LUTH: Nítorí àìsan owó oṣù, àwọn dókítà ARD da iṣẹ́ sílẹ̀ ní ilé ìwòsàn LUTH nílùú Èkó

Ibusun ileewosan lai si eeyan lori wọn Image copyright LUTH
Àkọlé àwòrán Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn tí ó ń tẹ̀wálọ́wọ́ ṣe sọ, àìsan owó oṣù ló ṣokùnfà iyanṣẹ́lódì náà.

Awọn dokita ni ile iwosan nla ti fasiti ilu Eko, LUTH ti gunle iyanṣẹlodi.

Ni aago mẹjọ owurọ ọjọbọ ni awọn dokita ni ileewosan nla naa, labẹ aṣia ARD bẹrẹ iyanṣẹlodi ọhun.

Ninu ọrọ to ba BBC News Yoruba sọ, aarẹ ẹgbẹ awọn dokita ni ileewosan nla fasiti ilu Eko, LUTH, Dokita Ọlawale Ọba ni ọrọ lori owo oṣu awọn dokita ti awọn alaṣẹ kuna lati san lo ṣokunfa iyanṣẹlodi naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Dokita Ọba ni oṣu kẹjọ ọdun 2018 ni awọn dokita ileewosan naa, titi to fi kan awọn dokita agba nibẹ gba owo oṣu kẹyin eyi to tumọ si pe owo oṣu mẹta ni wọn jẹ awọn Dokita nibẹ.

"A ti ṣe ipade ṣaaju iyanṣelodi yii ti a si ti fun awọn alaṣẹ ni gbedeke ọsẹ meji eyi to pari ni ọjọru, ọjọ kejidinlọgbọn oṣu kọkanla lai si ayipada. Idi niyi ti a fi gunle iyanṣẹlodi yii."

Awọn dokita iṣegun oyinbo ni ileewosan nla fasiti LUTH nilu Eko ni kudiẹkudiẹ ti o waye lori owo iṣuna ileewosan naa ninu eto iṣuna ti awọn alaṣẹ ileewosan naa fi ranṣẹ si ileeṣẹ eto iṣuna ijọba apapọ lo ṣokunfa aisan owo oṣu wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionBeautiful Nubia: Kò sí wàhálà tó ń ṣẹlẹ̀ láàgbáyé tí kò ní ọwọ́ ẹ̀sìn lábẹ́nú

Dokita Ọba to jẹ aarẹ ẹgbẹ awọn dokita nileewosan nla LUTH ṣalaye pe ninu biliọnu mẹjọ o din igba ẹgbẹrun naira, N7.8biliọnu ti wọn kọ fun owo awọn oṣiṣẹ, ileeṣẹ eto iṣuna buwọlu lu iwọnba biliọnu mẹrin abọ, N4.5 biliọnu ninu rẹ leyii ni o si ti n mu inira ba eto sisan owo oṣu awọn oṣiṣẹ nibẹ.

Nibayii, ko tii si ẹni lee sọ ohun ti yoo ṣẹlẹ sawọn alaisan ti wọn wa labẹ itọju ni ileewosan naa ṣaaju iyanṣẹlodi ọhun.

Titi di asiko ti a fi n ko iroyin yii jọ awọn alaṣẹ ileewosan naa ko tii fi ọrọ sita lori rẹ.