Ọlọ́pàá: Ọmọ ìyá méjì gé orí ọmọ ọdún mẹ́wàá nítorí N200,000

Image copyright Lagos State Police Command
Àkọlé àwòrán Ayodeji ati Saheed salaye fun awọn ọlọpaa pe ọgbẹni kan ti orukọ rẹ njẹ Sodiq Abefe ni o ni ki awọn lọ wa ori eniyan kan wa

Ọwọ ileṣẹ ọlọpaa ti tẹ ọmọ iya meji kan pẹlu ori ọmọdekunrin ti wọn ṣẹṣẹ ge nilu Eko.

Aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ Iṣẹgun ni awọn ọlọpaa to n gbogun ti ijinigbe ni Ipinlẹ Eko da Ayodeji Obadimeji to jẹ ọmọ ọdun mejidinlogun ati ẹgbọn rẹ Saheed Obadimeji duro ni opopona Ajah si Ẹpẹ nilu Eko. Nigba ti wọn maa wo inu ọkọ ti wọn wa, ori ọmọdekunrin naa ti wọn pe ni ọmọ ọdun mẹwaa ni wọn ba ninu rẹ

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Eko, Chike Oti ni awọn afunrasi naa ti wọn n gbe agbegbe Shapati ni Ibẹju-Lekki, ṣalaye fun awọn ọlọpaa pe ọgbẹni kan ti orukọ rẹ njẹ Sodiq Abẹfẹ ni o ni ki awọn lọ wa ori eniyan kan wa ti oun yoo si nfun wọn ni ẹgbẹrun lọna igba naira (N200,000).

Wọn tun sọ siwaju pe awọn tan ọmọdekunrin naa ki o lọ ba awọn ra elerindodo Coca-Cola wa, nigba ti o mu elerindodo naa de, wọn dee mọlẹ, wọn si fi ọbẹ ge ori rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionJide Kosọkọ: Isẹ́ tíátà yóò gòkè tíjọba bá gbówó kalẹ̀ láti seré

Ọlọpaa ti kan si awọn obi ọmọ naa ti wọn ni orukọ rẹ n jẹ Joseph Makinde.

Lẹyin ti ọlọpaa mu awọn afẹsunkan naa, ni wọn mu awọn oluwadii lọ ibi ti wọn sọ iyoku ara ọmọdekunrin naa si ninu ile kan ti wọn ko ti i kọ tan ni Sapati.

Kọmiṣọna fun ileeṣẹ ọlọpaa ní Ipinlẹ Eko Edgal Imohimi ti paṣẹ fun ẹka ọtẹlẹmuyẹ lati bẹrẹ iwadi kikun lori ọrọ naa. Bẹẹ ni o si tun kilọ fun awọn ara ilu lati maa ṣọ awọn janduku aṣẹkupani to le wa ni ayika wọn.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionSunday Ayẹni: Damilọla, aya ọmọ mi fìgbónára sọ mi sókùnkùn alẹ́