Awọn ọlọpaa mu Deji Adeyanju, Daniel Abobama ati Boma Williams ṣaaju iwọde kan ti wọn gbero lati ṣe ni ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kọkanla ọdun 2018.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ileeṣẹ Ọlọpaa ko ṣai mọ pe gbogbo awọn ọmọ orilẹede Naijiria lo ni ẹtọ lati sọ ero ọkan wọn, ẹtọ lati korajọpọ ati ẹtọ lati rin bi o ti wu wọn gẹgẹ bii ọpakutẹlẹ fun iṣejọba tiwantiwa gẹgẹ bii iwe ofin ọdun 1999 ti ṣe laa kalẹ labẹ ipele kẹtadinlogoji, ikọkandinlogoji, ogoji ati ọkanlelogoji, amọṣa awọn ẹtọ wọnyii gbọdọ waye lai ni tako ẹtọ awọn ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ Naijiria to ku pẹlu.

Iroyin nipa mimu ti ọlọpaa mu awọn ajafẹtọ mẹta yii ti n da ọpọ ariyanjiyan silẹ bi o tilẹ jẹ pe ileeṣẹ ọlọpaa ni mimu ti wọn mu wọn ko lodi si ofin.

Ọgbẹni Adeyanju wa lara awọn ajafẹtọ lorilẹede Naijiria ti wọn ṣiwaju ipe fun aiṣegbe ileeṣẹ Ọlọpaa, paapaa julọ bi eto idibo apapọ ọdun 2019 ṣe n kan ilẹkun ni orilẹede Naijiria.

Ni nnkan bi agogo mẹwa ana ni Ọgbẹni Adeyanju ṣi kọọ si ori ikanni Twitter rẹ pe awọn ti wa lọna olu ileeṣẹ ọẹọpaa nilu Abuja lati lọ ṣe iwọde "#PoliceNotPoliticians" to tumọ si pe #ọlọpaa kii ṣe oloṣelu, ki iroyin to jade pe ọlọpaa ti muu.

Image copyright Nigeria police force
Àkọlé àwòrán Ọgbà ẹ̀wọ̀n ìlúu Keffi ni àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wà báyìí nítorí àìmú ìlànà béèlì tí ilé ẹjọ́ fún wọn ṣẹ.

Nibayii ileeṣẹ ọlọpaa ti gbe lọ si ile ẹjọ ni Ọjọru kan naa ni ile ẹjọ Karshi Court ni olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja.

Adajọ fi aye silẹ fun gbigba oniduro rẹ ṣugbọn wọn ti fi wọn si ahamọ lọgba ẹwọn ilu Keffi ni ipinlẹ Nasarawa nitori aile mu ilana beeli rẹ ṣẹ.